You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ṣekúpa òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì iléeṣẹ́ OGTV láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ ni - Afurasí
Loootọ ni awọn amookunṣika ẹda kan da ẹmi sọrọsọrọ tẹlẹ nileeṣẹ tẹlifiṣan ipinlẹ Ogun, Arabinrin Kitan Ibilola Oyesiku, legbodo , amọ ọwọ ọlọpaa ti ba afurasi mẹta lori iku naa bayii.
Eyi nikan kọ, CP Bode Ojajuni ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, sọ fawọn akoroyin l'Ọjọbọ pe awon afurasi naa jẹwọ pe awon pa Kitan ati ọlọdẹ to n ṣọ ọgba rẹ, Pelumi Adetayo lati kọ iya naa lẹkọọ ni.
Awọn afurasi naa bi ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ṣe fi orukọ wọn lede ni:
Sodeinde Olajuwon Philip; ẹni ọdun mejilelogun (22), Sakirudeen Abdulraheem Ayoola; ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ( 27) ati Sobu Obafunsho; ẹni ọdun mẹtadinlogoji (36).
Ki lo ṣẹlẹ gan-an?
Lọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa ọdun yii ni iroyin gbode, pe awọn eeyan kan wọ ibugbe Arabinrin Oyesiku to wa ni Owode Egba, nipinle Ogun.
Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa lo ke gbajare lẹyin tawọn eeyan naa lọ tan.
Nigba ti won wọnu ọgba ile naa ni won ba oku Pelumi Adetayo to jẹ aṣọgba lẹnu ọna, bakan naa ni oku Kitan paapaa wa ninu ile nibi ti won pa a si.
Yatọ si pe wọn gba ẹmi lẹnu awọn meji yii, awọn to ṣiṣẹ ibi naa tun gbe mọto Lexus RX300 ti i ṣe ti Oloogbe Kitan lọ.
Ọlọpaa bẹrẹ iwadii
Bi iroyin iku awọn eeyan meji naa ṣe gbode ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun ti dide si i.
Ọjọ Satide naa ni CP Ojajuni atawọn ikọ rẹ si de ile naa.
Nibi abẹwo ti wọn ṣe sile naa ni wọn ti ri apẹẹrẹ pe awon eeyan kan fipa wọ inu ile Oloogbe Kitan loootọ.
Nigba to n ṣalaye lori iwadii ti wọn ṣe, Kọmiṣanaa ọlọpaa Ogun sọ pe awọn pada ri mọto iya ti wọn pa naa ni agbegbe Onikolobo, niluu Abeokuta kan naa.
O ni iwe pelebe kan wa ninu ọkọ naa to ṣatọna bọwọ ṣe ba awọn afurasi mẹta yii.
"Ọjọru ni ọwọ ba Sodeinde, afurasi akọkọ to lewaju ipaniyan naa, o jẹwọ fun wa pe oun lọwọ siku Arabinrin Kitan Oyesiku- CP Ojajuni
CP Ojajuni ṣalaye pe ayẹwo finni-finni nipasẹ imọ sayẹnsi tawọn ṣe si iwe pelebe ti wọn kọ naa lo ṣatọna bọwọ ṣe ba Sodeinde Olajuwon Philip, afurasi akọkọ ninu ipaniyan yii.
Ojajuni sọ pe Ọjọru lọwọ ba a lagbegbe Ibara,nibi kan ti wọn ti n ṣiṣẹ ile kikọ lọwọ l'Abeokuta.
O ni nibi ti Sodeinde ti n ba wọn ṣiṣẹ lebura ni ọlọpaa ti mu un.
"Lẹyin iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ miran ni ọwọ tun ba Sakirudeen Abdulraheem Ayoola to n ṣiṣẹ aṣọgba ati Sobu Obafunsho toun n ṣiṣẹ birikila.
"Bẹẹ la ṣe fi awọn mẹtẹẹta ti iṣẹlẹ naa rọ mọ si ahamọ."
Ojajuni tẹsiwaju ninu alaye rẹ fawọn akọroyin, pe lasiko tawọn n fọrọ wa awọn afurasi naa lẹnu wo, Philip jẹwọ pe oun loun ṣeto ipaniyan naa.
"Lasiko ta a n fọrọ wa wọn lẹnu wo, Sodeinde Olajuwon Philip, jẹwọ pe oun lọwọ si iku Arabinrin Olakitan Oyesiku. O tun sọ fun wa pe oun gba Sakirudeen Abdulraheem Ayoola ati Sobu Obafunsho lati ran oun lọwọ ninu iwa ika naa.
"Gẹgẹ bo ṣe sọ fun wa, o ti ṣiṣẹ pẹlu Oloogbe Kitan ri gẹgẹ bii ọlọdẹ to n ṣọ ọgba naa.
"Sodeinde sọ fun wa pe oun pa Olakitan Oyesiku lati kọ ọ lẹkọọ kan ni."
Nipa bi wọn ṣe pa awọn meji yii, CP Ojajuni ṣalaye pe awọn afurasi naa jẹwọ pe agbara awọn ka Pelumi to wa lẹnu geeti, bawọn ṣe fi ajulọ han an tan ni awọn raye wọle sinu ile.
Lẹyin naa ni wọn pa Arabinrin Oyesiku naa sinu ile, wọn si pada pa aṣọgba naa.
Awọn nnkan ti ọlọpaa ri bii ẹri
Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun ṣalaye pe awọn ri hama kan to ti kan, ada kan, apola igi kan ati biro ikọwe to ni awọ dudu lawọn ibi tawọn ti mu awọn afurasi naa.
"Iwadii n tẹsiwaju lati fi ẹsẹ awọn ẹri mulẹ, ki igbẹjọ awọn afurasi naa si bẹrẹ ni pẹrẹwu."
Bẹẹ ni CP Bode Ojajuni ṣalaye.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa Ogun duro ṣinṣin lorii pe idajọ ododo gbọdọ waye.
Ati pe gbogbo awọn to ba lọwọ si ọran yii yoo foju wina ofin.
Iru iṣẹlẹ yii ti waye ri l'Abeokuta
Tẹ o ba gbagbe, eyi kọ ni igba akọkọ ti iṣẹlẹ iṣekupani latọwọ ọmọọṣẹ yoo waye si ọga nipinlẹ Ogun.
Lọjọ akọkọ oṣu Kin-in-ni ọdun 2023 ni awọn kan ṣeku pe tọkọtaya Kehinde ati Bukola Fatinoye.
Dẹrẹba to n wa awọn lọkọlaya naa torukọ rẹ n jẹ Lekan Alabi lo pada jẹwọ pe wọn ki i ṣe oun daadaa lẹnu iṣẹ toun ti n ba wọn ṣe fun ọdun pipẹ loun ṣe ṣeto iku fun wọn.
O ni wọn ko fi kun owo oṣu oun, bẹẹ ni iṣẹ ti wọn n ran oun pọ ju owo ti wọn n san lọ.
Eyi ni Lekan ṣalaye pe o fa a toun fi lẹdi apo pọ pẹlu awọn kan, wọn si wọle to tọkọtaya naa bi wọn ṣe n de lati ṣọọṣi fun isin ọdun tuntun.
Wọn pa dumbu ọkọ, wọn si fọ hama mọ iyawo lori, wọn tun gbe ọmọ wọn ju sodo Ogun niluu Abeokuta nibi ti ọmọ naa pada dakẹ si.
Ni ti Oloogbe Kitan Ibilola Oyesiku yii naa, awọn agbofinro sọ pe apẹẹrẹ pe hámà ni wọn fọ mọ ọn lori to fi ku han.