"Bí a ṣe kó sínu wàhálà lẹ́yìn tí wọ́n jí àwọn ọmọ wa gbé níbi tí wọ́n ti lọ ṣe ìdánwò"

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn obi awọn akẹkọọ ti awọn afurasi Boko Haram jigbe lasiko ti wọ n ṣe idanwo NECO nile-ẹkọ ijọba to wa lagbegbe Lassa, ijọba ibilẹ Askira/Uba nipinlẹ Borno ti sọ pe inu iporuru ati aibalẹ ọkan lawọn wa lati igba ti iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Lara awọn obi naa sọ fun BBC pe lati ọjọ Aje ti wọn ti gbọ nipa ikọlu naa, ni ọrọ aye wọn ti yi pada, nitori pe wọn ko tii mọ ibi ti awọn ọmọ wọn ọhun wa, depodepo ipo ti wọn yoo wa.

Wọn sọ pe ohun to n kọ wọn lominu bayii ni bi awọn ko ṣe tii gbọ ọrọ lati di awọn alaṣẹ nipa iye awọn akẹkọọ ti wọn jigbe, ati igbesẹ to n lọ lati gba wọn silẹ pada.

Ọkan lara awọn olugbe Lassa, to bẹbẹ pe oun ko fẹ darukọ ara oun, sọ fun BBC pe niṣe loun sare lọ si ile-ẹkọ naa nigba toun gburo ibọn, to si loun ri awọn eeyan ti wọn n sa asala fun ẹmi ara wọn.

O ni "Awọn ọmọ mi moribọ, ṣugbọn ọpọ awọn eeyan ni ko mọ ibi ti awọn ọmọ wọn wa. A ti lọ sile iwosan ati ibi ti awọn oṣiṣẹ eleto aabo ko awọn to moribọ pamọ si, ṣugbọn wọn ko ri wọn nibẹ.

Ni bayii, ohun ti a kan le ṣe ni lati gbadura."

O ni awọn nigbagbọ pe awọn ti wọn jigbe ko din ni aadọta, bo tilẹ jẹ pe awọn mẹjọ pada ja ajabọ ninu wọn.

Obinrin alabiyamọ kan sọ pe latigba toun ti gbọ wi pe ile-ẹkọ ti ọmọ oun ti n kọ idanwọ rẹ lọwọ ni awọn agbebọn lọ ṣe ikọlu si, ni ọkan oun ko ti balẹ mọ, ti alaafia si ti jinna si oun.

Ẹni naa sọ pe "A ran awọn ọmọ wa jade lati kọ idanwo. A ko mọ wi pe wọn maa lọ ko wọn ninu yara idanwọ.

Adura la n gba wi pe ki Ọlọrun mu wọn pada layọ ati alaafia."

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

A gbọ pe owurọ, ọjọ Aje ni wọn ṣe ikọlu si awọn akẹkọọ naa, lasiko ti wọn n kọ idanwo NECO lọwọ. Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn afurasi ọmọ ogun ISWAP naa ni wọn wọ ilu Lassa pẹlu alupupu, ti wọn si dori kọ ile-ẹkọ girama to jẹ ti ijọba naa.

Wọn ni aarin ọja ti wọn maa n na ni gbogbo ọjọ Aje ni wọn gba kọja.

Gbara ti wọn ti wọ ile-ẹkọ ọhun ni wọn ti bẹrẹ sii yinbọn lakọlakọ, to si mu ki awọn akẹkọọ, olukọ ati awọn eeyan maa sa kijokijo.

Igba to ya ni wọn ji lara awọn akẹkọọ naa ati awọn obinrin to n ta ounjẹ ninu ọgba ile-ẹkọ, ko to di pe wọn gba inu igbo salọ. Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Borno, Nahum Daso fidi ikọlu naa mulẹ.

O sọ pe awọn ẹṣọ alaabo gbena woju awọn afurasi naa lẹyin ikọlu ọhun, lati dena wọn nipa jijẹ ki erongba wọn wa si imuṣẹ.

"Nnkan bi agogo mẹsan owurọ ni ikọlu to waye nile-ẹkọ girama ti ijọba ti Lassa. Awọn to ṣe ikọlu naa ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si ji awọn eeyan ti wọn ko lero gbe.

Ọga ọlọpaa ti ran alakoso ẹkun Askira/Uba, pẹlu awọn alaabo, ati pe wọn ṣi n tẹsiwaju lati maa wa awọn to ṣe ikọlu ọhun ninu igbo."

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ko tii le ṣe akọsilẹ iye awọn eeyan ti wọn jigbe, ati pe iwadii ṣi n lọ lọwọ. Ikọlu yii lo tun ti ta awọn olugbe ipinlẹ Borno ji, nibi ti wọn ti ṣe ikọlu si ẹmi ati dukia awọn eeyan, pẹlu bi awọn oṣiṣẹ eleto aabo ṣe n sọ pe awọn ti tẹsiwaju lori ọrọ eto aabo.

Koda, ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, awọn afurasi-aṣẹkupani kan yawọ ile-ẹkọ alakoọbẹrẹ Mussa ati ile-ẹkọ girama kekere nijọba ibilẹ Askira/Uba.

Nigba naa, Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Guusu Borno, Ali Ndume sọ fun BBC pe awọn ọmọ mejilelogoji, to fi mọ akẹkọọ ile ẹkọ girama kekere ati agba ti wọn gbe nile wọn, ti wọn ko si tii ri wọn.

Ṣugbọn ṣa o, awọn alakoso eto aabo ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lẹyin ikọlu naa, sibẹ, iṣẹlẹ naa tun tọka si awọn adojukọ to n doju kọ eto aabo lagbegbe ọhun.

Lati ọdun 2014, nigba ti awọn Boko Haram ji awọn akẹkọọbinrin ọgọrinlenigbadinmẹrin gbe nile-ẹkọ ijọba to wa ni Chibok, awọn ile-ẹkọ to wa lẹkun Ariwa-Ila-Oorun Naijiria, ni wọn ti n koju idunkooko lọwọ awọn agbebọn aṣekupani.

Igba to ya ni wọn pada tu ninu awọn akẹkọọ Chibok ọhun silẹ, nigba ti awọn miran sa mọ wọn lọwọ, ṣugbọn sibẹ, ko tii sẹni to mọ ibi ti wọn wa.

Awọn akọṣẹmọṣẹ eleto aabo ti sọ pe ikọlu to n lọ lẹkun Ila-Oorun fi han pe awọn Boko Haram ati ISWAP ṣi ni agbara lati ṣe ikọlu ni awọn agbegbe to jinna si itẹdo awọn eleto aabo.

Fun awọn mọlẹbi awọn akẹkọọ Lassa, ohun kan ṣoṣo to n kọ wọn lominu julọ bayii ni lati gba awọn ọmọ wọn silẹ, ki wọn si tun pada foju kan wọn.