"Wọ́n yìnbọn pa ọmọ wa ní ṣọ́ọ̀bù ìyá rẹ̀ torí ẹnìkan dé fìlà yẹ́lò tó jẹ́ tẹgbẹ́ Accord l'Osun, mo fẹ́ ìdájọ́ òdodo"

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ọjọ Kọọkanlelogun osu Kẹfa ọdun yii ni iṣẹlẹ laabi kan ṣẹlẹ ni Ilu Ilobu to wa ni ijọba ibilẹ Irẹpọdun ni Ipinlẹ Ọsun nigba ti wọn yinbọn mọ Ezekiel Olapade.

Se ni ariwo ta lori ayelujara nigba ti baba kan n sọkun pẹrẹ pẹrẹ pe awọn kan yinbọn pa ọmọ oun lainidii.

Idi ree ti BBC News Yoruba fi gba ilu Ilobu lọ lati tan imọlẹ si isẹlẹ yii, ka le mọ awọn eeyan to wa nidi isẹlẹ naa.

A de ile awọn oloogbe Ezekiel Olapade lati mọ bi isẹlẹ naa se ri lara wọn ati awọn eeyan ti wọn fura sipo wa nidi iwa ibi yii.

"Awọn janduku ri ọkunrin kan to de fila alawọ Yẹlo, wọn ro pe fila ẹgbẹ oṣelu Accord ni ọkunrin naa de"

Nigba to n ba ikọ iroyin BBC News Yoruba sọrọ, Olapade Olugbemiga tii se baba Ezekiel Ọlapade salaye pe awọn sadede ri awọn janduku kan lojiji ni.

Olapade ni awọn janduku naa lo gbe ibọn lọwọ pẹlu ohun ija miran niwaju ọọfisi ijọba ibilẹ Irẹpọdun to wa ni Iluu Ilobu.

"Ẹmu ati ẹran igbẹ ni iyawo mi n ta niwaju ọfisi ijọba ibilẹ naa.

Nigba ti awọn janduku naa de, wọn ri ọkunrin kan to de fila alawọ Yẹlo ṣugbọn awọn janduku naa ro wi pe, fila ẹgbẹ oṣelu Accord ni ọkunrin naa de.

Eleyi lo mu wọn kọju ibọn si ibi sọọbu iyawo mi lati ba ọkunrin naa ja.

Ṣugbọn bi gbogbo wa ṣe ri awọn ọkunrin ti wọn kọju ibọn naa si ọdọ wa, ni gbogbo awa ti a wa níbẹ sare dola ẹmi ara wa. "

"N ko mọ pe ina ti jo mi, ẹni ti ibọn ba ni mo sare gbe lọ si aafin Olobu ti Ilu Ilobu, ṣugbọn ki n to pada de, mo ba oku ọmọ mi Ezekiel nilẹ pẹlu ọpọlọpọ ẹjẹ lara rẹ"

Olapade Olugbenga tẹsiwaju pe ọmọ oun, Ezekiel, lo sare tẹle arakunrin to de fila yellow wọ inu igbo lati dola ẹmi ara rẹ.

O ni ṣugbọn lojiji lo boju w'ẹhin, to si ri iya rẹ to ti subu lulẹ.

O fikun pe eyi lo mu ki ọmọ naa pada lati gbe iya rẹ dide ṣugbọn ko to de ọdọ iya rẹ, ni awọn janduku naa yinbọn fun ọmọ oun.

"Emi ko mọ pe ina ti jo mi, ẹni ti ibọn ba ni mo sare gbe lọ si aafin Olobu ti Ilu Ilobu, ṣugbọn ki n to pada de, ni mo ba oku ọmọ mi Ezekiel nilẹ pẹlu ọpọlọpọ ẹjẹ lara rẹ.

Mo gbe sugbọn ko si ẹmi lara rẹ mọ."

Baba Oloogbe naa ni ohun ti oun fẹ ni idajọ ododo fun ẹni to gba ẹmi ọmọ oun, ki wọn si pa onitọun naa.

Bakan naa lo salaye pe ọkọ ti awọn janduku naa gbe wa ni wọn lẹ orukọ Oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo gomina mọ lára.

O yẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ Oṣelu Accord ati ijọba ipinlẹ Osun fun awọn Ọlọpaa laaye lati ṣe iwadii lori iṣẹlẹ naa - Alaga ijọba ibilẹ Ilobu labẹ APC

BBC News Yoruba kan si Amofin Adegoke Ogunsola to jẹ alaga ijọba ibilẹ Irẹpọdun labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, nibi wọn ti yinbon pa oloogbe Ezekiel Ọlapade.

Ninu ọrọ rẹ, Ogunsola salaye pe, ibanujẹ nla ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun nigba ti oun gbọ.

O ni o yẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ Oṣelu Accord ati ijọba ipinlẹ Osun fun awọn Ọlọpaa laaye lati ṣe iwadii lori iṣẹlẹ gbogbo t'oun waye lemọlemọ.

Ogunsola tun gba awọn ọmọ ẹgbẹ oselu alatako naa ni imọran pe ki wọn maṣe kọjú ija si ẹgbẹ oṣelu APC abi ẹgbẹ oṣelu miran lori rogbodiyan naa.

O tún tẹsiwaju pe lori awuyewuye ta lo jẹ ko ni awọn alaga ibilẹ laarinPDP ati APC.

