You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn àyípadà tí ìjọba Nàìjíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ mú bá ìsìnrú ìlú lẹ́yìn ọdún 53 ìdásílẹ̀ rẹ̀
Ijọba apapọ orilẹeede Naijiria ti ṣe awon ayipada to lọọrin lori eto isinru ilu ọlọdọọdun ti awọn akẹkọọjade nile ẹkọ giga maa n ṣe lẹyin ẹkọ wọn, eyi ti a mọ si NYSC.
Ọjọ Aje ni igbimọ alaṣẹ kede awọn ayipada naa lẹyin ipade apapọ wọn niluu Abuja.
Wọnyi ni awọn ayipada to ba ilana isinru ilu ti a tun mọ si Agunbanirọ
Awọn ologun ko ni i dari agunbanirọ mọ
Lati ilẹ wa, awọn ṣọja ni wọn maa n kọ awọn agunbanirọ lẹkọọ ijafafa bii ologun lasiko ti wọn ba fi wa ni ipagọ ọlọsẹ mẹta to bẹrẹ isinru ilu.
Rírìn lori okun, kiki ori bọ abẹ àgbá, yiyan bii ologun, ere sisa ati bẹẹ bẹẹ lọ ni awọn ṣọja maa n fi kọ awọn agunbanirọ naa laaarin ọsẹ mẹta ipagọ.
Amọ labẹ atunto tuntun yii, ijọba ti ni ṣọja ko ni i dari awọn agunbanirọ mọ, bi ko ṣe pe ọga nileeṣe ijọba ti ki i ṣe ologun rara ni yoo maa jẹ ọga agba ti yoo maa dari bayii.
Awọn adari mẹta ni yoo maa jẹ oluranlọwọ ọga agba naa, nigba ti sọja yoo kan maa ṣeranwọ aabo fun wọn nikan kaakiri Naijiria ni.
Ipagọ ọlọsẹ mẹta ti di ọsẹ mẹfa
Tẹlẹ, ọsẹ mẹta ni awọn agunbanirọ maa n lo ni ipagọ to ṣide isinru ilu ọdun kan.
Ilu kọọkan ni Naijiria lo ni agọ agunbanirọ ti wọn ti maa n lo ọsẹ mẹta ki wọn too pin wọn si aaye ti wọn yoo ti maa ṣiṣẹ isinru ilu naa lọ fun odun kan.
Amọ labẹ atunto to ṣẹṣẹ de yii, ọsẹ mẹfa ni ijọba apapọ sọ ipagọ naa da, o ti kuro ni mẹta.
Wọn ni eyi yoo da lori ẹkọ idagbasoke, ẹkọ nipa imọ ẹrọ igbalode, idadurofunra ẹni ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Labẹ eto yii ni awọn agunbanirọ yoo ti mu abala ti wọn ba fẹ bii eto ọgbin, ilera, eto ẹkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lilo imọ ẹrọ lati fi akoko isinru ilu to wọn leti :
Lodi si ilana lilo lẹta fi kede fun akẹkọọ to fẹẹ sinru ilu pe asiko ti to, ijọba ti ni imọ ẹrọ kikun ni wọn yoo maa lo bayii. Eyi yoo mu iṣẹ naa gunrege, yoo foju han lai si kọnu-n-kọhọ, yoo si tun ya kankan bi wọn ṣe wi.
- Ayipada yoo ba aṣọ ti wọn n wọ
Aṣọ kaaki alawọ ewe ati funfun ni awọn agunbanirọ Naijiria n wọ lati ọdun mẹtalelaadọrin ti wọn ti da a silẹ, amọ ijọba ti ni ayipada yoo ba aṣọ naa bayii.
Wọn ni eyi ti yoo fi ikọṣẹmọṣẹ han ti yoo si tun gbe ogo Naijiria jade ni yoo rọpo wayi.
- Yiyan jade bii ologun lẹyin ti wọn ba pari yoo yi pada di ayẹyẹ oye gbigba
Tẹlẹ, lọjọ tawọn akẹkọọgboye naa ba n pari eto isinru ilu, wọn a kora jọ soju kan, kaluku a wa lati oriko ti wọn pin in si, wọn a si ṣeto naa nilana atayebaye ti wọn maa n lo.
Ọjọ naa ni wọn maa n gba iwe ẹri 'mo ṣetan', awọn ti wọn ba si ti ṣẹ ẹṣẹ to le mu wọn ma gba iwe ẹri yoo gba afikun asiko ti wọn yoo fi tan ẹṣẹ wọn.
Amọ lọwọ yii, ijọba apapọ Naijiria ti ni ayẹyẹ ikẹkọọ-gboye ni yoo da.
Wọn ni yoo si maa yatọ gedegbe si bi wọn ṣe bẹrẹ eto naa.
Wọn yoo maa wo eto aabo ki wọn too gbe agunbanirọ lọ sibikibi:
Labẹ atunto yii ni ijọba ti ni ayẹwo finni-finni yoo maa waye daadaa nipa awọn agbegbe ti wọn yoo fi agunbanirọ ranṣẹ si, ṣaaju ki wọn too gbe wọn lọ sibikibi.
Ẹyi ṣe pataki bi wọn ṣe wi, lati ri i pe aburu kan ko ṣe ẹnikẹni ninu wọn lasiko isinru ilu.
- Abala ẹkọ ti wọn kọ ni wọn yoo fi pin wọn sibi iṣẹ:
Atunto yii fidi ẹ mulẹ, pe ẹka ẹkọ ti agunbanirọ ba ṣe nile ẹkọ ni wọn yoo lo lati fi pin wọn si ileeṣẹ ti wọn yoo ti sinru ilu.
- Atunṣe agọ agunbanirọ:
Bakan naa ni ijọba apapọ kede pe ayẹwo ti yoo le fidi ẹ mulẹ pe agọ agunbanirọ wa bo ṣe yẹ ko wa yoo waye.
Wọn yoo tun fidi ẹ mulẹ pe ibẹ daa lati fi ṣe agọ ki wọn too ko awọn agunbanirọ sibẹ.
Gbogbo eyi ni wọn lo wa fun lati ri i pe igba ọtun de ba eto ti a mọ si NYSC yii, bẹrẹ lati ibi aabo debi biba igba mu.
Bakan naa ni Aarẹ Tinubu paṣẹ pe ki Olootu idajọ orilẹede Naijiria, Lateef Fagbemi, ati Minisita to n ri si ọrọ awọn ọdọ, Ayodele Olawande, ri I daju pe wọn ṣe atunṣe ofin eto yii, ki awọn atunto tuntun yii si gberasọ lẹyẹ o sọka.