You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébọn kọlu Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo, jí baálẹ̀ gbé lọ ní ààfin
Kayefi nla lo jẹ fun awọn olugbe Ode Oriya nijọba ibilẹ Owo, nipinlẹ Ondo bi awọn agbebọn ṣe yabo aafin baalẹ ilu naa Adeniyi Adelana, ti wọn si ji gbe lọ.
Gbogbo olugbe ilu naa lo ti wa ni iporuru ọkan latari iṣẹlẹ naa eyi to waye ni deedee ago mẹjọ kọja isẹju marun ni asalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2026.
Awọn olugbe ilu naa ṣalaye pe awọn agbebọn mẹfa lo wọ aafin naa, ti wọn si sọsẹ yi lai si ẹni to yẹ wọn lọwọ wo.
Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé?
Ọkan lara ọmọ baalẹ naa to ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe, ní oru ọjọ Ẹti ni awọn afunrasi naa yabo ile baba rẹ tí wọn si gbe lọ.
Ọmọ naa ṣalaye pe iyawo baba rẹ ti wọn jọ wa ni aafin lasiko ti iṣẹlẹ naa waye farapa, bi awọn afunrasi agbebọn naa se yin ibọn lu lọwọ ọtun rẹ.
O ṣalaye pe awọn agbebọn naa gbe obinrin agbalagba kan pẹlu baba ohun, ṣugbọn wọn ti tu obinrin naa silẹ, ti wọn si gbe baba rẹ nikan lọ.
Ọmọ naa sọ pe awọn afunrasi ọhun ko ti kan si mọlẹbi lati bere owo tabi ohun miran.
O rawọ ẹbẹ si awọn ẹṣọ alaabo lati ṣawari baalẹ naa, ki wọn si se ipese abo to peye fun awọn olugbe agbegbe ọhun.
Kí ni ileeṣẹ ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Alukoro ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Jimoh Abayomi ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atejade to fi sọwọ si awọn akọroyin ni owurọ ọjọ Aiku.
Ọgbẹni Jimoh salaye pe awọn afunrasi naa, fi ọrọ naa ṣe oru la n se ika ni, bi wọn ṣe ṣamulo okunkun tí agbegbe naa wa lati se akọlu naa.
O ṣalaye pe awọn afunrasi agbebọn mẹfa lo sakọlu naa ti wọn si ji baalẹ Adeniyi Adelana gbe lọ.
Jimọh ṣalaye pe kete ti wọn gbọ iṣẹlẹ naa, DPO lagbegbe Owo pakitimọra, to si ko awọn ikọ ileeṣẹ naa lọ agbegbe ohun nibi ti wọn ti ba iyawo baalẹ naa to tí farapa ni ọwọ ọtun rẹ, ti wọn si gbe lọ ile iwosan fun itọju.
O ṣalaye pe wọn ti bẹrẹ si ni wa awọn igbo to wa ni ayika ilu naa pẹlu ifọwọsowọpọ awọn esọ alaabo miran lati ṣawari ẹni tí wọn jigbe naa.
Alukoro sọ pe kọmisọna ọlọpaa nipinlẹ, Ondo Felix Ohagwu ti pasẹ fun awọn ọlọpaa naa lati ṣawari baalẹ ọhun ni kiakia, ki wọn si daabo bo awọn olugbe agbegbe naa.
O wa rọ awọn olugbe agbegbe naa lati fọkan balẹ nitori awọn ikọ ọlọpaa tí bẹrẹ iṣẹ lati doola baalẹ naa, pẹlu aridaju pe wọn yoo fi awọn afunrasi ọdaran naa jofin.