O ni ko si idajọ to sọ pe ki awọn alaga APC mase lo ọdun mẹta to yẹ ki awọn lo ni ọọfisi.

"Ootọ ni pe ile ẹjọ gíga to fidi kalẹ ni Ilu Osogbo da ẹjọ ti a gbe lọ, lati jẹ ka lo saa wa pe ni ọẹfisi kowa wa gẹgẹ bii alaga ijọba ibilẹ labẹ ẹgbẹ oselu APC.

Sugbọn ile ẹjọ giga naa da ẹjọ wa nu, eleyi lo mu ki a tẹsiwaju lati gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ lori idajọ ile ẹjọ giga naa.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ko ti dajọ lori ẹjọ ti a gbe ka iwaju rẹ, ti gomina Ademola Adeleke fi sọ pe ki a kuro ni ọọfisi koowa wa."

Ki ni ohun ti ijọba Ipinlẹ Osun sọ lori rogbodiyan naa?

Kọmisọna fun eto Iroyin nipinlẹ Osun, Kolapo Alimi salaye pe, ẹni to da wahala ati rogbodiyan yii silẹ ni gomina ana nipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola.

O ni oun lo wa ni idi gbogbo ọrọ naa.

Alimi ni Oyetola n hu iwa yii tori pe o jẹ aburo si Aarẹ Bola Tinubu, o si n lo anfaani naa lati da omi alaafia ipinlẹ ọsun ru.

"Ni ọdun 2022 ni kete ti wọn pari idibo si ipo gomina nipinlẹ Osun tan, ti gomina ana Oyetola, padanu ibo naa, lo sẹsẹ roju raye lati seto idibo awọn alaga ijọba ibilẹ eyi ti ko ba ofin mu rara.

Awọn alaga ijọba ibilẹ naa ni asiko wọn ti pari lati inu osu Kẹwa ọdun 2025 ṣugbọn ti wọn tun gba ile ẹjọ lọ pe, awọn ko ti lo akoko igba ti o yẹ ki awọn ko lo tan.

Ile ẹjọ giga to wa niluu Osogbo ni wọn gbe ẹjọ naa lọ, ṣugbọn ni ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ naa da ẹjọ wọn nu wi pe, wọn ko ni ẹtọ labẹ ofin mọ lati tun tẹsiwaju nigba ti asiko wọn ti pari lati inu osu Kẹẹwa ọdun 2025

Wọn tun gba ile ẹjọ kotẹmilọrun lọ, eyi si lodi labẹ ofin."

Alimi tun tẹsiwaju pe rogbodiyan ti ko fi ọkan ara Ilu balẹ lo n waye lati ọdọ awọn ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ ọsun.

O ni wọn n lo awọn janduku lat da ilu ru ni gbogbo igba, eyi ti o si mu ki ọpọlọpọ ẹmi eeyan sọnu , tawọn miran si wa ni ile iwosan lọwọ lọwọ bayii.

O wa fi da gbogbo olugbe ipinlẹ Osun loju pe, ki wọn lọ fi ọkan wọn balẹ pe, gomina Ademola Adeleke ti gbe igbesẹ to le bori rogbodiyan naa.

A ti fun ijọba Osun ati apapọ ni gbedeke ọjọ diẹ, ti wọn ko ba ri ojutu si gbogbo rogbodiyan yii, a ṣe iwọde ti ko ni ọjọ kakiri Ipinlẹ Osun - Ajafẹtọẹni

Yahaya Ademola, ẹni to jẹ ajafẹtọ ọmọniyan ni Iluu Osogbo sọ pe, gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ kakiri Ipinlẹ Osun jẹ ohun to buru ju, to si tun jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ ju lọ.

O ni ninu iwoye ti oun, Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Osun ko ṣe iṣẹ kankan lori iṣẹlẹ ibi to n waye lemọlemọ naa rara.

"A ti kọ lẹta si ọga agba pata fawọn Ọlọpaa ni orilẹ-ede Naijiria lati gbe Kọmisọna Ọlọpaa Ipinlẹ Osun kuro ṣugbọn a ko ti ri esi kankan lati igba naa.

A ti fun ijọba ipinlẹ Osun ati ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ diẹ, ti wọn ko ba ti ri ojutu si gbogbo rogbodiyan naa, a ṣe iwọde ti ko ni ọjọ kakiri Ipinlẹ Osun.

Awọn oloko ki yoo le lọ si oko ati ọlọja ki yoo le jade lati ta ọja lasiko naa."

Ki ni ileesẹ ọlọpaa sọ lori rogbodiyan to n waye ni Osun?

Abiodun Ojelabi, agbẹnusọ fun awọn Ọlọpaa ipinlẹ Osun sọ pe kọmisọna ko dakẹ lori iṣẹlẹ idaluru gbogbo to n waye naa.

Ojelabi ni awọn Ọlọpaa n ṣiṣẹ wọn bo ṣe yẹ, ati pe, ọpọ awọn awọn afurasi adaluru lo wa ni ahamọ ọlọpaa.

O fikun pe awọn ọ̀lọpaa ko si ti da iṣẹ duro lori iwadi nipa ọmọ ti wọn yinbọn pa rara.

Abiodun Ojelabi, wa rọ gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Osun lati wa ni oju ni alakan fi sọri lasiko yii.

O wa fi ọwọ gbaya pe ki wọn lọ fi ọkan balẹ tori gbogbo awọn janduku naa ni ọwọ ofin yoo tẹ.