"Òfin tó mú Eleha ló mú eléégún, ẹ fààyè gbàwọn ẹlẹ́sìn àbáláyé náà láti máa wọ aṣọ ìbílẹ̀ lọ ilé ẹ̀kọ́ ISI n'Ibadan"

Oyinkansola Elebuibon wọ aṣọ funfun pẹlu ẹgba ọrun ati ilẹkẹ lọwọ

Oríṣun àwòrán, Oyinelebuibon/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

‎Ọrọ lori gbigba awọn akẹkọọ ẹlẹsin abalaye laaye lati maa wọ aṣọ ibilẹ lọ ile ẹkọ girama ISI ni fasiti Ibadan ti o fa awuyewuye sẹyin, ko tii tan an bi ile ẹjọ kotẹmilorun to kalẹ silu Ibadan ti jokoo lori ọrọ naa lonii Ọjọbọ ọjọ kọkanlelogun oṣu Karun un.

‎Amofin Bola Akioye to jẹ ọkan lara awọn agbejoro to n ṣoju awọn ẹlẹṣin abalaye nibi igbejọ naa ṣalaye wi pe ofin to mu eleegun naa lọ mu ẹlẹha, o wa rọ ile ẹjọ lati faye gba awọn ẹlẹṣin abalaye lati maa ṣe ẹṣin wọn gẹgẹ bi awọn ẹlẹṣin Islam naa ti ni oore ọfẹ lati gbadura ati lati wo Hijab ninu ile ẹkọ naa.

Amofin ‎Bola ni Ọdun 2017 ti awuyewuye naa kọkọ bẹrẹ ni wọn ti le awọn ọmọ awọn ẹlẹṣin abalaye kuro ninu ile ẹkọ ISI nitori wọn wọ ilẹkẹ.

o fikun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti ile ẹjọ giga ti Ipinlẹ Oyo ti faye gba ki awọn ẹlẹṣin Islam maa wọ Hijab, o yẹ ki awọn ọmọ awọn ẹlẹṣin abalaye naa le ma wọ aṣọ to jọmọ ẹṣin wọn lọ sile ẹkọ wọn.

‎Agbẹjọro naa ni abala ofin to daabo bo ẹtọ ọmọniyan ni orile-ede Naijiria ni o yẹ ki ile ẹjọ daabo bo papaa julọ lori awọn ẹlẹṣin abalaye.

‎Agbejoro mii, Fola Awonusi, toun naa jẹ ọkan lara awọn aṣoju fun awọn ẹlẹṣin abalaye ṣalaye wi pe niwon igba tawọn ẹlẹṣin musulumi ni àṣẹ lati wo Hijab ninu ile ẹkọ ISI gẹgẹ bi idajọ ile ẹjọ giga ti Ipinlẹ oyo se gbe e kalẹ lọdun 2024, awọn ẹlẹṣin abalaye naa gbọdọ jẹ anfani yii.

‎Hassan Taiwo agbejoro awọn ẹlẹṣin musulumi ṣalaye wi pe, awọn adajo alaga mẹta ti gbo ẹjọ onikaluku, o ni awọn alawo ti ṣaaju tako Igbejọ wi pe ki awọn ẹlẹṣin musulumi ma wo hijab ninu ọgba ile ẹkọ ISI.

‎Hassan tesiwaju wi pe iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn tun gbe ẹjọ wa wi pe awọn naa fẹ maa wọ awọn ohun ijọsin ẹṣin wọn lọ si ile ẹkọ bayii.

''‎Bi ile ẹjọ baa fi ẹtọ wa dun wa, a o lọ sile ẹjọ miran‎''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Bola Akioye tenu mọ ọn wi pe ile ẹkọ ISI n fi aye gba awọn akẹkọọ to jẹ ẹlẹṣin musulumi lati lọ jọsin ni gbogbo ọjọ eti bẹẹ ni awọn ẹlẹṣin Kristẹni naa maa n lọ si ile ìjọsin nigba ti o yẹ sugbọn ko si ibikan ti wọn ya sọtọ fun awọn ẹlẹṣin abalaye.

‎O ni ọpọ igba ni awọn to n dari awọn ile ẹkọ yii ko ka awọn sii.

Ampfin Akioye ṣe atenumọ idajọ ile ẹjọ kan nipinlẹ Oyo eyo to ni o sọ pe awọn ẹlẹṣin abalaye ko jamo nkankan.

‎Bola Akioye ni ipejọ awọn nissinyin ni lati faye gba ki awọn ẹlẹṣin abalaye ma wo ileke si ọwọ ati ẹsẹ, ki wọn si faye gba awọn ẹlẹṣin abalaye lati ma ṣe ìjọsìn wọn nigba to yẹ.

Bakan naa lo tun sọ pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ko gbọdọ dunkoko mawọn ọmọ awọn ẹlẹṣin abalaye mọ.

‎Ṣaaju ni awọn obi nile ẹkọ girama ISI ti wọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ati ti fasiti Ibadan lọ siwaju ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ lori ẹsun pe wọn fi ẹtọ awọn akẹkọọbinrin kan lori wiwọ ibori hijab dun wọn lọdun 2018.

‎Nigbati won gbe ile ẹkọ naa lọ si ile ẹjọ awọn ẹsun mẹta ni wọn fi kan ile ẹkọ naa awọn ẹsun naa pe ki ileẹjọ fi idi ẹtọ ọmọniyan awọn akẹkọọbinrin ọhun lati wọ ibori Hijab mulẹ.

Ẹbẹ keji ni ki ile ẹjọ o paṣẹ pe bi wọn ṣe se awọn akẹkọọ to wọ hijab wọ yara igbẹkọọ nile ẹkọ naa mọle fun ọpọlọpọ wakati ko bofin mu.

‎Bakannaa ni wọn tun fẹ ki ile ẹjọ naa gba awọn akẹkọọ naa laye lati ṣamulo ẹtọ wọn si ẹsin to ba wu wọn.

‎Ọjọ kejilelogun ọdun 2024 ni ile ẹjọ giga ti ipinle Oyo pa a lase pe ki awọn akẹkọọ musulumi maa wo Hijab nilẹ ẹkọ naa.

Ohun naa lọ faa ti awọn ẹlẹṣin abalaye naa se n pe fun gbigba awọn ọmọ awọn to jẹ akẹkọọ naa laye lati wo awọn aṣọ to farape ẹṣin wọn lọ si ile ẹkọ ki wọn si ya yara kan sọtọ fun won lati maa ṣe ijọsin wọn ninu ile ẹkọ naa.