You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mo kọ N500m tí wọ́n fi lọ̀ mi láti dènà Ajimobi nígbà tó fẹ́ di gómìnà, àmọ́ ó padà gbàgbé mi- Taiwo Otegbeye
Ọrọ ki I ku bo ti wu ko pẹ to, paapaa bi ẹni tọrọ ọhun kan ko ba ṣetan lati gbagbe rẹ tabi gbe e kuro lọkan.
Kọmiṣanna tẹlẹ fun eto ibaraẹnisọrọ nipinlẹ Oyo, Taiwo Ibiyemi Otegbeye, ti ṣalaye iṣẹlẹ kan to ni o ṣẹlẹ ni 2011, to kan oun ati gomina Oyo tẹlẹ, Oloogbe Abiola Ajimobi.
Otegbeye sọ pe oun kọ owo ti iye rẹ jẹ miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira (500,000m) silẹ nigba ti wọn fi lọ oun lati dina mọ Oloogbe Abiola Ajimobi lati ma ṣe di gomina.
Lori eto ileeṣẹ redio Splash FM kan niluu Ibadan ni Otegbeye ti sọrọ naa.
Bakan naa lo si tun fẹsun kan Gomina Seyi Makinde, pe o gbagbe oun lẹyin idibo ọdun 2023.
"Ẹmi lo ba mi sọrọ ti mo fi kọ lati gba 500m yẹn"
Ni itẹsiwaju alaye kọmiṣanna tẹlẹ naa, Otegbeye sọ pe:
"Ẹnikan fẹẹ fun mi ni 500M lati da ibo wọn ru, ki ibo miran le waye, ṣugbọn ẹmi dari mi lati ma ṣe bẹẹ.
"Bi mo ṣe ba ijọba Ajimobi da iṣẹ pọ niyẹn."
Otegbeye ṣalaye pe amọ ajọṣepọ oun ati Ajimobi pada foriṣanpọn, bo tilẹ jẹ pe ijọba rẹ ṣeleri foun pe oun yoo ṣi maa ri nnkan ṣe lẹyin ti wọn tu igbimọ ka.
"Lẹyin ti wọn ṣe ayẹyẹ ọdun keji ipade awọn alaṣẹ, awọn ọrọ kan ṣẹlẹ, wọn si tu igbimọ ka.
"Wọn sọ fun mi pe ko si ohun ti yoo ṣe ipo mi, ṣugbọn nigba ti wọn maa gbe orukọ tuntun jade, orukọ mi ko si nibẹ."
Otegbeye sọ pe oun gbọ pe awọn Musulumi kan ni wọn kora jọ, ti wọn ni oun ko gbọdọ pada wa, bo tilẹ jẹ pe oun n ṣe daadaa."
"Ajimobi ṣeleri pe oun yoo fun mi ni tikẹẹti ile igbimọ aṣofin ni 2015, ko mu un ṣẹ"
Ni afikun ọrọ rẹ lori eto naa, Otegbeye ṣalaye pe Oloogbe Abiola Ajimobi pada ṣeleri lati fun oun ni tikẹẹti ti yoo sọ oun di ọmọ ile igbimọ aṣofin labẹ APC ni 2015.
O ni ṣugbọn gomina tẹlẹ naa ko mu ileri naa ṣẹ.
"Nigba to ya, Ajimobi ko gbe ipe mi mọ, ko si ki n fesi sawọn atẹjiṣẹ mi naa, mo wa pinnu lati fa a le Ọlọrun lọwọ."
Kọmiṣanna tẹlẹ naa ko ṣai mẹnuba ọrọ Gomina Seyi Makinde, o ni boun ṣe ṣiṣẹ fun un gẹgẹ bii Igbakeji alaga ikọ iroyin to polongo ibo fun un ni 2023 to, Makinde ko ri toun ro mọ latigba to ti yege.
"Ko mu ileri rẹ kankan ṣe. Lati ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹta ọdun 2023, fun ọdun meji bayii, ko gbe ipe mi."
Otegbeye lo sọ bẹẹ.
Ta a ni Taiwo Otegbeye?
Taiwo Otegbeye lo dupo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, ni 2011.
O pada tako abajade esi idibo naa nigba to fẹsun kan ajọ INEC, pe wọn yọ orukọ ati ami idanimọ Action Alliance kuro lori iwe idibo.
Akọsilẹ fi han pe ẹgbẹ Action Alliance wọ INEC lọ sile ẹjọ, pẹlu Ajimobi ati igbakeji rẹ nigba naa; Moses Alake Adeyemo.
Lẹyin o rẹyin ni Otegbeye gbe ọrọ naa kuro niwaju igbimọ to n gbọ ọ, nigba ti oun ati awon igun mejeeji jọ ni asọyepọ.
Lẹyin to gbe ọrọ naa kuro niwaju igbimọ, Otegbeye darapọ mọ iṣakoso Ajimobi, o si ṣiṣẹ bii oludamọran pataki lori ọrọ ẹkọ.
Lẹyin naa ni wọn fi I ṣe kọmiṣanna fun eto iroyin lati 2011 titi di 2013.Ko too di pe o ni ijọba to ṣe adehun foun ko woju oun mọ.