Ta ló ń wó pátákó ìpolongo Gómìnà Adeleke lulẹ̀ l'Osun tí APC àti Accord Party fi ń ju òkò ọ̀rọ̀ sí ara wọn?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Igbimọ to n ri si ipolongo eto idibo sipo gomina ipinlẹ Osun lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu to n ṣe ijọba ni ipinlẹ naa, Accord Party fẹsun pe wọn ba n atẹ ipolongo ibo ara wọn jẹ nitor a ti wa oju aanu awọn araalu.

Ṣaaju ni iroyin sọ pe ikọ ipolongo ibo Gomina Ademola Adeleke ti fẹsun kan ẹgbẹ oṣelu APC pe wọn n ran awọn janduku lati maa ba awọn atẹ ipolongo ẹgbẹ oṣelu Accord Party jẹ kaakiri ipinlẹ Osun.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ipolongo fun Gomina Adeleke, Pelumi Olajengbesi fi sita, fẹsun kan pe loju awọn ẹṣọ aabo ni awọn janduku naa ṣe n ba awọn atẹ ipolongo ibo Accord jẹ, to si ke si ọga ọlọpaa Naijiria lati da si ọrọ naa.

Olajengbesi ni owurọ ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹjọ, oṣu Karun-un ni awọn janduku bẹrẹ si ni ba awọn atẹ ipolongo to jẹ ti ikọ Imole Campaign ati ti ẹgbẹ oṣlu Accord jẹ ni awọn ijọba ibilẹ bii Irewole, Ayedaade, ife, Irepodun, Oriade ati Osogbo.

O sọ pe ẹri wa to fidi rẹ mulẹ pe janduku kan ti orukọ rẹ n jẹ Asiri Eniba lo ṣe agbatẹru ikọlu naa, to si ni awọn ẹṣọ aabo lo kun lọwọ lati gbe igbesẹ naa.

O tẹsiwaju pe niṣe ni ẹgbẹ oṣelu APC atawọn eeyan rẹ, latari aini ohun kan pato ti wọn fi le tako ijọba Gomina Adeleke, ti wọn si ri bi ọpọ awọn araalu ṣe to lẹyin gomina ni wọn ṣe n gba ọna biba awọn atẹ ipolongo rẹ jẹ.

"Eyi kii ṣe ọrọ oṣelu lasan. Idunkoko si eto iṣejọba awaarawa, ominira eto oṣelu ati ipenija si kikopa ninu eto oṣelu ni alaafia."

Agbẹnusọ gomina naa wa ke si ọga agba ọlọpaa Naijiria lati pe fun iwadii lori awon ikọlu naa, lojuna ati le ṣawari awọn to ṣe atilẹyin fun ati lati le foju gbogbo awọn to lọwọ ninu rẹ jofin.

Ẹ ma fi wa gbe ẹnu awọn eeyan kuro ninu aikaju oṣuwọn ijọba to wa lode - APC fèsì

Amọ ẹgbẹ oṣelu APC ti wa fesi bayii, ti wọn si ni irọ to jina si ootọ ni ẹsun naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ipolongo oludije sipo gomina ipinlẹ Osun lẹgbẹ oṣelu APC, Bola Oyebamiji, Oluremi Omowaiye sọ pe ẹsun ti Olajengbesi fi kan awọn ko lẹsẹ nilẹ rara ati pe wọn kan mọọmọ ka awọn ẹsun naa si awọn lọrun lati fun ẹgbẹ APC ni orukọ buruku lasan ni.

Omowaiye ni atẹjade ti Olajengbesi fi lede jẹ ọna lati fẹ fi gbe ẹnu awọn eeyan ipinlẹ Osun kuro lori awọn ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan iṣejọba Adeleke ni.

O ni lati bii ọjọ diẹ sẹyin ni iroyin ti n ja rayinrayin kaakiri igboro pe ọwọ tẹ olori oṣiṣẹ ile ijọba, Alhaji Kazeem Akinleye, oluṣiro owo agba ipinlẹ Osun, Rasheed Olalere Alabi atawọn eekan mii labẹ iṣejọba to wa lode, ti wọn si ti wọn mọle fun igba diẹ.

O sọ pe ẹsun ti wọn fi kan awọn eeyan naa ni kiko owo to le ni biliọnu mẹrinla naira jẹ, owo to wa fun biboju aanu wo awọn eeyan ti agbara ojo ati ẹkun omi ba ohun ini wọn jẹ, kiko biliọnu meji naira mii, owo ti ijọba apapọ fi ṣe iranwọ lati fi ra awọn ọkọ igbalode ati gbigbe owo to le ọgọrun-un biliọnu naira to jẹ owo awọn ijọba nipinlẹ Osun gba ọna mii.

O woye pe nitori bi awọn ẹgbẹ atawọn ajọ mii ṣe n bu ẹnu atẹ lu ijọba ni iṣejọba Adeleke ṣe n wa ọna lati gbe ẹnu awọn eeyan kuro ninu awọn ẹsun yii, ti wọn si n ba ohun ini ara wọn jẹ.

O ni lẹyin naa ni wọn n fi ẹsun kan APC, ti wọn si n hu oniruuru nnkan pọ lati fi wa oju ire awọn araalu, ki wọn si fi gbe enu awọn eeyan kuro ninu aikaju oṣuwọn ijọba to wa lode.