You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni Stanley Osifo tó fẹ́ kojú Tinubu níbi ètò ìdìbò abẹ́nú APC?
Lati igba ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti kede iye ti wọn yoo ta fọọmu fun ẹni ti yoo dupo aarẹ labẹ ẹgbẹ naa ni awọn kan, paapaa awọn agbaagba ẹgbẹ, ti n sọ pe awọn ko ni ba Aarẹ Bola Tinubu du ipo naa.
Koda niṣe ni ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ, James Faleke fi owo ara rẹ ra fọọmu ọhun fun Tinubu.
Amọ, bayii ọkunrin kan ti jade, to si ti ra fọọmu lati dije tako Tinubu nibi eto idibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC to n bọ nibi ti wọn ti maa yan awọn to gbe asia ẹgbẹ oṣelu naa nibi eto idibo gbogbogbo ọdun 2027.
Iroyin ni ọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Stanley Osifo ra fọọmu ọgọrun-un miliọnu naira naa ni olu ile ẹgbẹ naa to wa ni Abuja, to si ṣetan lati dije tako Tinubu.
Aarẹ Bola Tinubu naa ti ṣe ohun gbogbo to yẹ lori fọọmu to ra naa, ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima si ti ba a da fọọmu naa pada lọjọbọ to kọja yii.
Ninu ọrọ Shettima, nigba to n da fọọmu naa pada lo ti rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ to fi mọ awọn gomina atawọn aṣofin lati ṣe atilẹyin fun Tinubu ninu erongba rẹ lati tun dupo aarẹ fun saa keji.
Ọpọ eeyan lo ti n wadii lati mọ iru ẹni to fẹ fori gbari pẹlu Tinubu jẹ.
Ta ni Stanley Osifo?
Ọmọ bibi ilu Benin, olu ilu ipinlẹ Edo, ẹkun guusu Naijiria ni Stanley Osifo.
Ọdun 2019 ni Osifo, ẹni aadọta ọdun, kọkọ jade lati dupo aarẹ Naijiria.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Iṣẹgun, Osifo juwe ara rẹ bii ọmọ Naijiria rere to ni afojusun ati ifarajin lati siṣẹ lojuna ati mu ki eto ọrọ aje Naijiria goke agba.
Nigba ti eto idibo sipo ku diẹ ko waye lọdun 2019 ni Osifo darapọ mọ egbẹ oelu APC.
O ni awọn ohun to maa jẹ afojusun oun ti oun ba di aarẹ Naijiria ni eto ọrọ aje, eto aabo, ilera, ipese omi ati idagbasoke ẹkun kọọkan ni Naijiria.
Ṣe igbesẹ Osifo yii ko ni da wahala silẹ ninu ẹgbẹ?
Lọpọ igba, ilana tubi-n-nubi ni ẹgbẹ oṣelu APC fi maa n yanju iru awọn iṣẹlẹ bayii.
Ẹwẹ, agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC, Mallam Bala Ibrahim sọ pe awọn maa ṣeto idibo abẹnu lati fi yan ẹni to maa dije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ naa.
Nigba to n ba BBC sọrọ, o ni niwọn igba to ti ra fọọmu, o ti fi han pe oun ni ifẹ lati dupo aarẹ, ti awọn si maa fun laaye lati kopa nibi eto idibo abẹnu.
Ọjọ Kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026 ni eto idibo abẹnu APC maa waye.
Bawo ni wọn ṣe n kopa nibi eto idibo abẹnu?
Mallam Bala Ibrahim sọ pe ilu Abuja ni eto idibo abẹnu naa ti maa waye.
Ofin tuntun to de eto idibo ni pe ẹnikeni to ba ti jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan lo ni anfaani lati dibo nibi eto idibo abẹnu ẹgbe oselu bẹẹ.
Amọ Bala Ibrahim sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC naa ni awọn ofin to de eni to le dibo ati pe o ni awọn ti ẹgbẹ faaye gba lati dibo.
"A ni awọn nnkan ti a fi n mu ẹni to le kopa nibi eto idibo abẹnu, ọmọ ẹgbẹ to b ani kaadi idanimọ ẹgbẹ, to n san owo oju iwe, to si ni awọn ilana mii ti ẹgbẹ ba ti la kalẹ."
O fi kun pe awọn alatilẹyin ẹni kọọkan maa to lẹyin eni ti wọn n ṣatilẹyin fun, ti wọn si maa ka iye eni to b awa lẹyin ẹnikọọkan lati fi mọ ẹni to ba jawe olubori.