You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló fa òórùn àbaadì tó kó aráàlú lọ́kàn sókè l'Ado Ekiti? Àlàyé rèé
Oorun lile kan lo ti n jade lawọn apa ibi kan nigboro ilu Ado Ekiti ati agbegbe rẹ lati bii ọsẹ diẹ sẹyin bayii.
Oorun naa le to bẹẹ to jẹ awọn olugbe Ado Ekiti ko le fọkan balẹ nitori ero pe o le ṣe akoba fun ilera wọn.
Ohun to tilẹ le ni pe wọn ko le sọ pato apa ibi ti oorun naa ti n fẹ wa, bẹẹ o kari gbogbo agbegbe.
Bakan naa ni awọn araalu kan sọ pe ọwọ òru ati idaji ni oorun naa maa n fẹ wa.
Awọn agbegbe bii Ajebandele, Adebayo, EKSU Road ati Oke-Osun to wa niluu Ikere Ekiti ni oorun naa ti n jẹyọ bi iwadii ṣe fidi ẹ mulẹ.
Ọwọ ti ba afurasi kan lori oorun naa- Ileeṣẹ to n ri si Ayika
Bi oorun naa ko ṣe yee fẹ wa, ileeṣẹ to n ri si ọrọ Ayika ati ohun alumọni inu ilẹ nipinlẹ Ekiti, ti jẹ ko di mimọ pe oun ti fi kele ofin gbe ọkunrin afurasi kan, Tunde Oshin.
Ṣaaju ni Kọmisanna fun ọrọ ayika atohun alumọni nipinlẹ Ekiti, Tosin Ajisafe-Aluko, ti ni ko sẹni to wa fi ọrọ oorun naa to ọfiisi oun leti rara.
Amọ owurọ ọjọ Ẹti ti I ṣe ọjọ kẹjọ oṣu Karun-un yii ni ileeṣẹ naa kede pe ọwọ ti ba afurasi ọhun.
Ileeṣẹ naa sọ pe awọn fọwọ ofin mu afurasi naa fun ẹsun dida eroja ti ko daa sinu odo kan lagbegbe Federal Housing, l'Ado Ekiti.
Gẹgẹ bi awọn olugbe agbegbe Federal Housing ṣe sọ, wọn kẹefin Oshin lasiko to n da eroja afarajọ ẹjẹ sinu odo kan to wa nibẹ, ni nnkan bii ọwọ aago mẹjọ owurọ.
Olugbe adugbo naa kan, Anike Balogun, ṣalaye fun BBC News Yoruba pe alẹ ọjọ keje, oṣu Karun-un ni awọn ti bẹrẹ si i gbọ oorun buruku naa, ti ko si jẹ kawọn le sun daadaa mọju.
Baba onile kan lagbegbe yii, Ibrahim Jimoh, naa ṣalaye pe afurasi naa gbiyanju lati sa lọ nigba ti awọn eeyan ri I, ṣugbọn awọn le e ba.
Alagba Jimoh sọ pe lẹyin naa lawọn fa a le awọn ọlọpaa Ẹkun Oke Ila lọwọ.
Ẹjẹ maaluu ti mo ti tọju tipẹ ni mo da sodo- Afurasi
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Tunde Oshin tọwọ ba naa ti ṣalaye ara rẹ lọdọ awọn ọlọpaa.
O ni ẹjẹ maaluu toun ti gbe pamọ lati bii ọjọ diẹ sẹyin fun ọsin ẹja loun lọ da sodo ki asiri to tu.
Ijọba ipinlẹ Ekiti ti waa paṣẹ pe ki igbesẹ akin waye lori iṣẹlẹ yii.
Ni idahun si aṣẹ naa si ni awọn ileeṣẹ to wa fun ọrọ ayika eto ilera ati awọn wolewole Ekiti fi bẹrẹ si fin kẹmika apakokoro si awọn akitan.
Wọn n fin si awọn ibi odo ati ayika ti gooro idalẹnu wa káàkiri igboro ilu Ado Ekiti ati agbegbe rẹ, lati dẹkun oorun naa.