"Bẹ́rẹ́dì ni ọkọ mi lọ rà fún àkọ́bí wa, tí wọ́n fi ṣá a pa ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìkómọ ọmọ wa kejì"
Ọjọ kẹtalelogun ọdọọdun ni ajọ isọkan agbaye ya sọtọ gẹgẹ bi ayajọ fun eto ilanilọyẹ nipa iya, osi ati idẹyẹsi ti awọn opo ati ọmọ wọn n koju ni awujọ kọọkan.
Bakan naa ni ayajọ naa wa lati pe akiyesi awọn eeyan si ọna lati se iranwọ fun awọn opo ati didẹkun hihu awọn iwa to le dakun isoro to n koju wọn lawujọ.
Loni ni ayajọ awọn opo lagbaye naa ko, idi si ree ti BBC News Yoruba se gbe fidio yii sita, eyi ti a se ni ọdun 2021 lati sami ayayjọ awọn opo to ko lonii.
Ninu iroyin yii la ti ri opo meji, Lydia Davies ati Ojo Bunmi Abolanle, ti wọn sọ iriri apanilẹkun ti wọn koju lẹyin ti ọkọ wọn ti jade laye.
Bakan naa ni awọn opo mejeeji yii sọ iru iya ati osi ti wọn la kọja pẹlu ipa ti idile ikọọkan wọn ko si igbe aye inira wọn.

Oríṣun àwòrán, Abosede Olawoye
"Burẹdi ni ọkọ mi lọ ra, ti wọn fi sa ni ada pa"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Akinwoye Davies Lydia Abosede tii se ọmọ bibi ilu Ijero Ekiti jẹ ọdun mẹẹdọgbọn nigba ti ọkọ rẹ, Segun Olawoye, jade laye.
O ni iku ọkọ oun waye ni ọsẹ to tẹle isọmọlorukọ ọmọ tuntun ti wọn bi.
"Isẹ aransọ ni ọkọ mi n se, o si maa n ra burẹdi bọ wa sile lati ibi isẹ to ba n bọ fun akọbi wa to jẹ ọkunrin.
Amọ ni ọjọ ti isẹlẹ to fa iku rẹ yii waye, ko ranti ra burẹdi yii, amọ bo se de lo ni oun fẹ lọ ra burẹdi fun ọmọ mi.
Ọmọ mi ọkunrin saba maa n tẹle baba rẹ jade, amọ ni ọjọ yii, o ni oun ko lọ, amọ n ko fura rara pe nnkan kan fẹ sẹlẹ ni.
Amọ nigba to lọ Burẹdi, o pẹ ko to de, mo ro pe o ya sile baba, o lọ gẹrun ni.
Nigba to ya, awọn kan gba geeti wa, mo ro pe awọn ole lo de, ti ẹru si ti n ba mi.
Nigba to ya, wọn fi tipa wọle, ti wọn si fi aworan ọkọ mi han mi, o wa ninu agbara ẹjẹ, wọn ni awọn eeyan kan lo sa lada.
Aago kan abọ ni asiko yii, mo si sare lọ gbe lọ sile iwosan, ti a si tọju rẹ titi fun ọdun kan ati osu mẹsan.
Lẹyin naa lo jade laye tori ọgbẹ ada naa ti se akoba fun egungun ẹyin rẹ."

Oríṣun àwòrán, Abosede Olawoye
"Atijẹ atimu ko rọrun fun emi nikan, ẹgbẹrun mẹrindinlogun naira ni mo n gba losu bii olukọ, ko san owo ile ẹkọ ọmọ kan debi rira ounjẹ tabi ki n lọ fi gba ile."
Abọsede tẹsiwaju pe ọkọ oun jiya, to si daamu pupọ, ko to jade laye.
O ni ki ọkọ oun to ku, ni oun ti n lọ gbe ni ọdọ iya ọkọ oun tori airi owo ile san, nigba to si ku tan, ibẹ naa lawọn n gbe.
"Iya ọkọ mi gbiyanju pupọ lati tọju wa, abiyamọ rere ni, o se iwọn to le se.
Amọ atijẹ atimu ko rọrun fun emi nikan, olukọ ni mi nile ẹkọ aladani, ibẹ naa si ni mo fi awọn ọmọ mi si.
Ẹgbẹrun mẹrindinlogun naira ni mo n gba losu, ko san owo ile ẹkọ ọmọ kan debi rira ounjẹ tabi ki n lọ fi gba ile."

"Ajorinmọrin ni isẹ ọkọ mi, to si maa n se tanki epo, bo se fi oolu lu oju tanki epo lo gbina eyi to pa a"
Ninu ọrọ tiẹ, Ojo Bunmi Abọlanle sọ pe ẹni ọgbọn ọdun ni oun wa nigba ti ọkọ oun jade laye.
O ni ọmọ meji ni oun bi fun, ti awọn mejeeji si jẹ obinrin.
"Ajorinmọrin ni isẹ ọkọ mi, to si maa n se tanki epo.
O se tanki epo fun awọn eeyan kan, amọ wọn da tanki epo naa pada pe o n jo.
Ọkọ mi wa wọnu tanki epo naa lọ lati jo ibi ti wọn lo n jo, amọ bo se fi oolu lu oju ibẹ ni tanki epo naa gbinna.
Gbogbo igbiyanju ọkọ mi lati jade sita ninu tanki naa lo nira tori bo se n fi ẹsẹ sori akasọ to gbe sinu tanki naa ni ẹsẹ rẹ n yọ.
Amọ o papa ri ẹna jade, ti wọn si gbe lọ sile iwosan sugbọn o ku lẹyin ọjọ keje to dele iwosan tori ina ti jo lara kọja aala."
Ojo Bunmi tẹsiwaju pe lati igba ti ọkọ oun naa ti jade laye ni oun ti n ko boju ati imu lati tọju awọn ọmọ.
"Lati igba naa ni mo ti n bawọn alakọwe tun inu ile se, tabi ki n maa bawọn fọ asọ.
Ẹni to ba ni ounjẹ nile yoo gbe fun mi, mo si tun maa n ro fufu ninu ile fun tita.
Ohun ti mo n se ree, ti mo fi n tọju awọn ọmọ mi.
Awọn obi mi ni ki n lọ ni ọkọ tuntun amọ mo sọ fun wọn pe n ko ni ọkọ kankan mọ.
Emi ati awọn ọmọ mi la dijọ n ko ara wa kiri titi di oni."

Igbe aye awọn opo jẹ mi logun, ti a ba n gbaruku ti wọn, Ọlọrun yoo tubọ bukun fun wa - Queen Abosede
Obinrin kan wa, Queen Abosede Tessy Show, maa n se iranwọ fun awọn opo yii ni ọdọọdun.
Oun naa salaye idi to fi n se bẹẹ ni ọdọọdun lati sami ayajọ ọjọ awọn opo lati ipasẹ ajọ kan ti kii se tijọba to da silẹ.
"Igbe aye awọn opo jẹ mi logun, mo si maa n fun wọn ni ohun ti mo ba ni.
Amọ mo ri pe o yẹ ka maa ro wọn lagbara ni, kii se ka fun wọn lowo ounjẹ lasan, eyi ti yoo mu ki wọn ni ọna ti owo yoo maa gba wọle lati tọju awọn ọmọ wọn.
Mo si mọ pe ti a ba n gbaruku ti awọn opo, Ọlọrun yoo tubọ maa bukun fun wa."






