Ọkùnrin méje tó ṣe pàṣí-pààrọ̀ ìyàwó bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá Hisbah

Oríṣun àwòrán, HISBAH
Ya mi lowo, ya mi laṣọ atawọn nnkan elo miran ṣee gbọ, ya mi ni iyawo tabi ọkọ rẹ ko dẹrun lati sọ lẹnu.
Amọ ikede ti Hisbah, munimuni to n lo ilana Sharia lapa Ariwa Naijria ti kede pe awọn eeyan meje kan n ṣe paṣi-paarọ iyawo wọn nipinlẹ Bauchi, wọn si n ba awọn obinrin naa lo pọ lọtọọtọ.
Ẹka Hisbah ipinlẹ Bauchi ṣalaye pe agbegbe Azare, nijọba ibilẹ Katagum, ni ọwọ ti ba awọn baale ile meje ti wọn ni wọn n paarọ iyawo naa.
Hisbah sọ pe eyi lodi si iwa ọmọluabi.
"Awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Wuddadu lo n ṣe paṣi-paarọ iyawo"
Gẹgẹ bi Hisbah ṣe kede, awọn kan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Wuddadu lo n paarọ iyawo mọra wọn lọwọ.
Olori ikọ Hisbah nijọba ibilẹ Katagum, Malam Ridwan Muhammad Khairan, ṣalaye fun awọn akọroyin pe awọn nawọ gan awọn meje naa lẹyin ti ifisun wa latọdọ awọn olugbe agbegbe yii, pẹlu awọn ti iwa naa ko tẹ lọrun ninu ẹgbẹ Wuddadu.
O fi kun un pe iwadii fi han pe awọn ọkunrin naa finu-fẹdọ ṣe paṣi-paarọ iyawo wọn ni, awijare wọn si ni pe ẹsin Islam fi aaye gba iru ẹ.
"Ko si idi kankan fun iru nnkan bẹẹ ninu Islam. Igbeyawo gbọdọ tẹle awọn alakalẹ ilana ni, ohun ti wọn si ṣe yii tako Sharia, àgbèrè lo tumọ si."
Bẹẹ ni Khairan ṣalaye.
O tẹsiwaju pe ikọ Ko Ba Kobo to wa ninu kọmandi naa lo mu awọn eeyan yii lẹyin ti iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ fi wọn han.
Bakan naa lo ni iṣẹ yoo maa tẹsiwaju lati mu awọn eeyan to ba n ṣe ohun to tako ẹsin ati iwa ọmọluabi.
O rọ awọn araalu lati maa foju ṣọri, ki wọn si tete maa fi ẹjọ awọn oniwakiwa to n purọ mọ ẹsin Islam sun.
O ni ki wọn maa tẹle itọni ẹsin Islam bi aṣẹ Oluwa, ki wọn yago fun iwa aitọ.
Gbogbo wa kọ la n paarọ iyawo ninu ẹgbẹ Wuddadu-Olórí
Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ paṣi-paarọ iyawo yii, Olori ẹgbẹ Wuddadu, Malam Sagir Bashir, sọ pe gbogbo ẹgbẹ kọ lo n huwa aitọ naa.
Gẹgẹ bo ṣe wi, awọn diẹ ninu awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni wọn n paarọ iyawo wọn.
Malam Sagir ṣalaye pe ọpọ igbesẹ ni ẹgbẹ ti gbe, pẹlu ibaraẹnisọrọ ati ikilọ, pe ki wọn dẹkun a n paarọ iyawo, amọ wọn ko dahun.
O ni wọn n huwa aitọ naa lọ labẹnu.
Olori ẹgbẹ Wuddadu sọ pe awọn pinnu lati sọ ohun to n ṣẹlẹ fun Hisbah, ki iwa to tọ le wa lawujọ awọn.
O ni awọn tọwọ ba yii ti figba kan ṣeleri fun ẹgbẹ pe awọn yoo jawọ ninu paṣi-paarọ iyawo, nigba ti awọn kilọ fun wọn.
Aigbọ lo ni o mu wọn dẹni ti ọwọ ofin ba bayii, ti wọn yoo si
ṣalaye ara wọn labẹ ofin.


























