You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìtàn Mánigbàgbé: Ohun mẹ́rìnlá nípa ọdún Bẹbẹ to máa ń wáyé fún ọdún mẹ́ta lẹ́yìn tí Aláàfin kan bá lo àádọ́ta ọdún lórí ìtẹ́
Nígbà ìwáṣẹ̀, ọdún kan to máa ń dùn, tó sì máa ń lárinrin nilu Oyo, ní ọdún kan tí wọn ń pè ní ọdún Bẹbẹ.
Aláàfin Ajiboyede to jẹ lẹ́yìn Ọba Ọrọmpọtọ wá lára àwọn Aláàfin tó ṣe ọdún Bẹbẹ, to dùn, tó sì lárinrin.
Àmọ́ ohun tó gbẹyin ọdún Bẹbẹ tí Aláàfin Ajiboyede ṣe lo sí jẹ Manigbagbe títí di òní torí ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tó gbẹyin rẹ.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ka a nínú ìwé ìtàn Yoruba ti Àlùfáà Samuel Johnson kọ, ọba Ajiboyede jẹ Aláàfin to ṣe àṣeyọrí lórí aleefa ṣùgbọ́n ó tún ní ìkà nínú.
Ohun pàtàkì tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọdún Bẹbẹ
- Gẹ́gẹ́ bí ìtàn náà ṣe sọ, ọdún Bẹbẹ, ní wọn tún máa ń pe ni odun ikú tàbí ìsìnkú.
- O sì jẹ ọdún tí Aláàfin kan máa ń ṣe lasiko to bá lè ní àádọ́ta ọdún lórí aleefa, èyí tí a tún lè pé ní ọdún Júbílì.
- Ọdún mẹta gbáko sì ni wọn máa ń fi ṣe ọdún Bẹbẹ, irú ọdún báyìí kò sì wọ́pọ̀ nílẹ̀ Yorùbá.
- Lásìkò ọdún Bẹbẹ, ànfààní wá láti sọ ohunkóhun tó bá wù ọ, tàbí ṣe ohunkóhun, tí kò sì ọlọ́pàá tàbí ẹnikẹ́ni tí yóò bí ọ.
- Kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò fi ẹ̀sùn àbùkù, ibanilorukọjẹ tàbí idaluru kan ẹnikẹ́ni bóyá ọmọdé ni tàbí àgbàlagbà, ọkùnrin tàbí obìnrin, olówó tàbí tálákà lásìkò ọdún Bẹbẹ.
- Ìjà igboro, ogun, aáwọ ìbínú àti ìwà ìdààmú miran kò gbọ́dọ̀ wáyé lásìkò ọdún Bẹbẹ.
- Àlàáfíà nìkan ló máa ń jọba lásìkò ọdún Bẹbẹ torí kii sì ìgbẹ́jọ́ tàbí ìdájọ́ kankan fún ẹnikẹ́ni.
- Àwọn Ilari Aláàfin gan kii rí isẹ kankan ṣe lasiko ọdun yìí, wọn kò sì ní kan nípa fún ẹnikẹ́ni láti júbà wọn.
- Ẹnikẹ́ni kii san tàbí gba isakọlẹ àti owó Ibodè lásìkò ọdún Bẹbẹ.
- Aṣọ imurode tàbí aṣọ ọdún àti aṣọ ayẹyẹ làwọn aráàlú máa ń wọ lásìkò ọdún Bẹbẹ.
- Asiko ijo, ilu ati àríyá sise ni asiko ọdún Bẹbẹ, tí àwọn ará oko àti ìlú kekeke yóò sí sílú Oyo láti ṣe ọdún náà, tí gbogbo ìlú yóò sì máa dùn yungba fún àríyá.
- Gbogbo àwọn ọba ìlú kekeke, Baalẹ àti olórí ìlú ni yóò wá máa kí Aláàfin kú oriire, wọn yóò máa jó, wọn yóò máa yọ pé ó pe àádọ́ta lórí ìtẹ́ àwọn baba ńlá rẹ.
- Asiko ọdún Bẹbẹ yìí ni àwọn ènìyàn yóò máa ko ẹ̀bùn wá fún Aláàfin ni ọ̀pọ̀lọpọ̀, bí wọn sì ṣe ń fún Aláàfin ni ẹbun, ní àwọn náà yóò máa gba ẹbun ni oriṣiiriṣii.
- Gbogbo àwọn ohun mèremère ni wọn yóò fi dárà sí ayika ààfin láti jẹ kó dun wo, tí àwọn igi àti àárín ìlú yóò sì wọ onírúurú ọ̀ṣọ́ lásìkò ọdún Bẹbẹ.
Ohun tó burú jáì nípa ọdún Bẹbẹ
Yoruba ni kò sí ohun tó dára, tí kìí ni àbùkù rárá, bẹ́ẹ̀ náà ni ọdún Bẹbẹ jẹ.
