You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Eko Bridge yóò wà ní títìpa fún àtúnṣe láti ọjọ́ Ìṣẹ́gun" -Ìjọba Eko
Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe Eko Bridge yoo wa ni titipa, bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila oṣu Karun-un ọdun 2026.
Eredi titipa naa bi wọn wi ni fun atunṣe, aabo ati iwadii.
Kọmiṣanna fun igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, Oluwaseun Osiyemi, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan lọjọ Aiku.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Eko Bridge jẹ ọkan lara awọn afara to so Erekusu Eko (Lagos Island) mọ awọn agbegbe miran ti wọn jẹ ọgbẹlẹ.
Pẹlu Afara Carter (Carter Bridge) ati eyi ti a mọ si Third Mainland Bridge.
Apa ibo ni yoo wa ni titipa?
Gẹgẹ bi Osiyemi ṣe ṣalaye, awọn apa ibi ti yoo wa ni titipa lara afara Eko naa ni ọna laarin Apongbon ati Ijora Olopaa.
Kọmiṣanna igbokegbodo ọkọ naa sọ pe awọn apa ibi to wọ Erekusu Eko yoo wa ni ṣiṣi fun awọn ọlọkọ.
"Ọna abawọ Erekusu Eko yoo wa ni ṣiṣi fawọn ọlọkọ, a o si pese awọn agbofinro to to pẹlu awọn ẹṣọ alaabo sawọn ọna mi-in ti awọn ọlọkọ le gba, ki lilọ bibọ ọkọ le ja geere."
Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.
Wọn fi kun un pe latari ọna aarin Apogbon si Ijora Olopaa ti ọrọ naa kan, kawọn awakọ maa gba afara Ẹlẹẹkẹta ti I ṣe Third Mainland Bridge wọ ibi ti wọn ba n lọ.
Tẹ o ba gbagbe, ṣaaju ni ijọba apapọ Naijiria ti pe fun titipa Eko Bridge, lati bẹrẹ Afara Carter tuntun .
Bakan naa ni Minisita fun Iṣẹ ode, David Umahi, ti sọ ṣaaju nibi eto kan niluu Eko, pe ayẹwo kikun kan labẹ omi, ti fi han pe awọn aleebu kan ti wa lara awon afara to jẹ gboogi l'Ekoo.
Umahi sọ pe lati 2013 ni ayẹwo ti fi han, pẹlu ayẹwo to tun waye laipẹ, pe awọn nnkan kan to n ran Afara Carter ati Third Mainland Bridge lọwọ labẹnu ti yẹ̀.
Ṣaa, ijọba Eko ko sọ gbedeke igba ti afara Eko Bridge yoo fi wa ni titipa.