'Mi ò tíì fojú rí àwọn ọmọ mi fún ọdún mẹ́jọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtòsí ara la wà'

Àkọlé fídíò, Mi ò tíì fojú rí àwọn ọmọ mi fún ọdún mẹ́jọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtòsí ara la wà
'Mi ò tíì fojú rí àwọn ọmọ mi fún ọdún mẹ́jọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìtòsí ara la wà'
Published

Ọdun mẹjọ sẹyin ni Ọgbẹni Mohammed Khumaisi foju kan iyawo rẹ atawọn ọmọ marun un to bi fun un gbẹyin.

Nigba to n ṣe abẹwo si ileto kan nitosi ilu ibinibi rẹ, ni ikọlu kan waye lati le awọn ikọ agbebọn Houthis kuro ni agbegbe naa to yi idile rẹ ka. Ibi ti ikọlu yii ka Ali mọ jẹ eyi ti ko dara to ninu wahala to ṣẹlẹ naa. Nibayii, ile atibaba kan ni awọn ibudo ogunlende lo n gbe lagbegbe iwọoorun ariwaa orilẹede Yemen to wa labẹ akoso ikọ agbebọn naa, eyi ti ko jina pupọ si agbegbe to wa labẹ iṣakoso ijọba orilẹede yemen nitosi aala orilẹede naa pẹlu Saudi.

Ohun to n ba Ali lẹru bayii ni pe pẹlu bi ọrọ ijiroro adehun Alafia tun ti ṣe foriṣanpọn bayii laarin ikọ agbebọn Houthis ti Iran n ṣa atilẹyin fun ati ijọba Yemen ti orilẹede Suadi Arabia n ṣugbaa, afaimọ ko ma di eyi ti oun ko ni fi oju ri awọn ẹbi oun mọ layelaye.