"Èyi ni ohun tí Olúwa sọ fún mi nípa ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti àwọn olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso" – Pásítọ̀ Adeboye

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Oludari ijọ Onirapada Kristẹni (RCCG),Pasitọ Enoch Adeboye, ti ṣalaye ohun to ni Oluwa fi han oun lori awọn akẹkọọ atawọn olukọ tawọn agbebọn ji gbe loṣu to kọja.

Ẹ o ranti pe ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn yabo ile ẹkọ mẹta ni l'Ahoro Esinele, Yawota ati Alausa ti wọn wa nijọba ibilẹ Oriire niluu Ogbomoso, ipinlẹ Oyo.

Wọn pa tiṣa kan nile ẹkọ naa, wọn si tun fi fidio ibi ti wọn ti bẹri olukọ ọkunrin kan han lori ayelujara.

Latigba naa ni awọn yoku ti wọn ji gbe ọhun ti wa nigbekun, ti igbesẹ si n lọ lọtun-un losi lati gba wọn jade.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ninu fidio kan to wa lori ayelujara, eyi ti wọn ya nibi eto kan ni Washington, D.C, Pasitọ Adeboye sọ pe bi ijinigbe naa ṣe ṣẹlẹ ni oun ti wa oju Oluwa lati gbọ ohùn rẹ.

"Iyanu ni itusilẹ awọn eeyan naa yoo jẹ, yoo ṣẹlẹ lojiji ni''

Ninu ọrọ Baba ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84) naa lo ti ni:

" O di dandan fun mi lati sunkun tọ Oluwa lọ, nitori a ti n gba aawẹ ati adura lori awọn akẹkọọ kan ti won ji gbe."

"Awọn to ji wọn gbe ro pe ijọba ko tete fun awọn lowo ti wọn beere, wọn si dumbu tiṣa wọn kan, wọn fi fidio rẹ han gbogbo aye.

"Nigba naa ni awọn kan bẹrẹ si i beere pe nibo ni Ọlọrun wa wa? Awa ta a ni a n gba aawẹ ati adura, nibo ni Ọlọrun wa wa? Ohun to jẹ ki n sunkun tọ Oluwa lọ niyẹn.

'Mo ni Baba, o ti gbọ wọn, wọn ni nibo ni Ọlọrun wa wa. Nigba naa ni Ọlọrun ba mi sọrọ.

"O ṣo fun mi pe bii ere ni itusilẹ awọn ọmọ naa yoo ri, ijọloju ti yoo ṣẹlẹ lojiji ni."

Bẹẹ ni Oludari ijọ RCCG naa wi.

Ọlọrun ko sọ asiko ti yoo jẹ fun mi

Ni itẹsiwaju ọrọ rẹ, Pasitọ Adeboye sọ pe Oluwa sọ pe Oun yoo mu ileri ṣẹ lori itusilẹ awọn akẹkọọ ati olukọ wọnyi ṣẹ.

Bakan naa lo ni Oluwa tun ba oun sọrọ lori awọn nnkan mi-in nipa Naijiria yii.

Adeboye ni amọ Oluwa ko sọ asiko pato ti itusilẹ naa yoo jẹ.

Ṣugbọn o ni Oluwa sọ pe koun fi eyi silẹ sọwọ Oun.

O ni lẹyin eyi ni Oluwa sọ pe Oun yoo tun sọrọ siwaju.

O fi kun un pe Oluwa sọrọ nipa awọn to n ran igbesunmọmi ati ijinigbe lọwọ lorilẹede yii.

Alagba Adeboye sọ pe ibanujẹ ọkan ni awọn ohun to n ṣẹlẹ lorilẹede yii n jẹ fun oun, paapaa awọn eyi to kan awọn Onigbagbọ ti i ṣe Kristẹni.

"Aarẹ Tinubu gbe igbesẹ nigba ti mo ni ko wa ojutuu si ọrọ aabo"

Lori bi eto aabo ṣe mẹhẹ ni Naijiria, Pasitọ Adeboye sọ pe loṣu Kọkanla ọdun 2024 ni oun sọ fun Aarẹ Tinubu, pe ko paṣẹ fun awọn ẹṣọ aabo lati ṣẹgun igbesunmọmi ati ijinigbe tabi ki wọn fipo silẹ.

O ni Aarẹ gbe igbesẹ naa loootọ bo ṣe yẹ, o si paṣẹ naa.

"Lẹyin ti mo sọrọ nita bẹẹ, wọn ni ki n wa ri Aarẹ ati iyawo rẹ. A sọrọ, mo si sọ ohun ti mo sọ nita gbangba fun wọn.

"Baba, ẹ ma fi akoko ṣofo, ẹ ba Aarẹ Trump sọrọ, ẹ lọ sọdọ awọn aṣoju, e pe awọn ologun yin, ẹ paṣẹ fun wọn. "Aadọrun ọjọ, ki wọn rẹyin gbogbo radarada yii tabi ki wọn fipo silẹ, kẹ ẹ si wa fabọ leri awon to n ṣatilẹyin fun igbesunmọmi."

Pasitọ Adeboye sọ pe bẹẹ ni oun sọ fun Tinubu.

O ni Aarẹ si gbe igbesẹ naa, nitori iroyin gbe e pe o ba America sọrọ, awọn jagunjagun wọn si wa.

O ni lọjọ Keresimesi ni ado oloro balẹ ni Naijiria lati koju awọn aṣebi.

"Aarẹ ni olori ogun, o paṣẹ bii olori, emi o mọ ohun to ba wọn sọ.

"Bi olori ogun ba n paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ rẹ, ta a niwọ lati wa nibẹ."

"Ẹ ma ṣe ro pe Tinubu yoo gbe khaki wọ lori ọrọ yii, o ti ṣe ohun to yẹ ko ṣe"

Ni ti ọrọ aabo Naijiria yii naa, Alagba Adeboye sọ pe oun ko le ba wọn sọ pe Tinubu ko gbiyanju, nitori o ti ṣe ojuṣe rẹ to yẹ ko ṣe.

O ni ki araalu ma ṣe ro pe Tinubu yoo tori ọrọ yii gbe khaki ologun wọ, ohun to yẹ ko ṣe lo ti ṣe.

O ṣakawe pe bi Aarẹ Trump naa ba paṣẹ, ki i ba wọn lọ sibi ohun to fẹ ki wọn ṣe, yoo paṣẹ rẹ yoo si wọ yara rẹ lọ sun ni.