Ṣé òótọ́ ni wọ́n fi ẹlikọ́pítà kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso lọ sí Kaduna?

Gomina Seyi Makinde pẹlu mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe

Oríṣun àwòrán, Facebook/Seyi Makinde

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọ pe irọ ni iroyin kan to n lọ nigboro pe wọn ti fi ọkọ ofururu ẹlikọpita gbe awọn akẹkọọ ati olukọ ti awọn agbesunmọmi jigbe ni Ahoro-Esiele ati Yawota lọ si ipinlẹ Kaduna.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, DSP Ayanlade Olayinka lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin.

Ọlọpaa ni irọ ni ohun to wa ninu fidio kan to sọ pe bẹẹ bi ọrọ ri ati pe awọn to ṣe fidio ọhun mọọmọ gbe jade lati ṣi araalu lọna ni.

O ni "Ileeṣẹ ọlọpaa fẹ jẹ ki araalu mọ pe iṣẹ takuntakun n lọ lọwọ lati doola awọn eeyan naa.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, ni ajọṣepọ pẹlu awọn ileeṣẹ eto abo mii ko dakẹ iṣẹ lati ri daju pe gbogbo awọn ti wọn ji gbe naa ni wọn pada wale layọ ati alaafia lati darapọ mọ mọlẹbi wọn ki a si fi ṣikun ofin mu awọn to ṣiṣẹ laabi naa.

"Irufẹ iwa bẹẹ ko bojumu, bẹẹ lo tun n da ibẹru sọkan awọn araalu"

"Bi awọn eeyan kan ṣe n mọọmọ pin iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa iṣẹlẹ yii lati jẹ ki araalu sọ ireti nu ninu ọlọpaa n kọ ileeṣẹ ọlọpaa lominu.

"Irufẹ iwa bẹẹ ko bojumu, bẹẹ lo tun n da ibẹru sọkan awọn araalu, o n ṣi awọn araalu lọna bẹẹ lo n di iṣẹ awọn eleto aabo lọwọ."

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo wa fi atẹjade naa kilọ fun gbogbo awọn to n pin iroyin ẹlẹjẹ kirii pe ki wọn ki ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ.

Ayanlade ni ẹnikẹni ti ọwọ agbofinro ba tẹ pe o n pin iroyin ẹlẹjẹ kiri nipa iṣẹlẹ naa lọna ati mu ki araalu sọ ireti ni ninu awọn agbofinro yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ipinlẹ Oyo ki wọn lọ fi wọn ọkan wọn balẹ ki wọn si maa ṣatilẹyin fun awọn agbofinro ninu iṣẹ wọn.

O tun rọ araalu ki wọn maṣe maa gba eyikeyi iroyin gbọ ayafi eyii to ba jade lakata awọn alaṣẹ nikan ki awọn kọlọrọsi ẹda kan ma ba a ṣi wọn lọna.

Nnkan bii ogoji ọjọ sẹyin ni agbebọn yabo ile ẹkọ meji ni Ahoro-Esiele ati Yawota ti wọn si ji akẹkọọ mọkandinlogoji ati oluke meje gbe lọ.

Wọn yinbọn lu olukọ kan lẹsẹkẹsẹ, wọn tun ge ori olukọọ mii ninu igbo ti wọn ko wọn lọ.