Ikú Mohbad tún súyọ níléẹjọ́ l'Abuja, wọ́n ní kí ọlọ́pàá wádìí bàbá rẹ̀ pẹ́lú Wumi, ìyàwó rẹ̀

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ile ẹjọgiga apapọ kan nilu Abuja ti kede pe oun yoo bẹrẹ igbẹjọ ẹjọ kan ti wọn pe lati kan an nipa fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria pe ko tun iwadii bẹrẹ lori iku to pa gbajumọ olorin takasufe ni, IleriOluwa Alọba ti ọpọ mọ si Mohbad.

Onidajọ James Ọmọtọshọ kede ọjọ kejidinlọgbọn oṣu karun un lati bẹrẹ igbẹjọ naa.

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria, Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ni olujẹjọ ninu ẹjọ naa eyi ti ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, the Registered Trustees of Break the Silence Foundation pe lori iwadii iku to pa Mohbad.

Ajọ naa n beere fun aṣẹ ile ẹjọ lati kan an nipa fun ileeṣẹ ọlọpaa lati tun iwadii bẹrẹ lori awọn ohun to rọgba yi iku gbajumọ olorin naa ka loṣu kẹsan an ọdun 2023.

Lara awọn ẹbẹ ti ajọ naa gbe wa siwaju ile ẹjọ naa ni 'aṣẹ kanpa lati mu ki olujẹjọ o ṣe ojuṣe rẹ gẹgẹbi ilakalẹ abala ikẹrin iwe ofin akoso iṣẹ ọlọpaa ti ọdun 2020...'. Wọn fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa pe gbogbo awọn to wa pẹlu oloogbe naa lasiko ikẹyin rẹ, paapaajulọ iyawo rẹ, Ọmọwumi Cynthia Alọba, awọn amugbalẹgbẹ akọrin naa, baba rẹ ti wọn ni 'o sare bo oku ọmọ rẹ mọlẹ lai gba aṣẹ lọwọ ọlọpaa.

Bakan naa ni wọn tun rawọ ẹbẹ si ile ẹjọ naa pe ko kan an nipa fun awsn ọlọpaa lati fi panpẹ ofin mu ẹnikẹni to ba lọwọ , lọna kan tabi omiran, ninu iku gbajumọ akọrin takasufe naa, pẹlu ẹri to ba fidimulẹ.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Mohbad jade laye ni oṣu kẹta ọdun 2023, ti iku rẹ si ṣokunfa oniruuru iwọde ati ifẹhonu han kaakiri ọpọ̀ agbegbe ni Naijiria, lẹyin ti ọpọ n woye pe ejo lọwọ ninu lori iku rẹ.

ọdun mẹta ti kọja, amọṣa ibeere gbogbo to yi iku Mohbad ka ko tii ri idahun yala latọdọ ijọba tabi awọn mọlẹbi rẹ.