You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mò sunkún lórí àwọn ọmọ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso, mi ò mọ̀ pé tèmi náà yóò ṣẹlẹ̀ sí mi - Iya Adelabu
Aburu ki i kan ilẹkun ko too wọle, ẹni to fẹ ṣẹlẹ si paapaa ko ni i mọ pe mẹwaa fẹ ṣẹlẹ lọọdẹ oun.
Ẹyi ni akawe to ba alaye ti iya to bi minisita tẹlẹ fun ohun amuṣagbara lorilẹede yii, Adebayo Adelabu, iyẹn Abilekọ Olufunmilayo Aduke Adelabu, ṣe lori ọmọ atawọn ọmọ ọmọ rẹ meji ti wọn ji gbe niluu Ibadan lọsẹ to kọja.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti ri wọn gba pada bayii lẹyin ọjọ mẹta ti wọn ji wọn gbe, mama naa ṣalaye lẹyin ti wọn de, nipa ibanujẹ to ba gba ọkan rẹ tẹlẹ lori awọn ọmọ ti wọn kọkọ ji gbe lọ ni Ahoro Esinele, l'Ogbomoso.
Lai mọ pe iru rẹ ku ọla ti yoo kan oun naa ni.
"O ku ọla ti temi naa maa ṣẹlẹ, ni mo sọkun kikoro nigba ti mo ri awon ọmọ ti wọn ko lọ lorii foonu, Ọlọrun to tu awọn ọmọ mi silẹ, yoo tu awon yoku naa silẹ"
Ninu fidio kan lori ayelujara, nibi ti wọn ti fi ọrọ wa Mama Adelabu lẹnu wo ni mama naa ti sọ pe:
"Emi ni mo bi Busayo Olaide to bi Peter ati Paul, ọmọ mi ni, abikanyin mi ni.
"Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe mo sunkun mo rẹni gba mi, mo dupẹ pe Ọlọrun ba mi fi aṣiri awọn ẹni ibi han. O jẹ kawọn ọmọ mi wale layọ ati alaafia, ti mo si ri awọn mẹtẹẹta pe.
"Mo dupẹ lọwọ awọn t'Ọlọrun lo lati jẹ ki wọn pada wale naa. Gbogbo awọn to wa nigbekun ni Ọlọrun yoo pada tu silẹ, ẹsẹ ara wọn ni wọn maa fi rin pada wale, ko sẹni kan ti yoo di oku ninu wọn.
"Ọlọrun ni ko ba wa ṣe ilu wa yii, ojoojumọ ni mo n gbadura, bi mo ṣe n gbadura lori awon ọmọ mi ni mo n gba tawọn yoku naa.
"O tiẹ ku ọla ti temi naa maa ṣẹlẹ ni mo sunkun kikoro nigba ti mo ri awon ọmọ ti wọn ko lọ lorii foonu, ti mi o mọ pe temi naa n bọ laaarọ ọjọ keji.
"Ṣugbọn mo dupẹ, Ọlọrun to tu awọn ọmọ mi silẹ , to fun wọn ni idande, yoo tu awon yoku naa silẹ. Ọlọrun a ba wa dawọ iru rẹ duro, a ba wa tun orilẹede wa ṣe."
Iya Adelabu tẹsiwaju ninu adura rẹ, pe Ọlọrun funra rẹ yoo gbajọba Naijiria, yoo fọwọ tọ awọn to n ṣejọba, yoo si ba wa tun un ṣe ju bayii lọ.
Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti Busayo Adelabu-John Paul n ko awon ibeji rẹ lọ silẹ ẹkọ lọjọ kẹta, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni awọn ajinigbe da mọto rẹ duro ti wọn si gbe e lọ pẹlu awọn ọmọ naa.
Ọjọ kẹta ti wọn ti wa nigbekun ni won si gba itusilẹ latọwọ awọn ọlọpaa to koju awon ajinigbe naa, tu wọn ka nibi ti wọn ko wọn pamọ si.
Àwọn ajínigbé tó jí àbúrò Adelabu gbé jẹ́ èèkàn nínú iṣẹ́ ajínigbé, àlàyé rèé nípa bí àṣírí wọn ṣe tú àti orúkọ wọn - Ọlọ́pàá
Kọmisona fun ile iṣe Ọlọpa Ipinlẹ Oyo, Abimbola Olugbenga ti kepe awọn olugbe Ipinlẹ Oyo lati maa fi ojú sọ́ri.
