You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àjọ CAN kéde ọjọ́ òní gẹ́gẹ́ bíi ọjọ́ 'Àìkú Dúdú' láti dárò àwọn ọmọ Naijiria tó ń jìyà ètò ààbò tó mẹ́hẹ
Bi ijinigbe, igbesunmọmi ati aisi aabo ṣe n peleke si i kaakiri Naijiria, ẹgbẹ Onigbagbọ lorilẹede yii, Christian Association of Nigeria' (CAN), ti kede ọjọ Aiku oni bii Aiku Dudu.
CAN kede ọrọ naa ninu iṣẹ ti Aarẹ wọn, Archbishop Daniel Okoh, ran si gbogbo Kristẹni lonii ọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹfa ọdun 2026.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, kikede ọjọ naa bii ọjọ Aiku Dudu, wa lati daro, bu ọla fun awọn eeyan ti ẹbi wọn ti koju idaamu, aibalẹ ọkan, ijinigbe ati igbesunmọmi kaakiri Naijiria.
CAN fi kun un pe yiya ọjọ naa sọtọ bii ọjọ to dudu, wa fun lati daro awọn ọkunrin, obinrin, ọmọde, awọn iranṣẹ Oluwa, agbẹ, ọmọ ile ẹkọ ati gbogbo agbegbe ti iṣoro yii ti fọwọ ba ni Naijiria.
"Lonii, ki i ṣe pe a n daro nikan, niṣe la tun n fi ohùn kan sọrọ.
"Ẹjẹ n ṣàn lorilẹede wa, ijọ Oluwa ko si le dakẹ lorii rẹ kawọn ẹmi ti ko ṣẹ si maa bọ, kawọn ẹbi wọn si maa wa ninu ibẹrubojo."
"Orí ààbò ẹ̀mí ni ijọba awarawa wà, pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo"
Gẹgẹ bi CAN ṣe wi, asiko ti Naijiria n ṣe iranti ijọba awaarawa naa ni ọjọ Aiku Dudu yii bọ si.
Ṣugbọn ko sohun to n jẹ ijọba awaarawa bi ko ba si aabo fun ẹmi eeyan, ti ko si si idajọ ododo bi ẹgbẹ Onigbagbọ Naijiria ṣe sọ.
Ẹgbẹ naa ṣalaye atilẹyin rẹ fawọn ẹbi ti wọn ji awọn eeyan wọn gbe lọ, pẹlu ọpọ eeyan to n gbe nilẹ yii ninu aibalẹ ọkan.
CAN fi ẹsẹ Bibeli kan gbe ọrọ rẹ lẹsẹ, eyi ti i ṣe iwe Matthew, ori karun-un, ẹsẹ kẹrin (5:4):
"Alábùkún fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú."
Wọn fi kun un pe awọn Kristẹni kaakiri Naijiria lo n sowọpọ gbadura fawọn ti rogbodiyan ilu yii kan, nibi kibi ti wọn ba wa.
"A n pe ijọba ni gbogbo ẹka lati tete ṣeto aabo to daju kaakiri Naijiria, a si rọ awọn ṣọọṣi, ile ẹkọ Kristẹni ati bẹẹ bẹẹ lọ lati fi kun eto aabo wọn"
CAN ko ṣai pe ijọba Naijria lati tete ji giri si eto aabo to mẹhẹ yii, gẹgẹ bi wọn ṣe ni ki araalu naa ma ṣafira.
"A n pe ijọba ni gbogbo ẹka pata lati tete gbe igbesẹ to daju, ki wọn ṣeto aabo ti ẹsẹ rẹ ko mi nilẹ fun aabo ẹmi ati dukia kaakiri Naijiria.
"Dida aabo bo araalu jẹ ojuṣe pataki ti a fi fun awọn to ba wa nipo agbara, wọn si gbọdọ fi gbogbo ipa wọn si i.
"A pe awọn ṣọọṣi, awọn ile ẹkọ Kristẹni, ileewosan, awọn ẹka to n ri si ẹsin ati bẹẹ bẹẹ lọ lati so okun aabo wọn le si i."
CAN fi kun un pe ijafara ko gbọdọ si bayii, ki kaluku maa wa ni igbaradi, ki wọn si maa ṣiṣẹ pẹlu awon ẹṣọ alaabo agbegbe wọn bi wọn ṣe n foju ṣọri.
Ẹgbẹ naa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ma ṣe bẹru, ṣugbọn ki wọn lo ayajọ yii lati fi maa ranti pe iduroṣinṣin lọjọ ewu ati adura gbigba fun orilẹede wa ṣe koko.
Igbesẹ CAN yii wa fun iranti, pe ijinigbe ati ipaniyan n gbilẹ kaakiri Naijiria, ti ọpọ eeyan si wa ni igbekun pẹlu.