You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé lórí bí àkọsílẹ̀ káàdì NIN ti ṣèrànwọ́ láti mú ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram méje àtàwọn adarí ISWAP tó ń darí bọ̀ láti Mecca
Minisita to wa fun ọrọ abẹnu lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Olubunmi Tunji-Ojo, ti ṣalaye pe akọsilẹ ajọ to n ri si ọrọ kaadi idanimọ NIN ni Naijiria, NIMC, ti ṣe iranlọwọ nipa mimu ọmọ ẹgbẹ Boko Haram meje pẹlu awọn adari ikọ agbesunmọmi ISWAP kan to n dari bọ lati ibi isin Hajj ti wọn lọ ṣe ni Saudi Arabia.
Tunji-Ojo sọrọ yii lọjọ Ẹti, nile ijọba Naijiria to wa l'Abuja, kete ti Aarẹ Tinubu buwọlu ofin ajọ to n ri si idanimọ lorilẹede yii, (National Identity Management Commission Act 2026).
Bawo lọwọ ṣe ba Boko Haram meje atawọn ọga ISWAP naa?
Gẹgẹ bi Tunji-Ojo ṣe ṣalaye, o ni Ọjọbọ to kọja ni ọwọ ba awọn afurasi naa ni papakọ ofurufu ipinlẹ Katsina, lẹyin ti wọn de lati Mecca.
Minisita naa ṣalaye pe bi ọwọ ofin ṣe ba wọn naa ni wọn ṣe fa wọn le ẹka ọtẹlẹmuyẹ DSS lọwọ.
Nigba to n ṣalaye ipa ti ẹka to n ri si akọsilẹ idanimọ awọn eeyan ko ninu ọrọ yii, Minisita fun ọrọ abẹnu sọ pe ọwọ ba awọn eeyan naa pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to n ri si iwọle-jade ni Naijiria ti a mọ si Immigration, ati ajọṣe awọn ọlọpaa abẹnu ti a mọ si Interpol.
Tunji-Ojo ṣalaye pe "mo mọ pe nigba kan, ominu kọ Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria nipa bawọn agbesunmọmi ṣe lọ fun irinajo ẹsin, o n ya a lẹnu pe bawo ni wọn ṣe kọja lawọn ẹnu ibode wa.
"Amọ mo layọ lati sọ fun yin pe l'Ọjọbọ to kọja yii, meje ninu awọn adari Boko Haram ati ISWAP ti wọn lorukọ ni ọwọ ba nigba ti wọn n dari bọ lati Mecca, wọn mu wọn ni papakọ ofurufu ni Katsina, wọn si fa wọn le awọn DSS lọwọ.
"Eyi ṣee ṣe nitori idanimọ NIMC ti a ti so pọ mọ akọsilẹ awọn ẹka to n ri si iwọlejade, bẹẹ lo si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọpaa abẹnu lojoojumọ ati ni gbogbo wakati, a si ti n lo ẹrọ fun eyi."
O fi kun alaye rẹ pe ofin NIMC ti Aarẹ ṣẹṣẹ buwọlu yii yoo tubọ ro eto aabo Naijiria lagbara, nipa siso awọn akọsilẹ kaluku pọ lawọn ẹka to n ri si i.
Gẹgẹ bi Tunji-Ojo ṣe ṣalaye, ofin tuntun yii yoo ṣe iranlọwọ fun Naijiria lati ṣẹgun ole jija, igbesunmọmi, ajẹbanu, aisi aabo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Niṣoju Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Godswill Akpabio, Igbakeji Abẹnugan ile igbimọ aṣoju; Benjamin Kalu atawọn lọgaa-lọgaa mi-in lẹnu iṣẹ ọba ni Aarẹ Tinubu ti buwọlu ofin NIMC ti ọdun 2026 naa lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun yii.