You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé rèé lórí ìròyìn tó gbalẹ̀ pé ọlọ́pàá ti mú Ọba ìlú Ẹ̀sínẹ̀lẹ̀ lórí ẹ̀sùn lílọ́wọ́ nínú ìwà ìjínigbé akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́
Ni irọlẹ ọjọ Isẹgun ni ariwo gba ori ayelujara pe awọn agbofinro ti mu ọba ilu Ẹsinẹlẹ, Oba Tajudeen Abidoye, nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo.
Iroyin naa ni wọn mu oriade naa nibamu pẹlu iwadii to n lọ lọwọ lori isẹlẹ ijinigbe to waye laipẹ yii nilu Esinele ati Yawota to wa nijọba ibilẹ Orire.
Bi ẹ ko ba gbagbe, agbegbe naa ni awọn ajinigbe ti ko awọn akẹkọ ati Olukọ to to mọkandinlogoji ni ọjọ kẹẹdogun osu karun ọdun yii, ti wọn ko si ti pada wa sile.
Iroyin naa fikun pe Oba Tajudeen Abidoye tii se Ẹlẹṣinele ti ilu Eṣinele ti wa ni atimọle awọn ọlọpaa fun ẹsun pe o ṣeeṣe ko lọwọ ninu iwa ijinigbe to waye ni ilu Yawota ati Ahoro Esinele laipe yii.
Oba Tajudeen Abidoye yii si lo ti n le waju lati pe fun iyọnda awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni ahamọ awọn agbebọn lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si ile ẹkọ mẹta nilu Yawota ati Ahoro Esinele.
Iroyin naa tẹsiwaju pe, awọn olọpaa, gbiyanju lati ṣe iwadii ati ibasepọ to wa laarin awọn afurasi ti ọwọ Ọlọpaa ti tẹ ati Ọba Tajudeen Abidoye Ẹlẹṣinele ti ilu Esinele.
" Wọn ko mu ẹnikẹni ninu ilu mi, wọn ko si mu emi gangan, mo wa laafin mi, mo ṣẹṣẹ pari ipade pẹlu awọn ara ilu mi tan nisinsinyi ni"
Iroyin yii lo ta akọroyin BBC News Yoruba nidi kan lati kan si oriade naa, lati wadi okodoro isẹlẹ yii.
Nigba to n ba wa sọrọ, Ẹlẹṣinele kede yanya pe irọ to jinna sootọ ni gbogbo iroyin naa, ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni ọmọ ninu si ni pẹlu.
Kabiyesi salaye pe igba akọkọ kọ niyi ti ọpọ iroyin ti ko lẹsẹ nle ti n jade nipa oun, paapaa julọ, lati igba ti iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebon ti waye nilu Ahoro Esinele.
Ọba Abidoye ni "Ibanujẹ ọkan lo jẹ fun emi ti mọ jẹ olori ilu, ti ko si dun mọ mi, sugbọn gbogbo iroyin ti onikaluku gbe, Ọlọrun to n san ẹsan yoo san wọn lẹsan.
" Wọn ko mu ẹnikẹni ninu ilu mi, wọn ko si mu emi gangan, mo wa laafin mi, mo ṣẹ paari ipade pẹlu awọn ara ilu mi tan nisinsinyi ni.
" Ọpọ iroyin ni wọn ti gbe jade lori mi, emi ko mọ nipa rẹ o".
Ta ba gbagbe, Ile ẹkọ Community High School, ni ijọba ibilẹ Oriire ni wọn ti ji awọn olukọ ati akẹkọ gbe lọjọ Karundinlogun, oṣu Karun un, ọdun 2026 ti a wa yii.
Bẹ si ni awọn agbesunmọmi naa ti ṣekupa ọkan lara awọn eeyan naa ti wọn ji gbe lẹyin ti wọn ti kọkọ pa olukọ kan sile ẹkọ ọhun lasiko ikọlu naa.
Wo àwọn ìlú tí ọ̀rọ̀ kàn bí ìjọba Oyo ṣe kéde ìséde ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá fún wákàtí mẹ́rìndínlógún lójúmọ́
Ijọba ipinlẹ Oyo ti kede iṣide fun wakati mẹrindinlogun ni ijọba ibilẹ mẹwaa kaakiri ipinlẹ naa.
Igbesẹ yii ni ijọba ni o n waye lati pọnkun akitiyan wọn lati ṣawari awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ti wa ni akata ajinigbe lati ọjọ Kẹẹdogun oṣu Karun-un, ọdun 2026.
Awọn ijọba ibilẹ mẹwaa to wa ni ayika Old Oyo National Park ni isede naa kan.
Atẹjade ti agbẹnusọ ijọba ipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi lede lọjọ Iṣẹgun, ọjọ Kẹtalelogun, oṣu Kẹfa sọ pe isede naa yoo bẹrẹ lọjọru, ọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹfa laaarin aago mẹrin irọle si aago mẹjọ aarọ ojoojumọ fun ọjọ meji ti isede naa maa kọkọ fi waye.
