Sunday Igboho ṣàlàyé ipò tí òun àtàwọn ẹ̀ṣọ́ Iru Ẹkun tó farapa nínú ìkọlù Old Oyo National Park wà

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludasilẹ ikọ eleto aabo Irun Ekun, Oloye Sunday Adeyemo tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ti sọ pe ko sewu loko lori iṣẹlẹ ikọlu tawọn janduku ṣe sawọn ẹṣọ Iru Ekun ninu igbo Old Oyo National Park lọsẹ ti kọja.

Igboho to sọrọ ninu fidio kan to wa lori ayelujara ṣalaye wi pe ara awọn ẹṣọ Iru Ekun to farapa naa ninu ikọlu Old Oyo National Park ti ya bayii.

Owo Baba Dami sọ pe oriṣiiriṣii iroyin loun ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa eyi tawọn eeyan n gbe kiri.

Igboho Ooṣa sọ pe alaafia ni oun gan an wa, o ni ko si nnkankan to ṣe oun.

''Mo n fi asiko yii sọ fun ẹyin ti ẹ jẹ ololufẹ mi wi pe ko si iyọnu kankan pẹlu mi.

Awọn baba wa maa n sọ pe ti ina ko ba tan laṣọ, ẹjẹ kii tan leekanna.

O digba ti gbogbo awọn Bororo ajinigbe ti wọn n dawọn eeyan wa laamu ba kuro ninu igbo wa tan ki a to sinmi pẹlu wọn,'' Igboho lo sọ bẹẹ.

Ọ̀pọ ẹ̀ṣọ́ ààbò Iru Ekun farapa bí wọ́n ṣe fìjà pẹ́ẹ́ta pẹ̀lú àwọn agbébọn nínú igbó Old Oyo National Park

Lọsẹ to kọja ni ọpọ awọn ọmọ egbẹ Iru Ekun to jẹ ẹṣọ aabo Oloye Sunday Igboho farapa yannayanna nigba ti wọn fija pẹẹta pẹlu awọn agbebọn ninu igbo Old Oyo National Park.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Nigerian Tribune ṣe sọ, iṣẹlẹ naa waye lasiko tawọn ẹṣọ aabo Iru Ekun n gbiyanju lati tọpinpin awọn agbebọn naa lọ ninu igbo Old Oyo National Park.

Wọn ni awọn ẹṣọ aabo naa gbiyanju lati lo duroonu lati fi ṣawari ibi ti awọn agbebọn naa wa ki wọn to tọ wọn lọ.

Ṣugbọn iṣẹlẹ naa di wahala nigba ti awọn afurasi agbebọn naa ti wọn ti gọ sibikan ṣina ibọn bolẹ fun awọn ẹṣọ aabo Iru Ekun naa ti awọn mejeeji si fija pẹẹta ninu igbo naa.

Wọn ni eyi ṣokunfa bi ọpọ awọn ẹṣọ aabo farapa yannayanna bi o tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi iye eeyan to farapa ninu iṣẹlẹ naa mulẹ.

Titi di asiko ti a n ko iroyin jọ, ileeṣẹ ọlọpaa ko i tii sọ ohunkohun lori ikọlu naa.