Bákan náà ló ní ki wọn si fi oun ti ko tọna lagbegbe wọn to ile iṣe Ọlọpa leti.
Olugbenga Abimbola lọ sọrọ yii nigbati o mu awọn akọroyin lọ si ibudo awọn ajinigbe, to ji Busayo Adegoke John Paul àtàwọn ìbejì rẹ̀ gbé.
Obìnrin yìí sí ní aburo Adebayo Adelabu tíì ṣe mínísítà tẹ́lẹ̀ fún ohun amusagbara,
Ọpọ ile lo wa layika ile tan ajinigbe fi se ile, iyalẹnu lo jẹ fawon olugbe agbegbe naa pe awọn ajinigbe lo n fi ibẹ ṣe ile
Àdúgbo Araromi Ayegun to wa ni ijọba ibilẹ Oluyole nilu Ibadan sì ni ilé àwọn ajínigbé tí wọn fi óbirin náà àtàwọn ọmọ rẹ pamọ sí, kí ọlọ́pàá to gba wọn silẹ lọ́jọ́ Satide.
Akoroyin ile iṣe BBC News Yorùbá to wa lara awọn Akọroyin to kọwọrin pẹlu ileeṣẹ ọlọ́pàá lọ sí ilé àwọn ajínigbé náà.
Ikọ̀ ìròyìn BBC sì fidi rẹ mulẹ wi pe ile naa jẹ ile oni yara meji, ti wọn si mọ odi yi ka.
Ọpọ ile lo wa layika ile naa, to si jẹ iyalẹnu fawon olugbe agbegbe naa pe awọn ajinigbe lo n fi ibę ṣe ile.
"Méjì nínú àwọn ajínigbé náà la mú balẹ"
Kọmisona Ọlọpa nínú àlàyé rẹ̀ ni awọn oṣiṣẹ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Ọlọpa ti ijọba apapọ pẹlu àjọṣepo awọn oṣiṣẹ ile iṣe ọlọ́pàá nipinlẹ Oyo lọ pawọpọ sisẹ idoola ẹ̀mí náà.
O ni lẹyin ti awọn ri aridaju Ibi tí awọn agbébọn naa wa, ni wọn to yabo ile naa ni bi aago meje aabọ ìrọ̀lẹ́ Satide, ọjọ kẹfa oṣu kẹfa ọdun yii.
"Isẹ iwaadi ti ile iṣe wa ṣe lo jẹ ka mọ ibi tí awọn ajínigbé náà sa pamọ sì ni agbegbe Araromi, nijọba ibilẹ Oluyole.
Ní kete ti ọkan ninu wọn rí wa, ẹni tí orukọ rẹ n jẹ Kelechi, se lo yìnbọn mọ awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ Ọlọpa, ti awọn náà si yìnbọn pada fún awọn afurasi Ajinigbe naa.
"Kelechi ati ọkan ninu awọn ajinigbe yii ni a mu balẹ, awọn miran fara gbọta, ti wọn si sa lọ.
Ṣugbọn ọwọ tẹ Wale Abolalewa ẹniti ọ̀pọ̀ mọ si Oloro ati Dare Oyedele ti wọn si jẹ èèkàn ninu ẹgbẹ ajinigbe naa.
Awon miiran ninu ẹgbẹ ajinigbe naa lọ seese ki wọn tí fara gbọta, a si n rọ awọn ile iwosan lati fi to ile iṣe Ọlọpa Ipinlẹ Oyo leti, ti ẹnikẹ́ni ba wa fun iwosan to nii se pẹlu ọgbẹ ọta ibon"
Lara awọn ohun ti wọn gba lọwọ awọn afurasi ajinigbe naa ni, ọkọ ayọkele Toyota Camry alawọ eeru, Ibọn mẹta, aake kan, ọta Ibon mẹrinla, oogun oloro ati awo oju méjì.
Tẹ ẹ ba gbagbe, ọjọ kẹta oṣu kẹfa ọdun 2026 ni awọn afurasi agbebọn ji aburo obinrin fun minisita tẹlẹ fun ohun amusagbara, Adebayo Adelabu ati awọn ọmọ rẹ ti wọn jẹ ibeji gbe lọ.
Agbegbe Elewura, Challenge, niluu Ibadan, ni isẹlẹ naa ti waye nigba ti obinrin naa n ko awọn ọmọ rẹ lọ si ile ẹkọ ni agbegbe Challenge nilu Ibadan.