Eyi tumọ si pe ti aago mẹrin irọlẹ ba ti lu lọjọru ni ko ni si lilọ bibọ mọ fun awọn eeyan titi di aago mẹrin owurọ ọjọ keji ti eyi si maa waye fun ọjọ meji gbako ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹwaa ti wọn ti kede isede naa.
Oyelade ṣalaye pe isede naa jẹ igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati koju ijinigbe atawọn ipenija aabo to n waye ninu igbo Old Oyo National Park.
O wa rọ awọn araalu lati ri daju pe wọn tẹle idari ijọba naa, ki wọn si ri pe wọn ko jade lawọn asiko ti ijọba kede naa.
O ni ṣiṣe bẹẹ jẹ atilẹyin awọn araalu si akitiyan ijọba lati da aabo bo ẹmi ati dukia awọn araalu.
Awọn ijọba ibilẹ ti isede ti maa waye atawọn ilu diẹ to wa labẹ wọn
Oriire - Ikoyi-Ile, Oolo, Orile-Igbon, Alawusa, Esinele, Yamota, Iluju
Orelope - Igboho, Igbope, Modeke, Jakuta, Obaago, Oke Afin, and Bonni
Irepo - Kisi Adagbangba, Agunla, Budo-Ojetere, Welewele, Sooro, Sise-orowo, Ajetowa,
Saki West - Saki, Ilua, Ogbooro, Ekokan, Agbele, Igbo-Irawo, Wasangere
Saki East - Ago-Amodu, Sepeteri, Ogbooro, Oje-Owode, Agbonle
Atisbo - Tede, Ago-Are, Irawo, Ofiki, Sabe
Itesiwaju - Otu, Okaka, Ipapo, Igbojaye, Komu, Oke-Amu, Baba-Ode
Iseyin - Ado-Awaye, Osogun, Akinwumi, Osoogun, ati Ilero
Olorunsogo - Igbeti, Iyamopo, Agbeni, Sagbon, Agoro, Aperu, Agbele, Okin, Opa/Ogunniyi, Waro/Apata-Alaje, Aboke, Ikolaba/Obadimo
Atiba - Offa Meta, Agunpopo, Aremo, Ashipa, Bashorun, Otefon, Afodija, Ayoade, Sabo
Ṣé òótọ́ ni wọ́n fi ẹlikọ́pítà kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso lọ sí Kaduna?
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe irọ ni iroyin kan to n lọ nigboro pe wọn ti fi ọkọ ofururu ẹlikọpita gbe awọn akẹkọọ ati olukọ ti awọn agbesunmọmi jigbe ni Ahoro-Esiele ati Yawota lọ si ipinlẹ Kaduna.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Ayanlade Olayinka lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.
Ọlọpaa ni irọ ni ohun to wa ninu fidio kan to sọ pe bẹẹ bi ọrọ ri ati pe awọn to ṣe fidio ọhun mọọmọ gbe jade lati ṣi araalu lọna ni.
O ni "Ileeṣẹ ọlọpaa fẹ jẹ ki araalu mọ pe iṣẹ takuntakun n lọ lọwọ lati doola awọn eeyan naa.
"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, ni ajọṣepọ pẹlu awọn ileeṣẹ eto abo mii ko dakẹ iṣẹ lati ri daju pe gbogbo awọn ti wọn ji gbe naa ni wọn pada wale layọ ati alaafia lati darapọ mọ mọlẹbi wọn ki a si fi ṣikun ofin mu awọn to ṣiṣẹ laabi naa.
"Irufẹ iwa bẹẹ ko bojumu, bẹẹ lo tun n da ibẹru sọkan awọn araalu"
"Bi awọn eeyan kan ṣe n mọọmọ pin iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa iṣẹlẹ yii lati jẹ ki araalu sọ ireti nu ninu ọlọpaa n kọ ileeṣẹ ọlọpaa lominu.
"Irufẹ iwa bẹẹ ko bojumu, bẹẹ lo tun n da ibẹru sọkan awọn araalu, o n ṣi awọn araalu lọna bẹẹ lo n di iṣẹ awọn eleto aabo lọwọ."
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo wa fi atẹjade naa kilọ fun gbogbo awọn to n pin iroyin ẹlẹjẹ kirii pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.
Ayanlade ni ẹnikẹni ti ọwọ agbofinro ba tẹ pe o n pin iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa iṣẹlẹ naa lọna ati mu ki araalu sọ ireti ni ninu awọn agbofinro yoo jẹ iyan rẹ niṣu.
Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo ki wọn lọ fi wọn ọkan wọn balẹ ki wọn si maa ṣatilẹyin fun awọn agbofinro ninu iṣẹ wọn.
O tun rọ araalu ki wọn maṣe maa gba eyikeyi iroyin gbọ ayafi eyii to ba jade lakata awọn alaṣẹ nikan ki awọn kọlọrọsi ẹda kan ma ba a ṣi wọn lọna.
Nnkan bii ogoji ọjọ sẹyin ni agbebọn yabo ile ẹkọ meji ni Ahoro-Esiele ati Yawota ti wọn si ji akẹkọọ mọkandinlogoji ati oluke meje gbe lọ.
Wọn yinbọn lu olukọ kan lẹsẹkẹsẹ, wọn tun ge ori olukọọ mii ninu igbo ti wọn ko wọn lọ.