Ajínigbé wọ agboolé gbé géńdé lọ n'Ikoyi-Ile, ọlọ́pàá mú afurasí méjì

Afurasi meji tọwọ ọlọpaa ba
Àkọlé àwòrán, Jayun Danali ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹtadinlogun lọ (17) lo wa lapa osi ninu aworan yii, ẹnikeji rẹ ti wọn jọ mu bii afurasi lori ijinigbe naa lo wa lapa ọtun, Muhammadu Abubakar ni won pe orukọ tiẹ.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe oun ti fi ofin mu awọn afurasi meji kan ni abule Layeri, nitosi Ikoyi-Ile, ipinlẹ Oyo.

Atẹjade ti Alukoro ọlọpaa Oyo, DSP Ayanlade Olayinka, fi sita lọjọ Aiku, ṣalaye pe Nathaniel Peter, ẹni ọdun mejidinlogoji (38) ni awọn ajinigbe naa gbe lọ.

O ni awọn ti mu afurasi meji lori iṣẹlẹ yii.

Bawo ni ijinigbe naa ṣe waye?

Ninu alaye ileeṣẹ ọlọpaa Oyo, wọn sọ pe ifisun kan lo de etigbọọ awọn lori iṣẹlẹ naa lọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii.

DSP Ayanlade ṣalaye, pe nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ ọjọ naa ni olugbe agbegbe naa kan mu ifisun wa, pe awọn agbebọn ti yawọ agboole kan lagbegbe ọhun.

O ni iwadii ọlọpaa lẹyin ti wọn de ibẹ fi han pe awọn agbebọn naa fipa wọ yara Nathaniel Peter, wọn si ji I gbe lọ.

Lẹyin eyi ni wọn gba ọna Igbo ọba apapọ sa lọ, eyi si jẹ lẹyin ti wọn ji ọkada kan ati foonu Nathaniel lọ pẹlu.

Awọn wo lọwọ tẹ, bawo ni wọn ṣe mu wọn?

Alukoro ọlọpaa Oyo ninu alaye rẹ, sọ pe iwadii bẹrẹ lẹsẹkẹsẹ lati mọ ohun to wa lẹyin ijinigbe naa atawọn to dan an wo gan-an.

Lẹyin eyi lo ni ọwọ ba afurasi meji torukọ won n jẹ Muhammadu Abubakar toun dagba, ati Jayun Danali, ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹtadinlogun lọ (17).

Awọn ọkunrin mejeeji ti ọlọpaa mu naa ni wọn ti n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn bi DSP Ayanlade ṣe wi.

Ayanlade sọ pe eyi yoo ran awọn lọwọ lati le mọ awọn to ba tun lọwọ ninu ijinigbe naa, kawọn si fi ṣinkun ofin gbe wọn.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, wọn ko ti I ri Nathaniel ti won ji gbe naa, amọ ileeṣẹ ọlọpaa Oyo sọ pe iṣẹ ti n lọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo miran, nipa bi wọn yoo ṣe ri i gba lai farapa.

Wọn rọ araalu Oyo lati fi ọkan balẹ, ki wọn fi oju ṣọri, ki wọn si tete maa fi ohun ifura ti wọn ba ri to ọlọpaa leti.

Eyi ni awọn ẹrọ ibanisọrọ ti wọn fi lede fun araalu lati pe, bi wọn ba ni ifitonileti kankan fun agbofinro:

"Oyo State Call Response Center Toll-Free Line: 615

Oyo State Police Command Control Room: 08081768614 / 07055495413"