Ṣé dátà 100mb yóò tó akẹ́kọ̀ọ́ láti kàwé lórí ayélujára lóòjọ́?

Oríṣun àwòrán, Getty Images/Asiwjau Bola Tinubu
Ijọba apapọ ti kede eto tutun kan nibi ti awọn akẹkọọ yoo yi maa kawe lori ayelujara pẹlu data ọfẹ.
Minisita fun eto ẹkọ, Tunji Alausa to fi ikede naa sita sọ pe o wa lara awọn akanṣẹ eto ti ijọba ṣe labẹ eto Renewed Hope Agenda.
Ijọba ni awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ girama agba titi de fasti ni ọrọ naa yii kan.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, iye data ọfẹ ti akẹkọọ yoo janfani rẹ loju opo naa ni ọgọrun mẹgabaiti, 100MB, loojọ.
Lasiko to n sọrọ nibi ifilọlẹ eto naa ti wọn pe ni "Initiative for Zero-Rated Access to Educational Platforms and Content in Nigeria," Alausa ni ijọba gbe eto ọhun kalẹ ki gbogbo mutumuwa le lanfani si eto ẹkọ.
O tun sọ pe ijọba n ṣeto bi awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹrindinlogun lọ yoo ṣe lanfani si ori ayelujara lati daabobo awọn ọmọde ọhun nibẹ.
Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 yii ni eto naa yoo bẹrẹ ni ajọṣepọ ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ẹkọ, ajọ NCC atawọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ.
Ṣe 100mb to awọn akẹkọọ lati kawe loojọ?
Ni kete ti iroyin yii jade ni ọpọ awọn akẹkọọ ti wọn jẹ iran Gen Z ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori rẹ.
Ohun ti ọpọ ninu wọn n sọ ni pe 100MB naa ko le to nnkankan.
Nigba ti BBC kan si akẹkọọ kan ti ọjọ ori rẹ ko tii ju ọdun mẹtalelogun lọ, Happiness Adetuyi, o ni "100MB ko le to nnkankan o."
"100MB kole to loojọ, ṣe ẹ mọ pe ti eeyan ba ti tan data rẹ gan, ti gbogbo awọn atẹjiṣẹ to ti n duro sibẹ wọle sori foonu eeyan, 100MB ti tan niyẹn."
Gẹgẹ bi Hapiness ṣe sọ, 100MB ko le to lati maa ka iwe lori ayelujara, koda ti ko ba si awọn aworan nibẹ tabi fidio.
O ni "Ti mo ba lanfani lati ba ijọba sọrọ, mo maa sọ fun wọn ki wọn ṣe e ni 1GB o kere ju, awọn akẹkọọ ṣi le lo 1GB bẹẹ bẹẹ."
Aarẹ Amẹrika ṣeleri $5,000 faraalu ti ẹgbẹ oṣelu rẹ ba wọle ibo
Ẹwẹ, ikede ijọba Naijiria yii lo n waye lasiko kan naa ti Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ṣeleri owo ti iye rẹ to $5,000 fun gbogbo ọmọ ilẹ naa to ti dagba ti ẹgbẹ oṣelu rẹ, Republican ba le jawe olubori ninu idibo sile aṣofin ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2026 yii.
Trump ni "Ti ẹgbẹ oṣelu Republican ba le wọle, gbogbo wa la jọ maa wọle, ẹ o si gba $5,000. Owo iranwọ Trump ni a maa pe e."
Ọrọ yii ni Trump sọ lasiko ipade gbogbo ẹgbẹ oṣelu naa to waye ni Dallas lasiko yii ti ẹgbẹ ọhun n fidi wọ ni ifagagbaga pẹlu ẹgbẹ oṣelu Democrat.
Aarẹ naa ko mẹnuba ibi ti owo naa yoo ti wa amọ o kan sọ fun wọn pe orilẹede wọn ti n pa obitibiti wọle wọle lasiko yii ni.
Gẹgẹ bo ṣe, o ni ki wọn ri bii pe oun wa lara awọn to do n dije du ipo, nitori naa, ki wọn jade witiwiti lati dibo.
Iwadii kan fi han pe ọpọ ọmọ ilẹ Amẹrika ni inu wọn ko dun si ijọba Trump, paapaa bi nnkan ṣe gbowo lori ati ogun to gbe ti Iran.
Ajọ kan to maa n ṣewadii nipa gbigba erongba araalu, Decision Desk HQ, ti sọ asọtẹlẹ pe ẹgbẹ oṣelu Democrat ni yoo jawe olubori ninu idibo sile aṣofin naa pẹlu esi 230-205 ati 51-19, ninu idibo oṣu Kọkanla.
Amọ Aarẹ Trump ti ṣeleri fawọn eeyan Amẹrika pe ọwọngogo to gbode yoo pada maa pada walẹ ni kete ti ogun Iran ba ti pari.
Wayi o, bo tilẹ jẹ pe ijọba Naijiria ko so ileri tirẹ mọ eto idibo bii Trump, ileri mejeji yii lo n waye lasiko ti eto idibo ku oṣu perete.






























