Àwọn kan fẹ́ kí n sọ ₦25 milíọ̀nù tí Ogogo tọ́jú sọ́wọ́ mi di owó Mọ́ṣáláṣí ṣùgbọ́n mo ní rárá – Ìmáàmù ìlú Ilaro
Lasiko isinku gbajumọ oṣere tiata, Taiwo Hassan ti ọmọ pọ si Ogogo ni iroyin kan han sita pe gbajumọ oṣere naa gbe owo tabua kan ti iye rẹ jẹ miliọnu marundinlọgbọn Naira si ikawọ Imaamu agba ilu Ilaro, Alhaji Tajudeen Adewumi.
BBC News Yoruba ba baba Imaamu naa sọrọ o si ṣalaye pe gẹgẹbi ajọṣepọ to dan mọran to wa laarin oun ati oloogbe Ogogo ṣe jẹ lo jẹ ko fi owo naa si ikawọ oun ati wi pe, ile baba rẹ lo ni oun fẹ fi kọ, ki ọlọjọ to de baa.
Imaamu Adewumi ni lẹyin abẹwo ti oun ṣe gbẹyin si Ogogo nigba to wa ni ileewosan to n gba itọju lo san owo naa si aṣuwọn oun.
"Igba ti mo dele ni ọjọ keji lo pe mi pe oun fẹ gbe owo kan si mi lọwọ o, owo yẹn oun fẹ fi kọ ile baba-baba oun to wa ni ọọkan ni bi ile kẹrin si wa; pe ile yẹn ti di ilẹ, oun dẹ maa tun ile naa kọ."
O ni ọjọ naa lo fi miliọnu marundinlọgbọn Naira ranṣẹ si oun nitoripe o ṣeeṣe ki oun rinrinajo lọ si orilẹede India fun itọju nigba naa.
O ni nigba to ku tan loun pe awọn ẹbi rẹ pe bawo lawọn yoo ṣe ṣe owo naa? Nibi ipade naa ti wọn ṣe lọjọ keje lẹyin iku rẹ lo ni awọn ti daa pada fun ẹbi rẹ lati le tẹsiwaju pẹlu erongba ti Ogogo ni lori owo naa.





