Àlàyé rèé lórí ohun táwọn iléeṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ṣe tí ìjọba àpapọ̀ ṣe fọnmú mọ́ wọn lọ́wọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba apapọ orilẹede yii ti kilọ fun awọn ileeṣẹ eleto ikansira ẹni lati ri i pe araalu gbadun owo ti won n san.

Ijọba apapọ parọwa yii nitori oju opo ikansira ẹni ti ki i ye e ṣe ṣegeṣege, ti ibaraẹni sọrọ ki si gun rege nigba mi-in ni Naijiria,

Minisita fun eto ibaraẹnisọrọ ati ikansiraẹni; Bosun Tijani, lo kilọ ọhun lọjọ Aiku, ninu atẹjade kan.

Tijani sọ pe ijọba ti ṣe awọn atunṣe to laami laaka lẹka ibaraẹnisọrọ.

O ni awọn ileeṣẹ to fi n ṣowo ni Naijiria lo ku si lọwọ lati ri I pe awọn onibaara n gbadun owo ti wọn n san lati kan sira wọn.

Gẹgẹ bo ṣe wi:

"Ojuṣe awon ileeṣẹ ikansira ẹni bii MTN Nigeria, Airtel Nigeria, Globacom ati T2 ni bayii, lati gbe gbogbo igbesẹ to yẹ ti wọn yoo fi koju ipenija, ti awọn ọmọ Naijiria yoo si fi maa gbadun ohun ti wọn n sanwo fun."

Awọn eto wo ni ijọba ṣe?

Minisita naa tẹsiwaju pe ijọba Tinubu ba idojukọ pade lẹka yii tẹlẹ, nitori ainawo si awọn ẹka to yẹ bi ibaraẹnisọrọ.

O ni ohun to fa a nigba naa ti awon onileeṣẹ ikansiraẹni ko fi le pese ohun ti araalu n fẹ niyẹn.

Lati ṣẹgun iṣoro naa, Tijani sọ pe ijọba wa iranlọwọ de ọdọ Banki Agbaye, wọn si gbe eto kan, Project Bridge, jade lati mu oju opo gbooro.

Eto mi-in to tun ṣalaye pe ijọba yoo ṣe ni ipese afikun opo nipasẹ NUCAP.

O ni eyi yoo bẹrẹ iṣẹ ki ọdun yii too pari.

O yẹ ki olokoowo kereje le lo intanẹẹti to ya kankan ni ṣọọbu tabi ile e rẹ

Nigba to n sọ afojusun ijọba lori eto ikansiraẹni, Bosun Tijani sọ pe ki araalu ni anfaani si oju opo to ja geere, to yara kankan ati intanẹẹti ti ko mu wahala dani rara ni.

Minisita naa sọ pe yala awon olokoowo kekere to n lo intanẹẹti ni ṣọọbu, tabi ile, o yẹ ki wọn le lo ayelujara taara lati ibẹ lai si idaamu kankan.

O ṣalaye awọn ilana irọrun mi-in tijọba tun ṣe lati mu ikansiraẹni ja geere.

Awọn bii atunṣe si owo ipe, kika ẹka yii kun abala pataki nini nnkan amayedẹrun, ṣiṣe aridaju owo ori to yẹ ki onibaara san lori ikansiraẹni, ati atunto nla fun ọrọ aje.

Gbogbo awon nnkan wọnyi ti mu iṣẹ awọn onileeṣẹ ikansira ẹni rọrun ju ti tẹlẹ lọ bi minisita naa ṣe ṣalaye.

"Wọn ti n fẹsẹ mulẹ daadaa bayii, iṣẹ wọn ti han kedere, wọn si ti n jere pada."

Bosun Tijani lo sọ bẹẹ.

"Awon ọmọ Naijiria yoo maa ri iyatọ ninu ipe, data rira ati ilo ayelujara karikari"

O fi kun un pe ijọba ti ro ileeṣẹ Nigerian Communications Commission (NCC) lagbara lati wo iṣẹ ti awon ileeṣẹ onikansira ẹni n ṣe, fi ofin mu wọn, da seria to yẹ fun awon to ba tapa sofin .

Minisita sọ pe ireti oun ni pe awon ọmọ Naijiria yoo to maa ri iyatọ ninu ipe, data rira ati ilo ayelujara karikari.

"O yẹ kawọn eeyan Naijiria bẹrẹ si I ri ayipada rere, ki wọn si gbadun owo ti won n san nisinyi ati lọjọ iwaju.

"A maa ri I daju pe awọn onileeṣẹ ikansira ẹni ṣe ohun to yẹ."

Bosun Tijani lo pari alaye rẹ bẹẹ.