Kí ló mú àwọn awakọ̀ tírélà dí ojú ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Ore lọ dé Benin pa? Àlàyé rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ eeyan to koju iṣoro airi ọna gba bi awọn awakọ tirela ṣe di oju ọna marosẹ Eko-Ore si Benin pa l'Ọjọru ko ni i gbagbe iṣẹlẹ naa kia pẹlu ohun ti oju wọn ri.

Sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ nikan kọ ni ti ọjọ naa, bi ko ṣe pe gbogbo rẹ duro pa lẹyin ti awọn to n wa tirela loju ọna naa fi ọkọ wọn di ọna pa lati ibi agbegbe Oniparaga lọ.

Ọpọ awakọ ero, awakọ adani atawọn ero ọkọ lo foju wina idaamu nla latari iṣẹlẹ naa fun ọpọlọpọ wakati.

Bi wọn ṣe wi, ohun ti wọn tori rẹ di ọna pa ko ṣẹyin ẹsun ti wọn fi kan awọn ọlọpaa ipinlẹ Ondo.

Ki ni ọlọpaa Ondo ṣe fawọn awakọ naa ti wọn fi di ọna pa?

Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye, ifẹhonu han ni awọn awakọ tirela naa fi ọkọ ti wọn fi di oju ọna pa ṣe.

Awijare wọn si ni pe wọn ni awọn ọlọpaa kan ti wọn n ṣiṣẹ loju ọna yii ti sọ awọn awakọ tirela di ohun ti wọn n re jẹ nipa owo gbigba.

Wọn fi kun un pe awọn agbofinro naa tun maa n dunkooko mawọn lai ni idi kan.

Eyi ni iroyin sọ pe o fa a ti lilọ bibọ ọkọ ṣe duro patapata lawọn asiko ifẹhonuhan yii, ti awọn eeyan si bẹrẹ si i ṣe fidio ohun to n ṣẹlẹ, ti wọn n pin in ka lori ayelujara.

Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo sọrọ

Ninu alaye Kọmandi ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori iṣẹlẹ yii ni wọn ti sọ pe ki i ṣe nitori pe ọlọpaa n gbowo aitọ lọwọ awọn awakọ ni wọn ṣe fi ẹhonu han.

Wọn ni irọ gbuu ni pe nitori ọlọpaa ni awọn awakọ ṣe di ọna pa.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ondo, DSP Abayomi Jimoh, fi sita lori iṣẹlẹ yii, ṣalaye pe iwadii fi han pe awakọ tirela kan lo ni gbolohun asọ pẹlu awọn ọlọpaa lasiko ti wọn n ṣiṣẹ wọn loju ọna yii.

Ede aiyede naa lo pada di ohun to di oju ọna pa bo ṣe sọ.

Gẹgẹ bi atẹjade awọn ọlọpaa ṣe wi, awakọ to wa tirela naa mọ-ọn-mọ fi ọkọ rẹ di oju ọna pa, eyi to fa sunkẹre fakẹrẹ.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo fi da yin loju, pe iṣẹlẹ yii ko ni nnkan kan lati ṣe pẹlu owo ti wọn ni awọn ọlọpaa kan n gba lọwọ awọn awakọ.

"A rọ araalu lati ma ṣe gba eyi gbọ."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ọlọpaa naa wi.

Lati koju wahala naa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Felix Ohagwu, tete paṣẹ pe kawọn agbofinro lọ si oju ọna ọhun, ki wọn si ri i pe ohun gbogbo pada sipo.

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ṣi n koro oju si iṣẹlẹ yii, pẹlu bo ṣe jẹ pe oju ọna ọhun ko fi bẹẹ rọgbọ lati gba mọ, latari awọn afurasi agbebọn ti iroyin sọ pe wọn n dọgbọn sa sawọn ibi kan loju ọna yii.

Wọn ni fifi ẹmi ọpọ eeyan wewu ni iṣẹlẹ yii jọ.