You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìkà kọ́ lọmọ ejò, àwa èèyàn là ń kó tiwa bá wọn- Taiwo Okikiola-Ọmọ elejo
Ika lọmọ ejo ni Yoruba wi, ko si sẹni ti yoo foju kan ejo ti ko ni i ta giri pẹlu ẹ̀rù.
Amọ ọdọmọbinrin kan ree ti oun mu ọrọ ejo ni ọkunkundun gidi. Taiwo Okikiola ni Orukọ rẹ.
Bo ṣe wa jẹ pe Taiwo Okikiola gan-an ni ni orukọ rẹ yii, Ọmọ elejo tabi Ifa lejo ni awon eeyan mọ ọn si.
Eyi ri bẹẹ nitori Taiwo kẹkọọ nipa awọn ẹranko afarayafa bii Ejo, Ọni, Alangba ati bẹẹ bẹẹ lọ nile ẹkọ, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni Herpetologist .
O ṣalaye pe ika kọ lọmọ ejo, ejo gan-an ko fẹ lati fi oró rẹ ge eeyan jẹ.
Idi ti mo fi yan ejo atawọn nnkan afayafa mi-in laayo ree
Nigba to n ṣalaye idi rẹ to fi yan ohun ti ọpọ eeyan maa n sa fun laayo, Ọmọ elejo sọ pe:
"Mo jẹ eeyan to nifẹ si gbogbo nnkan to n fi aya fa patapata, emi o foju ti awa Adulawọ fi maa n wo nnkan afayafa bii pe wọn ki i ṣe iṣẹda Ọlọrun wo won.
"Lati kekere ni mo ti nifee si ejo, mo maa n mu won, fi won ṣere, ju wọn silẹ. Mo waa mu un lọkundundun, mo si ni i lọkan lati jẹ kawọn eeyan mọ pe iṣẹda alaafia ni ejo.
"Iya mi gan-an o tete mọ nnkan ti mo n ṣe, ẹkọ nipa iroyin ni won ran mi lọọ ka nile ẹkọ, ki n too dari si ẹkọ nipa ejo."
Ọmọ elejo fi kun un pe bẹẹ naa kọ lejo buru to, awọn eeyan lo n fi oju ẹranko to buru wo wọn.
"Ohun tawọn eeyan ko mọ ni pe awọn ejo gan-an ko raye tiwa, ohun ti won maa jẹ ni won n wa. Awa eeyan ni lati mọ eyi, ko si ye wa daju pe awa gan-an la n kọle sibi ti wọn wa, ti a n lọ ba wọn ni ibuba wọn".
Okikiola ko ṣai fi kun un pe iṣẹ elejo toun gbe dani yii ti n jẹ kawọn eeyan mọ pe ejo ki i ṣe iṣeda buruku, bo tilẹ jẹ pe awọn kan maa n tabuku oun lori ayelujara,tawọn mi-in si maa n pe oun ni ajẹ.
Bi o ba fẹ mọ nipa ohun ti o le fi mọ pe ejo ti wa ni ayika rẹ, Ọmọ elejo ka wọn kalẹ ninu fidio yii. Wo o ki o kẹkọọ siwaju nipa awọn ejo ti a tun mọ si Olufa.