You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kí ló mú kí Iyabo Obasanjo fi ẹgbẹ́ APC sílẹ̀ lẹ́yìn tó lulẹ̀ láti díje fún ipò gómìnà?
Sẹnetọ Iyabo Obasanjo Bello, ọmọ Oloye Olusegun Obasanjo to jẹ aarẹ Naijiria nigba kan, ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC bayii, lori ẹsun pe awọn aṣiwaju ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun ko huwa to tọ, wọn ko pọn oun le bii ọmọ ẹgbẹ gidi.
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bii oṣu diẹ sẹyin ni Iyabo Obasanjo kede pe oun fẹ dupo gomina ipinlẹ Ogun, ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Eyi ko pada bọ si i pẹlu bo ṣe jẹ pe Senetọ Olamilekan Adeola (Yayi) ni ẹgbẹ fa kalẹ fun ipo naa l'Ogun.
Iyabo ki Yayi ku oriire nigba naa, o si ni oun faramọ ipinnu ẹgbẹ, ṣugbọn ni bayii, obinrin naa ti sọ awọn idi kan ti ko fi fẹ ba APC ṣe mọ.
Bi wọn ko ba ti pọn eeyan le lagbo, afi ki eeyan fi agbo bẹẹ silẹ - Iyabo Obasanjo
Iwe kan ni Iyabo kọ si Alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun, Oloye Yemi Sanusi, ninu eyi to ti kede pe oun ko ṣe ẹgbẹ naa mọ, to si sọ awọn idi to fi gbe igbesẹ naa sibẹ.
Ninu iwe to kọ lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta ọdun 2026 si Alaga APC ni Iyabo ti koro oju si ilana ti wọn fi yan Yayi bii oludije ipo gomina Ogun.
O ni wọn ko tẹle ilana ẹgbẹ APC ti wọn fi yan an.
Gẹgẹ bi Obasanjo ṣe wi:
"Mo gba lati ti ẹnikẹni ti ẹgbẹ ba fẹnu ko le lori lẹyin, ṣugbọn wọn ko sọ fun mi ki wọn too yan Senetọ Adeola bii eni ti won fẹnu ko si.
"Wọn ko tun jẹ kawọn olutẹle mi kan wọle sibi ti wọn ti ṣeto naa, wọn ko iyan wọn kere.
"Sibẹ naa, mo gba abajade ohun ti ẹgbẹ sọ nitori iṣọkan, mo si ki Senetọ Adeola kuu oriire lojuu gbogbo aye lalẹ ọjọ yẹn naa."
Iyabo tẹsiwaju pe Yayi loun fẹ ba awọn eeyan oun ṣepade, lasiko ipade naa ni wọn si beere nnkan mẹta lọwọ rẹ.
O ni Yayi ṣeleri lati da wọn lohun laaarin ọsẹ kan, o ni oṣu meji lẹyin ipade naa, Yayi ko mu adehun rẹ ṣẹ.
"Ohun ti wọn ti ṣe fun mi latigba naa fi han bi wọn ko ṣe fẹ mi to, ti wọn ko si pọn mi le.
"Nigba ti wọn ba ti n fi apari iṣu han alejo, ile too lọ niyẹn.
"Fun idi eyi, mo n kuro ninu ẹgbẹ APC, nibi ti wọn ko ti fẹ mi."
Bẹẹ ni apa kan iwe ti Senetọ Iyabo Obasanjo kọ ṣe wi.
Ta a ni Iyabo Obasanjo-Bello?
Ọmọ bibi inu Oloye Olusegun Obasanjo ni Ojogbon Iyabo Obasanjo-Bello.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 1967 ni wọn bi i.
Dokita oniṣegun oyinbo to gboye lori àwọ̀ ara eeyan ni, ṣugbọn pupọ ninu asiko rẹ lo fi ṣe oṣelu.
Ṣaaju ni Iyabo Obasanjo ti ṣe kọmiṣanna fun eto ilera nipinlẹ Ogun, laaarin ọdun 2003 si 2007.
Bakan naa lo ṣoju fun Aarin Gbungbun Ogun lati 2007 si 2011.
Nigba ti igbiyanju rẹ lati tẹsiwaju nile igbimọ aṣofin ko kẹsẹ jari mọ ni 2011, Iyabo Obasanjo gba ilu oyinbo lọ, lorilẹede America.
Nibẹ lo wa lai da si ọrọ oṣelu Naijiria mọ, titi di ipari ọdun 2025 ti awọn patako to n kede ipadabọ rẹ sinu oṣelu bẹrẹ si I foju han l'Abeokuta.
Awọn akọle bii "Ọmọ wa ni, eniyan wa ni, ara wa ni." Pẹlu fọto Iyabo Obasanjo bẹrẹ si i farahan kaakiri ilu Abeokuta.
Nigba to si di ọdun 2026 yii, Sẹnetọ Obasanjo kede erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Ogun ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
O forukọ silẹ ni wọọdu kọkanla,nijọba ibilẹ Ibogun- Ifo, o si kede pe oun ko fẹ ipo miran ninu oṣelu ipinlẹ Ogun ju ti gomina lọ, ninu ẹgbẹ APC.
Ṣugbọn lasiko yii, ọmọ Obasanjo loun ko ṣe APC mọ, tori wọn ko fẹ oun nibẹ pẹlu iwa wọn.