AI lè gba iṣẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tí kò bá fi kún ìmọ̀ ẹ̀rọ wọn lẹ́nu iṣẹ́ ọba-Ìjọba àpapọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
B'aye ba n yi ka maa ba aye yi, igba lonigba n lo.
Imọ ẹrọ igbalode ti a mọ si Artificial Intelligence (AI) ti lilo rẹ ti n gbilẹ lawọn ileeṣẹ ati ẹka kaakiri agbaye, ni ijọba apapọ Naijria ti sọ pe o ṣee ṣe ko gba iṣẹ lọwọ awọn eeyan ti imọ ẹrọ wọn ko ba kun to.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba tun fi awọn oṣiṣẹ lọkan balẹ pe lilo AI ko tumọ si pe yoo rọpo awọn eeyan patapata, sibẹ, o ṣee ṣe kawọn kan padanu iṣẹ wọn.
Alaye ijọba apapọ ni kikun
Ọga agba nileeṣẹ ijọba apapọ Naijiria to n ri si ikede ati imọ ẹrọ, 'National Information Technology Development Agency' (NITDA), Kashifu Inuwa, lo kede ọrọ yii niluu Abuja.
Inuwa ti Aristotle Onumo, ọga to n ri si iṣakoso ati ajọṣe lẹnu iṣẹ ọba, ṣoju fun nibi eto to ti kede yii l'Abuja, ṣalaye pe o yẹ kawọn oṣiṣẹ ri AI bii nnkan eelo idagbasoke ni.
O ni o yẹ ki wọn ri imọ ẹrọ naa bii ohun amuṣẹya, yatọ si ki wọn maa foju ohun to n ba wọn figa gbaga wo o.
"Ẹru ṣaa maa n ba awọn eeyan pe AI fẹ waa gbaṣẹ lọwọ wọn ni, paapaa awọn oṣiṣẹ ijọba.
"Ṣugbọn mo fẹ la nnkan kan ye yin, pe iṣẹ awọn eeyan to kọ lati fi kun imọ ẹrọ wọn ṣee ṣe ko bọ.
"Amọ awọn to ba ṣetan lati tun ara wọn kọ, ki wọn si gba a a wọle yoo jẹ anfaani pupọ lati ara AI.
"AI ko wa lati rọpo awon eeyan patapata, ṣugbọn awọn to ba kọ lati ni imọ si lẹka imọ ẹrọ le ni iṣoro lati le duro nibi ti imọ ẹrọ ti n tẹsiwaju".
Bẹẹ ni ọga NITDA naa ṣalaye.
Ọna abayọ
Lati ṣẹgun ohun to le jẹ ibẹru fun awon oṣiṣẹ nipa AI, Inuwa ṣalaye pe ajọ NITDA ti bẹrẹ idanilẹkọọ fawọn oṣiṣẹ ti iṣẹ wọn nilo imọ ẹrọ.
O fi kun un pe NITDA ti figba kan ni ajọsọ pẹlu ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, lati kọ awọn oṣiṣẹ ijọba ni imọ ẹrọ to jẹ mọ AI.
Bakan naa lo ni awọn eeyan ti yoo gba iṣẹ ọba lọjọ iwaju gbọdọ mọ pe imọ ẹrọ ṣe pataki, ki wọn le maa ba igba mu lawujọ agbaye ti AI ba n dari.
Ọga NITDA rọ awon ileeṣẹ ọba, ajọ ati ẹka ọtọọtọ lati gbe imọ AI abẹnu jade fawọn oṣiṣẹ wọn.
O ni eyi ti yoo le ṣe odiwọn laaarin iṣẹ eeyan ati eyi ti AI yoo ṣe.

























