Àlàyé rèé lórí ohun fà á táwọn òṣìṣẹ́ tó ń pèsè omi àti ètò ọ̀gbìn ṣe gunle ìyánṣẹ́lódì

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo isẹ lo dẹnukọlẹ lonii ni ile iṣẹ to n pese omi ẹrọ ati eto ọgbin, Lower Niger River Basin ti ilu Ilọrin nipinlẹ Kwara.

Awọn Oṣiṣẹ ile iṣẹ naa pẹlu awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ( NLC) ipinlẹ Kwara fẹhonuhan loni ọjọ Aje ọjọ kọkanla oṣu yii.

Ifẹhonuhan naa bẹrẹ nikan bi aago meje owurọ oni.

Ki lo wa fa iyansẹlodi naa ti idi ti yoo fi waye fun ọjọ meji.

Akọroyin BBC News Yoruba wa nibi iwọde naa, to si bawọn osisẹ, alasẹ ileeẹsẹ ati awọn adari ẹgbẹ osisẹ nipinlẹ Kwara sọrọ.

"Awọn alaṣẹ ko fi ọkan awọn osisẹ lọkan balẹ rara, ko si ìgbéga fawọn oṣiṣẹ ile iṣẹ naa, won ko si jẹ k'awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ṣiṣẹ wọn bii ẹgbẹ oṣiṣẹ"

Nigba ti wọn n ba BBC News Yoruba sọrọ, awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ n pese omi ẹrọ ati eto ọgbin, Lower Niger River Basin sọ pe, awọn alaṣẹ ile iṣẹ naa ko fun awọn laye lati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu ofin ẹgbẹ oṣiṣẹ.

Pẹlu alaye pe, awọn alaṣẹ ile iṣẹ naa fun ogun mọ awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ, eyi ti inu awọn osisẹ ko dun si rara.

Ninu ọrọ rẹ lasiko ifẹhonuhan naa, alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ( NLC) ni ipinlẹ Kwara, Comrade Muritala Saheed Ọlayinka sọ pe, awọn alaṣẹ ile iṣẹ naa ko fi ọkan awọn osisẹ ibẹ balẹ rara.

Pẹlu alaye pe, ko si ìgbéga fawọn oṣiṣẹ ile iṣẹ naa, won o si jẹ k'awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ile iṣẹ naa ṣiṣẹ wọn gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣiṣẹ.

O fikun pe, ọpọ ipade lẹgbẹ osisẹ ipinlẹ Kwara ti ba igbimọ alaṣẹ ile iṣẹ naa ṣe ipade lori ọrọ yii ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si.

Comrade Muritala Saheed Ọlayinka ni ọpọ awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ naa ni wọn foju wina ọpọ iṣoro lẹnu iṣẹ.

O fikun pe, awọn oṣiṣẹ to ba sọrọ lori iwa tawọn alaṣẹ ile iṣẹ naa n wu niwa, wọn a gbe wọn lọ si ibo miran.

"Ọmọ mi wa lara awọn akẹkọọ ti yóò ṣe idanwo WAEC lọla, ifẹhonuhan naa yóò ṣe idiwọ fun idanwo awọn akẹkọọ"

Ninu ọrọ rẹ, Alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ to ma lawọn ileesẹ eto ọgbin atawọn to fara pẹ, Union of Agriculture and Allied employee, .NUAAE. Comrade Mudi Ọlayinka Raji ni awọn alaṣẹ ile iṣẹ naa ko ka awọn oṣiṣẹ kun.

Pẹlu alaye pe Ifẹhonuhan naa waye lẹyin ọpọlọpọ ipade lori ọrọ naa.

Lasiko to n sọrọ alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ (NLC )ni ile iṣẹ Lower Niger River Basin Comrade Abdulrosheed Ayedun ni ẹgbẹ oṣiṣẹ ko le faramọ awọn igbesẹ ti ọga agba ile iṣẹ naa Onimọ ẹrọ Olumoroti Oluṣọla n gbe.

O ni ifẹhonuhan naa tẹsiwaju lọla, gbogbo ọna to wọ ile iṣẹ naa ni wọn yoo si gbe ti pa.

Bi awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ naa ko se raye wọle, bẹẹ ni awọn akẹkọọ to n lọ ile ẹkọ ile iṣẹ naa ko raye wọle.

Ọkan lara awọn obi to gbe ọmọ rẹ wa si Ile ẹkọ to wa nínú ọgba ile iṣẹ naa, Arabinrin Yetunde Lawal, fi ẹdun ọkan han lori iṣẹlẹ naa.

O salaye pe ọmọ oun wa lara awọn akẹkọọ ti yóò ṣe idanwo (WAEC) lọla pẹlu alaye pe, Ifẹhonuhan naa yóò ṣe idiwọ fun idanwo awọn akẹkọọ.

O wa parọwa sawọn alaṣẹ ile iṣẹ naa ati ẹgbẹ osisẹ lati jumọ ni asọyepọ.

Ifẹhonuhan naa ti ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC Ipinlẹ Kwara dari rẹ, lo bẹrẹ lago meje owurọ oni ọjọ Aje ọjọ Kọkanla oṣu yii.

Awọn osisẹ alabo ile iṣẹ naa ti ẹnu ọna abawọle sile iṣẹ naa pa ṣugbọn awọn olufẹonuhan ja gate naa ati kọkọrọ ti wọn ti pa.