Ọ̀nà wo ni ìṣéde tíjọba Oyo ṣe yóò gbà nípa lórí aráàlú láwọn ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá tọ́rọ̀ kàn?

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọpọ awọn eeyan to n gbe ni awọn ilu nlanla ati kekeke to wa ni ijọba ibilẹ mẹwaa nipinlẹ Oyo ti n sọ ero wọn nipa isede tijọba ipinlẹ Oyo kede lagbegbe wọn.

Bẹẹ ba gbagbe, aarọ ana nijọba ipinlẹ Oyo kede konile-ogbele lọna ati dena ijinigbe awọn akẹkọo ati olukọ nipinlẹ naa.

Awọn ijọba ibilẹ mẹwaa to wa ni ayika Old Oyo National Park ni isede naa kan.

Isede ọhun yoo bẹrẹ lati aago mẹrin irọlẹ si aago mẹjọ aarọ ọjọ keji, eyi tii se wakati mẹrindinlogun gbako.

BBC Yoruba kan si awọn eeyan ti wọn n gbe nilu Igboho atawọn ijọba ibilẹ ti ọrọ naa kan, pupọ ninu wọn ni wọn sọ pe awọn faramọ igbesẹ ọhun.

Gẹgẹ bi ohun ti awọn ti a ba sọrọ sọ fun wa, wọn ni ẹmi lo ju, bẹẹ ni ẹmi ko laarọ, nitori naa, ohunkohun ti ijọba Oyo ba ṣe lori ipese aabo to peye lo tẹ awọn lọrun.

Lara awọn ti a ba sọrọ ni ọgbẹni Aladan to n ṣe iṣẹ mọnamọna to ni isede naa ko ni pa oun lara rara latari pe iṣẹ oun ti maa n pari ko to di aago mẹrin irọlẹ.

O ni "Oniṣẹ ọwọ ni mi, ko le pa wa lara to bẹẹ, igbesẹ ti ijọba gbe ni lati daabo bo ẹmi wa, nitori naa o tẹ awa lọrun.

"Ti mo ba lọ si ibiṣẹ laarọ, mo ti maa n de titi aago mẹrin irọlẹ, aago mẹrin irọlẹ ni mo maa n ṣetan.

Koda ti mo ba lọ sinu oko gan, mo ti maa n pada ki aago mẹrin irọlẹ to lu."

BBC Yoruba tun kan si ọgbẹni Olawuwo to jẹ awakọ, to maa n na ilu Ibadan siluu Igboho, oun naa sọ pe igbesẹ ijọba ọhun tẹ oun lọrun.

O ni "Ti ilu ba wa lalaafia, ni awa ti a n bẹ laarin ilu naa yoo ni lalaafia.

"Gbogbo asiko ti isede naa ba gba wa, a o farada naa ni o, nitori aabo lo ṣe pataki.

"Igbesẹ ti ijọba ṣẹṣẹ n gbe yii, o yẹ ki wọn ti gbe siwaju, kii ṣe iru akoko yii lo yẹ ki wọn ṣẹṣẹ gbe."

Ọkunrin naa ni niwọn igba ti ọkọ oun ko ba ti yọnu, ko si ohun to ni ki oun ma wọle ṣaaju aago mẹrin irọlẹ.

O ni irinajo Ibadan si Igboho ko kọja wakati marun un si mẹfa pere.

Nipa bi iye owo ti yoo maa pa wọle loojọ yoo ṣe dinku, ọgbẹni Olawuwo sọ pe "To ba dinku, ko ni itumọ, a ni ki alaafia ṣa ti jọba ni koko."

Ẹlomii ti a tun ba sọrọ, Azeez Alaga to n ṣiṣẹ akoyanri sọrọ bii awọn to ṣaaju rẹ pe niwọn igba to jẹ pe fun anfani araalu ni igbesẹ naa, oun faramọ isede ọhun.