Àwọn ajínigbé tu aláboyún àtàwọn ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́yìn tí Sunday Igboho fún wọn ní gbèdéke wákàtí méjì

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Instagram
Idile kan to wa ni ahamọ awọn ajinigbe ni Ilu Igboho, ipinlẹ Oyo ti gba itusilẹ leyin ti Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho, ẹni to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation fun awọn ajinigbe naa ni gbedeke wakati meji lati tu awọn ẹbi naa silẹ.
Eyi mu ki awọn eeyan ilu naa bẹrẹ si ni fo fayọ, ti inu wọn si n n dun si itusilẹ awọn araalu ọhun, ti wọn si fi ijo pade awọn to gba itusilẹ naa.
Fidio kan to wa lori ayelujara ṣafihan bawọn eeyan ṣe n fi ijo pade alaboyun kan, aburo rẹ atawọn ọmọ rẹ ti wọn gba itusilẹ kuro ni ahamọ awọn ajinigbe to n da agbegbe naa laamu.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti Sunday Igboho ṣekilọ fawọn olori awọn Fulani to n gbe ninu ilu Igboho lori bi ijinigbe ṣe n peleke si ni agbegbe naa.
Fidio kan to wa lori ayelujara ṣaaju kawọn idile naa to gba itusilẹ ṣafihan ibi ti Sunday igboho ti n ba awọn olori awọn Fulani sọrọ ni aafin Ọba ilu Igboho to si n fi itara han lori bi eto aabo ṣe ti mẹhẹ ni ilu naa.
Igboho fẹsun kan pe awọn Fulani ni awọn afurasi to n ji awọn eeyan gbe ni agbegbe naa ati pe oun ko ni kawọ rọ ni ilu baba oun, ki oun maa wo awọn ajinigbe naa lati maa da nnkan ru.
O fẹsun kan pe awọn ajinigbe to gbe alaboyun naa atawọn ọmọ rẹ beere fun owo itusilẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ amọ niṣe ni wọn pa ẹni to gbe owo lọ fun wọn lai tu awọn eeyan wọn silẹ.
Ọọdunrun miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun lati gba itusilẹ awọn eeyan naa ki wọn to dinku si aadọjọ miliọnu naira.
Igboho ni awọn ajinigbe ko ni maa ṣọṣẹ ni ilu abinibi oun ki oun maa woran ati pe eyi ti wọn ṣe yii ni wọn gbọdọ fi fopin si iwa bẹẹ.
O ni oun ko ni gba ki wọn maa ṣe awọn nnkan ti oun n ja fun opin rẹ ni ilu mii lati maa waye ni ilu baba oun ati pe awọn ajinigbe naa maa kan idin ninu iyọ ti wọn ko bat u awọn eeyan naa silẹ laaarin wakati meji.
O fi kun pe nitori ọba ilu awọn ko fẹ ki ọrọ naa mu ija dani ni oun fi n ba awọn eeyan naa sọrọ ni tubi n nudi, ti oun n fi suuru ṣe ohun gbogbo.
Nigbẹyin, awọn adari Fulani ni agbegbe naa gba itusilẹ alaboyun naa atawọn ọmọ rẹ ki gbedeke wakati meji ti Sunday Igboho fun wọn to pe.

























