Àrun Ebola ti gbilẹ̀, gbẹ̀mí èèyàn ní Congo, àmọ́ níbo lọ̀rọ̀ dé dúró ní Nàìjíríà? Àjọ NCDC ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Latari ariwo to gba ori ayelujara kan, pe arun Ebola ti n tan ka lawọn orilẹede kan, ajọ to n gbogunti itankalẹ arun lorilẹede yii, Nigeria Centre for Disease Control and Prevention (NCDC), ti sọ pe arun Ebola ko ti i si ni orilẹede Naijiria.
NCDCA fi awon eeyan Naijiria lọkan balẹ lori Ebola, bo tilẹ jẹ pe o n gbilẹ si i lorilẹede Democratic Republic of Congo (DRC) ati Uganda.
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita lọjọ Aiku, ọga agba ajọ NCDC, Dokita Jide Idris, sọ pe "Naijiria ko ni ẹnikankan to ni arun Ebola lọwọlọwọ."
O fi kun un pe ajọ yii pẹlu awọn alẹnulọrọ ati ileesẹ eto ilera, ti gbe eto ifinmufnlẹ kan dide lati dena itankalẹ arun naa.
Dokita Idris rọ awọn eeyan Naijiria lati fọkan balẹ, ki wọn mu imọtoto ni koko, ki wọn ma si ṣe gbe iroyin ti ko ri bẹẹ kiri.
Bakan naa lo rọ awọn eleto ilera lati foju ṣọri, ki wọn maa ṣọ awon eeyan to ba fi apẹẹrẹ Ebola han, paapaa awọn to ba ti rin irin ajo.
O to eeyan 88 ti Ebola ti pa ni DRC Congo, apa ibi kan ti wọn pe ni Ituri ni arun naa ti n ṣọṣẹ, gba ẹmi ju, bi iroyin ṣe sọ.
Ajọ Ilera Agbaye kilọ nitori atankalẹ Ebola
Lọjọ Aiku, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Karun-un yii ni ajọ to n ri si ilera lagbaaye, 'World Health Organization' (WHO), kede pe ki gbogbo agbaye ṣọra fun arun Ebola to n tan kalẹ ni DRC.
Ibẹrubojo gbalẹ si I lẹyin ti ibudo ayẹwo kan tun fidi Ebola mulẹ ni apa Ila-Oorun DRC, nibi ti a mọ si Goma.
Wọn ni ẹnikan ni arun naa nibẹ.
Lapapọ, eeyan mejidinlaadọrun-un (88) ni iroyin sọ pe wọn ti padanu ẹmi wọn si ọwọ Ebola.
Eeyan 336 ni wọn ni o fara jọ pe awọn naa ti lugbadi arun iba to maa n mu ẹjẹ jade lara, gẹgẹ bi Africa Centres for Disease Control and Prevention (CDC Africa) ṣe kede lọjọ Satide.
"A ri akọsilẹ kan ti ayẹwo fi han pe o ti lugbadi arun naa ni Goma.
"O ni I ṣe pẹlu iyawo ọkunrin kan ti Ebola pa ni Bunia, to rin irinajo lati Goma lẹyin iku ọkọ rẹ nigba toun naa ti ko arun yii."
Ọjọgbọn Jean-Jacques Muyembe, Adari ẹka to n ri si ayẹwo ni Congo; Congolese National Institute for Biomedical Research' (INRB), lo ṣalaye bẹẹ fun ẹka iroyin AFP.Bakan naa ni ọga agba ajọ WHO; Tedros Adhanom Ghebreyesus, sọ pe bi onka awon to lugbadi arun naa ṣe n pọ si I n kọ eeyan lominu.
"Mo ri ohun to n ṣẹlẹ yii bii ohun ti gbogbo agbaye gbọdọ bojuto."
Bẹẹ ni ọga WHO naa kọ ọ soju opo X re, bo tilẹ jẹ pe o fi kun un pe ko ti I di ohun ti awọn le kede bii idagiri arun bawọn ẹka kan ṣe n gbe e kiri.


























