You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mi ò kí ń ṣe aláìmoore bíi Aregbesola, mo máa ṣàtìlẹ́yìn fún Tinubu fún sáà kejì – Igboho
Ajijagbara fun ominira ilẹ Yoruba nigba kan ri, Oloye Sunday 'Igboho' Adeyemo ti sọ pe oun yoo ṣatilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu fun saa keji rẹ nipo Aarẹ, nitori oun kii ṣe alaimoore bii gomina ipinlẹ Osun nigba kan ri, Rauf Aregbesola.
O ni gbogbo agbara oun loun yoo fi ṣatilẹyin fun Tinubu nitori oun ko le pa ore ti Tinubu ṣe fun oun mọra.
Igboho lo sọ ọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si ọọfisi awọn ọdọ ẹgbẹ oṣelu APC lorilẹede Ghana.
Gẹgẹ bii Igboho ṣe sọ, "Mo dupẹ fun Ọlọrun pe mo tilẹ ri oore ọfẹ gba lati ọdọ baba wa Bola Ahmed Tinubu. Oore ọfẹ ti mo ri gba ni mo fi le wa sọdọ yin lonii lati wa ki yin.
"Mo maa tẹsiwaju lati maa ṣatilẹyin fun ijọba Bola Tinubu nitori oun lo mu mi pada wale lati ilẹ okere.
"Ko nilo pe a n fi akoko ara wa ṣofo, baba yoo ṣe ẹlẹẹkeji, iyẹn daju lọdọ Ọlọrun to ni wa, baba yoo ṣe ẹlẹekeji."
Igboho tẹsiwaju pe ọpọ ọmọ Yoruba ni Tinubu ti ṣe oore fun ti wọn si fi ibi san pada fun.
O ni "Ẹ wo iru awọn eeyan ti baba yẹn ṣe oore fun, ti wọn jẹ ọmọ Yoruba, ti wọn tun fi ibi ṣu, ara wọn ni Aregbesola yẹn.
"Iru anfani ti Aregbesola ni lọdọ baba wa Tinubu, ọpọlọpọ eeyan ni ko ni iru ẹ."
Igboho sọ pe pẹlu iranlọwọ Tinubu ni Aregbesola fi bẹrẹ irinajo oṣelu lati ipo kọmiṣọna titi to fi de ipo minisita.
O ni nitori naa ko yẹ ko jẹ irufẹ eeyan bii Aregbesola ni yoo maa tako Tinubu.
Ajijagbara naa sọ pe lootọ ni eeyan yoo maa ṣẹ ara wọn nile aye amọ ko tọ ki eeyan gbagbe oore nitori pe ẹnikan ṣe ẹnikeji.
Igboho pari ọrọ rẹ pe niwọn igba ti Obasanjo ati Buhari ti le ṣe ọdun mẹjọ gẹgẹ bii Aarẹ Naijiria, Tinubu naa gbọdọ ṣe ọdun mẹjọ tirẹ ko pe.
Wayi o, ọpọ araalu lo ti n bu ẹnu atẹ lu ọrọ Igboho naa.
Pupọ awọn eeyan ọhun n sọ pe lootọ ni Aarẹ Tinubu le ṣe Igboho looore amọ kii ṣe gbogbo ọmọ Naijiria ni oore naa kan, nitori naa ki Igboho maṣe sọrọ lorukọ gbogbo araalu pe Tinubu gbọdọ ṣe ọdun mẹjọ.