Kí ló fa gbas-gbos láàárín Akpabio àti Oshiomhole nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin, àlàyé rèé

Senetọ Adams Oshiomhole ati Godswill Akpabio; olori ile igbimọ aṣofin agba Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others/Godswill Akpabio

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Laipẹ ti i pẹ rara ti ile igbimọ aṣofin agba Naijiria ṣe atunṣe ofin to de awọn aṣofin to ti wa nile igbimọ tẹlẹ lori bi wọn ṣe le pada dupo, Olori ile igbimọ naa, Godswill Akbapio ati Senetọ Adams Oshiomhole to n ṣoju Ariwa ipinlẹ Edo, ti gbena woju ara wọn.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, o to iṣẹju mẹwaa ti aigbọra ẹni ye to waye laaarin awọn mejeeji fi ṣẹlẹ, lẹyin naa si ni ipade ṣẹṣẹ bẹrẹ pada.

Itahun sira ẹni naa waye nigba ti Akbabio bẹrẹ si i ka akọsilẹ ijokoo ọjọ Iṣẹgun l'Ọjọru.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Iroyin sọ pe bi Akpabio ṣe n ka akosilẹ ohun to ṣẹlẹ nile igbimọ lọjọ Iṣẹgun, Oshiomhole pe e si akiyesi kan to ni o tako ofin ile.

Ṣugbọn Olori ile igbimọ aṣofin naa ko gba a laye lati sọrọ.

Akpabio sọ pe ofin ile ti wọn ṣe ni 2023 ko faaye gba dida ọrọ mọ eeyan lẹnu lasiko bi eyi.

Lẹyin naa ni wọn tẹsiwaju ninu ipade wọn.

Ṣugbọn ko pẹ ti wahala mi-in tun fi rugbo de, nigba ti Olori ile fẹ sọrọ lori atunṣe ofin ile igbimọ naa to waye laipẹ.

Bo ṣe gbe ẹnu le ọrọ naa ni Oshiomhole tun gbiyanju lati ta a ko o.

Ṣugbọn Akpabio tun ran an leti pe ofin ọdun 2023 fun ile naa ko faaye gba idasi rẹ niru asiko bẹẹ.

Nigba ti Oshiomhole taku pe oun gbọdọ sọrọ, Akpabio pe akójàánu ile naa tẹlẹ, Senetọ Orji Kalu, lati ṣalaye ofin ọhun fun un.

Iroyin sọ pe Kalu dide, o si sọ fun Oshiomhole pe ko si aaye lati pe akiyesi ohunkohun lasiko ti wọn ba n ka ibo ati ohun to ṣẹlẹ nile igbimọ lọwọ.

Ki lo de ti Oshiomhole ṣe bẹẹ nile igbimọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Igbagbọ ọpọ eeyan ni pe bi ko ba si ohun to ṣe ẹ̀ṣẹ́, ẹ̀ṣẹ́ ki I deede ṣe.

Wọn ni atunṣe ofin ti ile igbimọ ṣẹṣẹ ṣe, ti ko jẹ ko rọrun fun awọn aṣofin kan lati le dije pada mọ lo n mu Oshiomohole gbarata.

Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ipade atilẹkunmọriṣe kan ni ile naa jẹ ko di mimọ, pe oun ti ṣe atunṣe si abala kẹrin ati ikarun.

Awọn abala mejeeji yii le ma jẹ ko rọrun fun awọn aṣofin to ti wa nile, atawọn to n dipo mu lọwọ lati dije.

Labẹ ofin naa, awọn sẹnetọ ti wọn ti wa nipo fun o kere tan, ẹẹmeji leralera ki wọn too tun yan wọn ni wọn le dupo olori.

Labẹ ofin kẹrin (Order 4), wọn gbọdọ wo ipo ti olori wa ki wọn too fa a kalẹ, lati ori Aarẹ ile tẹlẹ de ori awon aṣofin to ti ṣe saa meji.

Ofin Karun-un (Order 5) naa tun paṣẹ pe awọn sẹnetọ to ba ti ṣe saa meji, o kere tan, ni wọn le dupo to ṣe koko nile igbimọ.

Awọn ofin yii ti ka Senetọ Oshiomhole lọwọ ko, pẹlu bo ṣe jẹ pe saa akọkọ lo n ṣe lọwọ.

Bẹẹ naa lo si ri fun awọn sẹnetọ mi-in naa to jẹ saa kan ṣoṣo ni wọn ṣi n ṣe.

Bi ofin naa ṣe jọ pe o ti yi wọn lagbo da sinu ni wọn lo mu Senetọ Oshiomhole ṣe ohun to ṣe nile igbimọ aṣofin.