Àwọn òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ní BCOS n'Ibadan figbe ta lórí owó ìfẹ̀yìntì tíjọba jẹ wọ́n

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹfẹyinti nileeṣẹ agbohunsafẹfẹ tipinlẹ Oyo, iyẹn Broadcasting Corporation of Oyo State (BCOS) ti ke gbajare si ijọba lati san awọn owo ifẹyinti wọn.
Gbogbo awọn oṣiṣẹfẹyinti naa lo pariwo sita l'Ọjọbọ, ọsẹ yii, nibi ipade ti wọn ṣe ninu ọgba ileeṣẹ BCOS to wa niluu Ibadan.
Nibẹ ni wọn ti n beere fun owo ifẹyinti oṣu mẹrin, awọn afikun ẹtọ owo ifẹyinti, to fi mọ awọn owo ti wọn n yọ lori owo oṣu wọn, eyi ti wọn ni ijọba ko san lati bi oṣu mẹrin sẹyin.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, lẹyin ipade naa, alaga ẹgbẹ naa, Ọgbẹni Ayorinde Adisa sọ pe ko yẹ ki awọn ma daamu lati gba owo ifẹyinti wọn, lẹyin ọpọ ọdun ti wọn fi ṣiṣẹ sin ijọba.
Adisa sọ pe ko si nnkan to n lọ kaakiri agbaye, ti wọn kii jẹ ki araalu mọ, nipasẹ fifi ara jin fun iṣẹ iroyin ati ilu lapapọ.
O ni tọsan-toru lawọn fi n ṣiṣẹ, nigba idibo, ijamba, iṣoro, ati oniruuru eto, ati pe lawọn igba miran, awọn kii raaye mọlẹbi wọn.
O tẹsiwaju pe awọn ni wọn fi oogun ati ẹjẹ wọn kọ ileeṣẹ BCOS si ipo to wa lonii, fun idi eyi, o lawọn gbọdọ jeere iṣẹ ọwọ wọn.
Adisa sọ bakan naa pe pupọ ninu wọn lo n koju awọn iṣoro oniruuru, latari bi awọn ṣe farajin fun iṣẹ, ti awọn si nilo owo lati fi tọju ara wọn.
O ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn ni wọn ko ni ohun miran tabi iṣẹ miran ti wọn n ṣe, to jẹ pe owo ifẹyinti yii nikan ni wọn gbojule.
O sọ pe bi ẹni fi wọn sinu ebi ati iya ni bi ijọba ko ṣe san owo ifẹyin naa fun wọn, nitori pe ojoojumọ ni ebi n pa awọn mọ inu ile.
"Asiko to yẹ ka maa jẹgbadun ree"
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe, asiko to yẹ ki awọn maa gbadun iṣẹ ti wọn fọjọ aye wọn ṣe, ni ijọba wa n fi ẹtọ wọn dun wọn.
O ni iye owo ounjẹ, oogun lilo, owo ile, owo ọkọ wiwọ ti lọ soke ni ilọpo mẹta, to si n ṣakoba fun awọn.
O sọ pe ipo ti eto ọrọ aje wa nilẹ Naijiria lasiko yii n kọ awọn lominu pẹlu bi wọn ko ṣe ri owo ifẹyin ati ẹtọ wọn gba.
Ọpọlọpọ lẹta lati kọ si ijọba
Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe ọpọlọpọ lẹta ni awọn ti kọ si ijọba lati le fun wọn ni ẹtọ wọn, ṣugbọn to ni ijọba ko ri ti wọn ro.
O lawọn tun ba awọn alakoso ileeṣẹ BCOS ṣe ipade, lati le ri sọrọ awọn, ṣugbọn to ni ijakulẹ ni awọn ba pade.
Nigba to n sọrọ lori ohun ti wọn n fẹ, o sọ pe awọn fẹ ki ijọba gbe wọn kuro labẹ iṣaokso BCOS, ki wọn si gbe wọn sabẹ ileeṣẹ to n ri sọrọ owo ifẹyintin oṣiṣẹ.
O nibẹ lawọn nigbagbọ pe owo ifẹyinti awọn yoo ti maa wọle sapo awọn loorekoore, lai daamu.
Adisa wa fi imọriri rẹ han si Gomina Seyi Makinde bi ko ṣe fọrọ awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹfẹyinti ṣere, to si n pese gbogbo awọn ohun amayedẹrun fun wọn.
O ni Gomina Makinde ti fi han pe oun nifẹ awọn oṣiṣẹ ati awọn oṣiṣẹ fẹyinti, to si lawọn nigbagbọ pe yoo da si ọrọ awọn laipẹ.


























