Bàlúù yà wọ ojú pópó, kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ́, ẹ̀mí márùn ún lọ síi, ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lọ́gán

Aworan bi baluu naa ṣe ya wọ aarin titi ti awọn ọkọ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bàlúù yà wọ ojú pópó, kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ́, ẹ̀mí márùn ún lọ síi, ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lọ́gán
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Iwadii ti bẹrẹ lori ijamba ọkọ baluu akẹru Amazon to rena kọja oju opo rẹ ni papakọ ofurufu Miami lọjọ Aiku.

Eeyan marun un lo padanu ẹmi wọn ti eeyan marun un miran si farapa yannayanna nigba ti baluu naa ko ijamba ni nnkan bi agogo mẹfa irọlẹ.

Baluu naa to jẹ Boeing 767-300 yawọ kuro loju opo ibalẹ si awọn baluu lọ ja si opopona kan nibi to ti kọlu awọn ọkọ to n lọ loju popo naa.

Ileeṣẹ abanigbẹru kan ti orukọ rẹ n jẹ A21 Air ni North Carolina lorilẹede Amẹrika lo n lo baluu naa. Wọn si ṣalaye ninu ọrọ ibanikẹdun wọn pe, "iṣẹlẹ ijamba ọkan ninu awọn baluu ni ilu Miami jẹ eyi to bani ninu jẹ".

Wọn ni lọgan ti iṣẹlẹ ijamba naa ṣẹlẹ ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ti de sibẹ.

Adari ileeṣẹ panapana ni Miami, Raied Jadallah ṣalaye pe mẹta ninu awọn marun un to farapa ni wọn wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.

Pupọ awọn to farapa naa lo jẹ pe wọn ha mọ inu tabi abẹ ọkọ ni to si jẹ pe awọn panapana ni lati sa ipa kikankikan ki wọn to le yọ wọn.

Awọn alaṣẹ sọ pe nnkan bi igba oṣiṣẹ panapana ni wọn dide ṣiṣẹ ni ibi iṣẹlẹ ijamba naa, ati wi pe yoo ya ju bayii lati sọ pe nnkan bayii ni pato lo ṣe okunfa ijamba naa.