You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Eré ìdárayá ìgbátí ni mo fi ń jẹun, wọ́n ti gbá mi léti rí tí ojú mi ya, mo sojú Nàíjíríà nínú ìdíje àgbáyé"
Oniruuru ere idaraya lo wa lorilẹ aye, bawọn kan se n gba bọọlu ori ilẹ, lawọn mii n gba bọọlu ẹlẹyin ori tabili ati bọọlu alapẹrẹ, ẹsẹ kikan, ijakadi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ni aye atijọ, awọn ere idaraya ti Yoruba maa n se ni mimu ẹkẹ, ijakadi ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Amọ ohun ara ọtọ gbaa ni ere idaraya gbigba eeyan leti eyi ti ọpọ eeyan fi n jẹun bayii.
Ọna lati mọ nipa ere idaraya gbigba eeyan leti atawọn ewu to wa ninu rẹ lo mu ki BBC News Yoruba kan si ọkunrin kan, Kabiru Adediran, ti ọpọ eeyan mọ si Nigeria Hulk, ẹni to n fi ere idaraya gbigba eeyan leti jẹun.
"Mo wa ninu ile lọjọ kan, mo n jẹun, mo ri fọnran fidio kan, ti wọn n gba ara wọn leti, mo si ri pe mo nifẹ si ere idaraya onigbati naa"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Kabiru ni oun ni ẹni akọkọ ti yoo soju Naijiria nibi idije ere idarayaagbaye lori gbigba eeyan leti alagbara.
Power Slap si ni wọn n pe ere idaraya naa.
Nigba to n salaye ohun to gbe de idi ere idaraya yii, Nigerian Hulk ni idi ẹsẹ kikan fawọn ipẹẹrẹ ni oun ti kọkọ bẹrẹ ere idaraya.
"Mo soju ipinlẹ Eko ninu ẹsẹ kikan ni ọdun 2024 nipinlẹ Delta.
Lẹyin igba ti mo de, mo kopa ninu idije ti wọn ti n kan ẹsẹ ati ijakadi papọ.
Mo wa ninu ile lọjọ kan, mo n jẹun, mo wa ri fọnran fidio kan, ti wọn n gba ara wọn leti, mo si ri pe mo nifẹ si ere idaraya onigbati naa.
Ibẹ ni mo ti bẹrẹ idije fun ere idaraya onigbati, mo si ti di ilumọọka ni agbaye nidi ere idaraya naa.
Mo lọ soju Naijiria ninu idije agbaye fun eti gbigba, mo si jawe olubori nibẹ."
Ki lo de ti wọn fun ni orukọ Hulk?
Gbajumọ ajẹsẹ kan ni agbaye lo n jẹ Hulk, ki wa lo de ti wọn fun Kabiru Adediran ni orukọ yii.
Ninu alaye rẹ, Kabiru ni Davido ati ẹgbọn rẹ tii se ọmọ gomina ipinlẹ Osun, Shina Rambo, lo fun oun ni orukọ naa.
"Nigba ti mo ba fẹ lọ se igbaradi ere idaraya onigbati, mo maa n se igbaradi fun ọrun, ati ejika mi tori ibi apa ni agbara wa.
Bakan naa, mo maa n se igbaradi fun atẹlẹwọ ati ọrun ọwọ mi tori ko ma baa maa dun mi, ti mo ba fun ẹni kan nigbati.
Emi kii fi igbaradi ọrun mi sere tori ọna lati ri okun gbe ti wọn ba fun eeyan ni igbati."
Ewu ati ijamba to wa ninu ere idaraya gbigba eeyan leti
Kabiru Adediran salaye siwaju pe ewu pupọ lo wa ninu ere idaraya onigbati naa, paapaa fawọn agọ ara.
Nigba to n salaye awọn ewu naa, Hulk ni "Mo ti ri eeyan kan ti wọn bu ni igbati, ti ẹjẹ n yọ ni ẹnu ati oju rẹ.
Mo dẹ tun ti ri eeyan ti gbogbo eyin rẹ yọ ati gbogbo eyin rẹ fo danu.
Aimọye igba ni mo ti jẹ igbati, ti oju mi maa ya, ti oju mi maa wu amọ ti mo ba dele, maa lọ̀ fi omi gbigbona wọ ọ."
"Anthony Joshua ni awokọse mi, o si wu mi lati ba ja"
Nigerian Hulk ni gbajumọ akansẹ ni agbaye, Anthony Joshua, ni oun fi n se awokọse, ti oun si fẹran rẹ pupọ.
"O wu mi pupọ pe ki emi ati Anthony Joshua koju ara wa lati ja ere idaraya ẹsẹ kikan.
Mo si maa ta si lori ayelujara pe mo fẹ ba ja, mo maa n pe e nija gan, ti awọn eeyan si ro pe mo korira rẹ ni amọ eyi ko ri bẹẹ.
Mo nifẹ Anthony Joshua pupọ, o si wu mi lati ba a ja."