Àwọn òṣìṣẹ́ adóòlà ẹ̀mí yọ èèyàn 26 lábẹ́ ilé alájà mẹ́ta tó wó l'Eko, èèyàn mẹ́jọ kú

Oríṣun àwòrán, NEMA/X
Ajọ LSFRS to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ti doola eeyan mẹrindinlọgbọn nigba ti eeyan mẹjọ padanu ẹmi wọn nibi ile alaja mẹta to wo lagbegbe Alakija lopopona Ojo si Satellite Town l'Ọjọbọ niluu Eko.
Ọga agba LASEMA, Ọmọwe Olufemi Oke-Osanyintolu, naa sọ iye eeyan to ku nibi iṣẹlẹ naa wi pe mẹjọ ni wọn.
O ni awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi si n tẹsiwaju lati yọ awọn eeyan labẹ ile to wo naa.
Ọmọwe Oke-Osanyintolu ni awọn yoo tun maa fi to araalu leti bi nnkan ṣe n lọ nibi iṣẹlẹ naa.
Ajọ LSFRS sọ pe ilegbee ni ile ọhun eyi tawọn eeyan n gbe inu rẹ lasiko ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Eeyan mẹwaa ni wọn kọkọ yọ labẹ ile to wo naa, wọn si ti ko wọn lọ sile iwosan fun itọju.
Ajọ naa ni iṣẹ si n lọ lati yọ awọn eeyan mii ti wọn le ha sabẹ ile to wo naa.
Àjọ LSFRS sọ pé ní nǹkan bíi ago méjìlá ọ̀sán kùdíẹ̀ kó lù ni àwọn gba ìpè wí pé ilé kan ti dàwó ní Satellite Town.
Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Margaret Adeseye, sọ pé lọ́gán làwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà ti dé ibẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìdóòlà ẹmí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀
Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ti ile kan dawo niluu Port Harcourt nibi ti ẹnikan ti padanu ẹmi rẹ nipinlẹ Rivers.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post

























