You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àgbà òṣèré tíátà, Kola Oyewo jáde láyé
Iroyin to n tẹ wá lọ́wọ́ ni yajoyajo yìí tí fìdí rẹ mulẹ pé àgbà òṣèré tíátà, Kola Oyewo tí jáde láyé.
Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kejìlá oṣù kẹfà ọdún 2026 yìí ni ìròyìn ikú àgbà òṣèré náà gbà orí ayélujára kan.
Àwọn gbajúmọ̀ òṣèré bíi Kunle Afod ati Yomi Ọlọrunlaiye ni wọ́n ti ń daro ipapoda àgbà òṣèré náà.
Laipẹ yìí ni Oloye Kola Oyewo ṣe ayẹyẹ ọgọ́rin ọdún lókè eepẹ
Bi o tilẹ jẹ pe a kò tíì lè sọ irú ikú tó pa àgbà òṣèré náà, àmọ́ ó sísọ lójú rẹ nínú ìròyìn kan pé àìsàn asetọ ń ba òun fínra.
Onírúurú ère sinima ni Kola Oyewo tí kopa èyí tó sọ ọ di olókìkí.
Lara awọn sinimá náà ni Tí Olúwa ni ilẹ̀, Saworo Ide, The Gods are not to blame áti bẹẹ bẹẹ lọ.
Bawo ni ìgbésí ayé Kola Oyewo ṣe lọ?
Ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kẹta ọdún 1946 ni olóògbé Kola Oyewo dele aye.
Ìlú Oba Ile nipinlẹ Osun ni wọn bi i si, to si bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ère tíátà pẹlu ẹgbẹ́ òṣèré Oyin Adejobi.
Kola Oyewo ṣe ere tíátà fún bíi ọgọ́ta ọdún, lára ere to tí kopa ni Sango, Koseegbe àti Super Story.
Bákan náà, olùkọ́ àgbà ní olóògbé Oyewo, to si gbà oye ọmọwe nìdí ere sise ni fásitì Ibadan.
Fásítì Obafemi Awolowo ni olóògbé náà tí ṣiṣẹ olùkọ́ni, ó si tún ṣiṣẹ ni Fásítì Redeemer áti Elizade.
A gbàdúrà pé kí ọba òkè tẹ sì afẹ́fẹ́ rere.