Ìdí ni pé lásìkò ọdún Bẹrẹ yìí, èèyàn ni wọn máa ń pa láti fi ṣe ìrúbọ fún Odùduwà, tíí ṣe babanla Yoruba.
Bákan náà, gbogbo ọba tó ti jẹ lẹ́yìn Odùduwà ni wọn yóò tún fi ẹ̀jẹ̀ èèyàn rúbọ fún lásìkò ọdún náà.
Èèyàn méjì méjì ni wọn yóò fi rúbọ fún ọba kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ lẹ́yìn Odùduwà lásìkò ọdún Bẹbẹ
Àwọn ẹ̀jẹ̀ èèyàn yìí ni wọ́n yóò dapọ mọ ẹ̀jẹ̀ ọpọlọpọ ẹran tí wọn pa, tí wọn yóò sì dá sórí ilẹ̀.
Orí ẹ̀jẹ̀ yìí ni Aláàfin àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ yóò ti máa jo ijo etutu, ìgbésẹ̀ yìí sí lo lágbára julọ fún ètùtù àti ìdúpẹ́ Lásìkò ọdún ọ̀dún Bẹbẹ.
Idi si rèé tí wọn tún ṣe máa ń pe ọdún Bẹbẹ ni ọdún ikú tàbí ìsìnkú.
Ohun tó tún jẹ́ ìyàlẹ́nu nípa ọdún Bẹbẹ ni pé àwọn Aláàfin díẹ̀ to ṣe ọdún yìí, tí wọn lé ní aadọta ọdún lórí ìtẹ́, máa ń tètè kú ní kété tí wọn ba ṣe ọdún Bẹbẹ tan.
A sì lè ṣe àpèjúwe ọdún Bẹbẹ yìí bíi ọdún tí wọn ń ṣe láti sàmì ìparí ṣáá ọlọdun pipẹ Aláàfin kan lórí ìtẹ́.
Ọdun Bẹbẹ lẹyin fun Aláàfin Ajiboyede, Arẹmọ rẹ, Osemolu kú, Ọba pa gbogbo èèkànlú to wa bá kẹ́dùn
Aláàfin Ajiboyede náà lo aadọta ọ̀dún aleefa, to si se ọdún Bẹbẹ.
Àmọ́ ni kété to parí ọdún Bẹbẹ tán, ní Arẹmọkunrin Aláàfin Ajiboyede, tí orúkọ rẹ ń jẹ́ Osemolu, fo sanlẹ, to si jáde láyé.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn yà wá sí ààfin láti bá Aláàfin Ajiboyede daro ikú ọmọ rẹ̀ ṣùgbọ́n ohun ìyàlẹ́nu lo jẹ pe ṣé ni ọba náà pàṣẹ pé kí wọn pa àwọn èèkànlú àti ọ̀tọ̀kùlú ìlú to wa bá kẹ́dùn.
Awijare Aláàfin náà ni pé ojú ayé lásán làwọn èèyàn náà wà ṣe, ikú ọmọ rẹ̀ kò dùn wọn dé ọkàn.
O ni òun ń gbọ́ oòrùn oúnjẹ ní ọwọ́ gbogbo wọn eyi to túmọ̀ sí pé wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹun tán, ní wọ́n ń bọ̀ wa si ààfin láti wa ba òun kẹ́dùn.
Aláàfin Ajiboyede tọrọ àforíjìn lẹ́yìn tí Àáfà kan ṣe waasi fun pé ìwà ìkà lo wu
Ṣé ni gbogbo ìlú dàrú lórí ìwà tí Aláàfin Ajiboyede hu yìí, pàápàá lẹ́yìn tí Àáfà kan to wa lati ilẹ̀ Tapa ṣe wáàsí fun un.
Àáfà kan tí wọn ń pe ni Baba Kewu lo rán Ọmọ rẹ̀, tó ń jẹ Baba Yigi wa láti ilẹ Tapa, pé ko sọ fún Aláàfin pé ìwà ìkà lọ hu.
Baba Yigi ni bí Aláàfin Ajiboyede ṣe gbẹ̀san ikú ọmọ rẹ̀ lára àwọn aláìṣẹ̀ jẹ ìwà ìkà torí ikú ọdọ Ọlọ́run wa lo pa ọmọ rẹ.
Wáàsí náà wọ Aláàfin yìí ni akinyẹmi ara, to si ri pe oun ti si iwa hu.
O wa pé gbogbo èèyàn ìlú Oyo papọ, to si tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ wọn fún ìwà ìkà tó hu náà.
Asiko to sì ń gbaradi láti kúrò ní ìlú Oyo Igboho tó wà, láti kó lọ sílú Oyo òde òní, ní Àlàáfín Ajiboyede tẹri gbaṣọ.
Ohun sì ni Aláàfin kẹrin to jẹ nilu Igboho, òun náà sì ni wọn sìn gbẹyin sínú ìlú náà.