You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọkùnrin tí wọ́n sinòkú rẹ padà wọ ìlú, ariwo sọ
Iṣẹlẹ kayeefi nla kan ṣẹlẹ ni Masindi, lorilẹede Uganda lẹyin ti ọkunrin ti wọn sin oku rẹ ni wakati diẹ sẹyin ṣadede yan fanda wọ inu ilu.
Ileeṣẹ iroyin Daily Monitor jabọ pe, Godwin Baguma, lati ilu Kijana to wa lagbegbe Kijura ni Uganda ti di awati fun ọpọlọpọ ọsẹ, eyii to sọ awọn mọlẹbi rẹ sinu iporuru.
Opin ọsẹ lawọn mọlẹbi ọkunrin naa, ti wọn ni o n ṣe gangangan, gba ipe lati agọ ọlọpaa pe awọn ri ọkunrin kan to ti n jẹra ninu oko ireke lagbegbe Kisanja.
Wọn gbe oku naa lọ sile igbokupamọsi to wa nile iwosan Masindi nibi ti wọn ti ni ki awọn mọlẹbi ti eeyan wọn sọnu wa maa ṣayẹwo rẹ boya eeyan wọn ni.
Baba Baguma, Yakobo Kamuturaki, ni oun ran ọmọ oun kan ko lọ ṣayẹwo oku naa boya ti ọmọ oun to sọnu ni,
Lẹyin ti wọn ti ile iwosan de, wọn sọ fun baba agba naa pe oku ọmọ rẹ Baguma gan ni ni wọn ba ninu oko ireke ọhun.
Bi eto isinku ṣe waye
Kamuturaki ni "Wọn ni oku naa ti jẹra. Awọn ọmọ mi lọ sibẹ pẹlu awọn ibatan wọn, wọn si fidi rẹ mulẹ pe lootọ lo ti ku."
Lẹyin iroyin naa lawọn mọlẹbi rẹ tete lọ ṣeto isinku fun.
Iroyin iku ọkunrin naa milẹ titi lagbegbe ti wọn n gbe atawọn ilu to yii ka, eyii to mu ki awọn eeyan ya bo ile wọn lati ba mọlẹbi rẹ kẹdun.
Eto isinku rẹ waye lọjọ Aiku pẹlu erongba lati ṣeto idagbere ikẹyin fun lọjọ Aje.
Amọ iyalẹnu lo jẹ nigba ti iroyin bẹrẹ si n gbode pe Baguma wa laaye lagbegbe Kihanguzi, to wa niluu Labongo.
Aburo rẹ obirin ni awọn ko kọkọ naa ni iroyin naa ṣugbọn lẹyin to di akoko kan lawọn pinnu lati lọ wo o.
Jane sọ pe nigba ti wọn de ibẹ, wọn ba ẹni ti awọn ro pe o ti ku to ṣi wa laaye.
Ki lo ṣẹlẹ si oku ti wọn ti sin ṣaaju?
Bi wọn ṣe fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọmọ wọn wa laaye ni awọn mọlẹbi ọhun pada lọ wu oku ti wọn sin ṣaaju ti wọn si da oku ọhun pada sile iwosan.