Sunday Igboho ti wọnú igbó bíi ẹ̀ẹ̀mẹrin, a kò tíì rí àwọn tí wọn jí gbé, ₦150m táwọn ajínigbé bèèrè là ń wá - Ọba Igboho

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ni opin ọsẹ to kọja yii ni iroyin nipa ijinigbe ati ipaniyan to n waye ni Oke Ogun ipinlẹ di ohun to lu si gbogbo aye.

Eyi ko ṣẹyin fidio kan to gba ori ayelujara nibi ti Sunday Adeyemọ ti ọpọ mọ si Sunday igboho ti n ba olori awọn Fulani sọrọ ni aafin Ọba ilu Igboho to si n fi itara han lori bi eto aabo ṣe ti mẹhẹ ni ilu naa.

Igboho fẹsun kan pe awọn Fulani ni awọn afurasi to n ji awọn eeyan gbe ni agbegbe naa ati pe oun ko ni kawọ rọ ni ilu baba oun, ki oun maa wo awọn ajinigbe naa lati maa da nnkan ru.

Igboho fẹsun kan pe awọn ajinigbe to gbe alaboyun atawọn ọmọ rẹ beere fun owo itusilẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ amọ niṣe ni wọn pa ẹni to gbe owo lọ fun wọn lai tu awọn eeyan wọn silẹ.

Ọọdunrun miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun lati gba itusilẹ awọn eeyan naa ki wọn to dinku si aadọjọ miliọnu naira.

"A ko tii ri awọn ti wọn ji gbe ti a n wa, awọn ajinigbe ni awọn maa gba aadọjọ miliọnu naira"

Oniruuru awuyewuye lo ti waye lori fidio naa, tawọn ileeṣẹ iroyin kan sig be iroyin pe awọn eeyan naa ti gba itusilẹ lẹyin ti Igboho dunkoko mọ awọn Fulani naa amọ ti alaga ijọba ibilẹ Oorelope ati ileeṣẹ ọlọpaa ti jiyan iroyin naa.

Nigba ti BBC News Yoruba kan si ọkan lara awọn Ọba ilu Igboho, Ona Onibode Igboho, Ọba Abdulrasheed Adetoyese Jaiyeola Kẹta fidi rẹ mulẹ pe awọn to wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa ko i tii gba itusilẹ.

Ọba alaye naa ni aadọjọ miliọnu naira ti wọn n beere fun gẹgẹ bi owo itusilẹ ni awọn ṣi n wa, ti awọn ko si ri yanju titi di asiko yii.

"A o tii ri awọn ti wọn ji gbe ti a n wa, wọn ṣi duro lori pe awọn maa gba aadọjọ miliọnu naira naa ṣi ni.

"Sunday Igboho ti wọ inu igbo bii ẹẹmẹrin lẹnu igba to de pelu awọn eeyan rẹ, wọn o tii ri wọn."

"Sunday Igboho ba awọn olori Fulani sọrọ lati fi ṣẹru bawọn boya wọn maa ri awọn eeyan wọn ba sọrọ lati dena iwa ibajẹ"

Nigba to n sọrọ lori fidio to gba ayelujara nibi ti Sunday Igboho ti n ba awọn olori Fulani sọrọ, Ọba naa ni awọn gbe igbesẹ naa lati le wa ojutuu sọrọ awọn ajinigbe ti wọn n ṣọṣẹ ni agbegbe naa ni.

O ni oun to jẹ ki Sunday Igboho pe ipade naa ko ṣẹyin pe awọn Fulani ni awọn afurasi to n ji eeyan gbe ni agbegbe naa, ti awọn si gbe igbesẹ naa lati fi ṣẹruba wọn boya wọn maa ri awọn eeyan wọn ba sọrọ lati dena iwa ibajẹ.

O fi kun pe igbagbọ wa pe awọn Fulani to n gbe ni agbegbe Oke Ogun atawọn to n ṣiṣẹ ibi le ni ajọṣepọ nipasẹ pe iran kan naa ni wọn ati pe ọja Kara to wa ni agbegbe naa mu ki awọn Fulani maa pọ si nibẹ.

Ọba naa kọminu pe lodi si aye igba to jẹ pe awọn ọba maa n mọ igba ti alejo ba wọ ilu, o ni idasilẹ awọn ọja Kara ti ijọba n da silẹ kaakiri gbogbo ilu jẹ ko ṣoro fun awọn araalu lati le mọ nigba tawọn ajoji ba ti wọ ilu ati lati mojuto irufẹ awọn eeyan to n wọ agbegbe wọn.

"Ṣe bi nnkankan la maa sọ fun wọn lati dawọ awọn iwa ibi ti wọn n wu?

Wọn ni ọrọ aje ni gbogbo ibẹyẹn, ta ba sọ pe a maa le wọn kuro nibẹ yẹn, wọn o ni fẹ ki ọrọ aje wọn bajẹ, wọn a le mọ bi wọn ṣe maa ba awọn ọmọ wi lati dawọ iṣẹ ibi duro."

Ọba Ọba Abdulrasheed Adetoyese woye pe igbese ti Sunday Igboho ko buru nitori awọn eeyan ilu rẹ lo n gbiyanju lati da aabo bo, ti ko si ni dake maa woran ki nnkan maa bajẹ loju rẹ.

Ẹ kilọ fun Igboho lati ye dunkoko mọ awọn Fulani mọ, kii ṣe gbogbo iran Fulani ni ọdaran - Ẹgbẹ Fulani

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn Fulani kan, the Concerned Fulani People of Nigeria ti kepe aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn ọba mii nilẹ Yoruba ti ṣekilọ fun Sunday Igboho lori ọrọ to sọ nipa awọn Fulani.

Ẹgbẹ naa ni ohun ti Igboho sọ nipa awọn ẹya Fulani to n gbe ni ipinlẹ Oyo ku diẹ kaato nitori o ko gbogbo iran awọn pọ ni.

Atẹjade ti adari ẹgbẹ naa, Ibrahim Barkindo Chubado fi sita lọjọ Aiku sọ pe pipe gbogbo Fulani ni ọdaran fun iwa ti awọn diẹ ninu wọn n wu le dena igbepọ alaafia to ti n waye ni agbegbe naa fun igba pipẹ laaarin awọn Yoruba ati Fulani ni agbegbe ọhun.

Ẹgbẹ naa tẹmpelẹmọ pe awọn iran Fulani ko fi aaye gba iwa ijinigbe, igbeṣumọmi atawọn iwa ọdaran mii ati pe ko yẹ ki wọn maa fi iwa ibajẹ kan kan gbogbo iran tabi ẹya.

O ni awọn Fulani to wa kaakiri orilẹ ede Naijiria ni wọn maa n huwa ọmọluabi, ti wọn si maa tẹle ilana ati ofin, ti ko si yẹ ki wọn maa di ẹbi awọn ọdaran ru gbogbo wọn.