Ọlọ́pàá tó kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi ní mo gbọ́dọ̀ ṣẹ̀wọ̀n - Ọmọbìnrin ọdún 15 táwọn ọlọ́pàá mú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní Kwara ṣàlàyé

Àkọlé fídíò, Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá tó mú mi bámi sọ̀rọ̀ ìfẹ́, mo kọ̀
Ọlọ́pàá tó kọ ẹnu ìfẹ́ sí mi ní mo gbọ́dọ̀ ṣẹ̀wọ̀n - Ọmọbìnrin ọdún 15 táwọn ọlọ́pàá mú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní Kwara ṣàlàyé

Obinrin kan niluu Arandun, nipinlẹ Kwara ti ke gbajare sawọn ọmọ Naijiria fun iranlọwọ lẹyin to fẹsun kan awọn ọlọpaa pe wọn ti ọmọ oun obinrin to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun mọle fun odidi ọjọ mẹta gbako.

Ninu fidio kan to n mi igboro titi loju opo X ni obinrin naa ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara pe wọn mu ọmọ naa dipo ẹgbọn rẹ ti wọn fẹsun ole jija kan lẹyin ti ẹgbọn rẹ to jẹ afurasi na papa bora.

Inu fidio ọhun ni a ti ri bi awọn mọlẹbi ọmọdebinrin naa ṣe n pariwo lagọ ọlọpaa pe ko tọ ki wọn ti ọmọ kekere mọle.

Irọ ni wọn pa mọ wa, a ko ti ọmọde mọle lọna aitọ - Ọlọpaa

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti fesi so ọrọ naa pẹlu alaye pe irọ ni ẹsun ti mọlẹbi naa fi kan oun.

Ninu atẹjade ti agbẹsnusọ rẹ, ‎SP Adetoun Ejire-Adeyemi fi ṣọwọ si awọn akọroyin lọjọ Aje, o fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni ọlọpaa mu ọmọde ọhun.