Àwọn ajínigbé tún jí èèyàn 80 gbé ní Niger, Zamfara

Oríṣun àwòrán, Others
Lasiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger ati ti Zamfara ko ti i le sọ pato iye eeyan ti awọn ajinigbe ji gbe lọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku to kọja yii, lẹyin ijinigbe ọlọpọ eeyan to waye lawọn agbegbe kan nipinlẹ mejeeji.
Ohun ti awọn ẹka iroyin agbegbe naa kede ni pe ko din ni eeyan ọgọrin, (80) ti pupọ ninu wọn jẹ agbẹ ati obinrin tawọn ajinigbe gbe lọ nibi iṣẹlẹ mejeeji.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Ijinigbe akọkọ waye lagbegbe Mariga, ipinlẹ Niger, lọjọ Satide, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹsan-an ọdun 2026.
O kere tan, eeyan mẹtadinlaadọta (47) ti pupọ ninu wọn jẹ obinrin ni iroyin sọ pe awọn ajinigbe to dihamọra ogun gbe lọ ninu iṣẹlẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Niger, Abiodun Wasiu, kọkọ fi lede lo ti ṣalaye pe nnkan bii aago mẹta ọsan ọjọ Satide ni ikọlu naa waye.
O ni ogun eeyan (20) ni wọn gbe lọ ni abule Mukura, lagbegbeKasuwan-Garba, ijọba ibilẹ Mariga.
Abiodun sọ pe awọn ikọ alaabo ti n ṣiṣẹ pọ lati gba awọn eeyan naa silẹ.
Amọ ẹka iroyin AFP ṣalaye pe eeyan mẹtadinlaadọta (47) o kere tan ni awọn ajinigbe ọhun gbe lọ.
Iroyin naa sọ pe pupọ ninu awọn ti wọn gbe lọ naa ni wọn jẹ obinrin.
Lasiko ti awọn obinrin naa n wa ẹ̀pà lati inu ilẹ̀ ni wọn kọlu wọn bi iroyin yii ṣe wi, ti wọn si gbe wọn lọ.
Ẹka iroyin naa sọ pe o ṣee ṣe kawọn ti wọn gbe lọ naa pọ ju mẹtadinlaadọta lọ.
Ti Zamfara
Ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aiku; ọjọ kejindinlọgbọn oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 ni wọn kọlu Zamfara ti ko jinnna si Niger.
Alaye awọn ẹka iroyin agbegbe lori ijinigbe yii, ni pe o kere tan, ogoji eeyan (40) ni wọn gbe lọ ni Yargada, nitosi Gusau, ipinlẹ Zamfara.
Awọn olugbe awọn agbegbe ti ijinigbe ti waye naa sọ pe ki i ṣe pe wọn ji awọn eeyan gbe lọ lasan, wọn ni wọn tun dana sun ile awọn eeyan pẹlu.
Awọn ajinigbe to n dihamọra ogun naa ni araalu tun mọ si bandiiti, iṣẹ wọn ko si ṣẹṣẹ bẹrẹ, paapaa julọ lapa Ariwa Iwọ-Oorun ati Aarin-Gbungbun Oke Ọya.
Ọpọ igba ni wọn ti jẹ awọn abule run, ji nnkan ọsin ko ti wọn yoo si maa beere owo itusilẹ lori awọn eeyan ti wọn ji gbe.
Awọn agbẹ kan ko tilẹ le lọ si oko wọn mọ, nitori ibẹru ijinigbe, eyi to n fa aito ati ọwọngogo ounjẹ.
Ni ti ipinlẹ Niger to paala pẹlu olu ilu ilẹ wa Abuja, ọpọ igba ni ikọlu ti waye nibẹ, paapaa lawọn ibi to sunmọ igbo bii Mariga ti wọn tun kọlu yii.
Ninu awọn igbo naa ni awọn ajinigbe n sa si.
Bakan naa si ni Zamfara naa jẹ ọkan lara awọn ibi tawọn bandiiti yii ti n ṣọṣẹ pupọ, bo tilẹ jẹ pe awọn ologun ko dawọ iṣẹ duro nibẹ.
Ṣaa, awọn alaṣẹ ti sọ pe iṣẹ n lọ lati ri awọn ti wọn ji gbe lọ gba pada, ki wọn si fi ṣinkun ofin mu awọn to ji wọn gbe.


























