You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Olóòtú ìjọba UK, Keir Starmer kọ̀wé fipò sílẹ̀
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, UK, Keir Starmer ti kọwe fipo rẹ silẹ gẹgẹ bi olootu ijọba ilẹ naa ati olori ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Ko i tii pe ọdun meji ti Starmer gba ipo olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi bi o ṣe gba ipo naa lọjọ Karun-un, oṣu Keje, ọdun 2024 lẹyin ti ẹgbe oṣelu rẹ, labour Party ṣe jawe olubori nibi eto idibo gbogbogbo orilẹ ede naa.
Nigba to n kede fifi ipo silẹ lọjọ Aje, Starmer ni oun ti fi ipinnu oun to Ọba Charles leti ni owurọ yii.
"Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oselu Labour Party maa gbe atẹ eto bi wọn ṣe maa yan adari tuntun sita ni ọjọ Kesan-an, oṣu Keje"
Ẹwẹ, Starmer ṣi maa dipo rẹ mu titi di igba ti egbẹ oṣelu Labour Party maa pari gbogbo eto lati yan olori mii ki ile aṣofin orilẹ ede naa to wọle pada lati isinmi wọn ninu oṣu Kẹsan-an.
O ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ Labour Party maa gbe atẹ eto bi wọn ṣe maa yan adari mii tuntun ni ọjọ Kesan-an, oṣu Keje.
Eyi tumọ si pe wọn ti maa yan olootu ijọba mii ki ile aṣofin to wọle pada.
Starmer juwe akoko rẹ gẹgẹ bi olootu ijọba UK bii igba to wuyi julọ ninu igbesi aye rẹ.
O ni oun n gbe igbesẹ lati fipo oun silẹ nitori oun fi orilẹ ede ti oun nifẹẹ si siwaju ni ati pe oun fi da awọn ẹgbe oṣelu oun ti ko ni igboya ninu oun lati ko wọn sodi nibi eto idibo gbogbogbo orilẹ ede naa.
O fi kun pe oun maa ṣe gbogbo ohun to w ani ikapa oun lati ri daju pe o rọrun lati ijọba fun ẹni to ba maa gbapo lọwọ rẹ.
O ni ẹni to maa gbapo lọwọ oun n gba akoso ijọba Britain ti ayipada ti ba laaarin ọdun meji seyin.