Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Dele Odule tó fi lọ béèrè iye tí wọ́n ń ta pósí fún ara rẹ̀? Ìdí abájọ rèé

Dele Odule wọ ẹṣiki funfun, o si de fila funfun

Oríṣun àwòrán, Dele Odule/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbaọjẹ oṣere ori itage, Dele Odule, ti ṣalaye ninu ifọrọwerọ kan to ṣe wi pe oun ti lọ na posi fun ara oun ri nigba ti gbogbo nnkan doju ru foun.

Gbajugbaja oṣere naa sọ pe oun gbe igbesẹ yii lẹyin ti ọrọ aye oun ko ye oun mọ.

O ni oun lọ beere iye ti wọn n ta posi lagbegbe kan niluu Abeokuta lẹyin toun pinnu lati gbẹmi ara oun.

Ọgbẹni Odule sọ pe oun ṣe eleyii ki awọn eeyan maa ba le maa fi oun ṣe yẹyẹ.

''Ọrọ ara mi ko ye mi mọ nigba naa, mi o si ni igbagbọ wi pe mo le laluyọ mọ lẹnu iṣẹ mi.

Awọn eeyan bii Olaiya Igwe mọ nipa ọrọ ti mo n sọ yii tori a jọ de ibẹ ni.

Olaiya bu sẹkun nigba ti o bami de ibi ti mo ti lọ beere iye ti wọn n ta posi l'Abeokuta.

Aarẹ ko ṣe mi, mi o kan gbagbọ pe mo le laluyọ mọ laye ni.

Gbogbo rẹ ti su mi tori gbogbo awọn ti a jọ lọ si ile ẹkọ olukọni Grade Two lo ti di ọga lẹnu iṣẹ wọn,'' Odule lo sọ bẹẹ.

Gbajumọ oṣere naa tun sọ nipa bi ọmọkunrin rẹ kan ṣe ṣaisan ti oun si bẹrẹ sii gbe e kaakiri lati wa iwosan.

Odule sọ pe niṣe lawọn n gbe ọmọ naa lati ile iwosan kan si omiran to fi mọ ile iwosan UCH niluu Ibadan.

Alawo sọ pe ti a ba ṣe irubọ fun ọmọ mi to n ṣaarẹ, yoo gbadun - Dele Odule

Ilumọọka oṣere naa fikun ọrọ rẹ pe iṣoro toun ni yii lo jẹ ki oriṣiiriṣii aafa, pasitọ atawọn alawo wọle si oun lara.

''Oriṣiiriṣii imọran ni wọn n fun mi, bawọn kan ti n sọ pe ka gbe ọmọ naa lọ sori oke lawọn mii n sọ pe kawọn aafa ṣe hantu fun un ko le gbadun.

Bakan naa lawọn alawo n sọ pe ti a ba ṣe irubọ fun ọmọ naa, yoo gbadun.

Gbogbo nnkan ti wọn sọ yii ni mo ṣe patapata.''

Dele Odule sọ pe alawo kan lẹgbẹẹ Ijebu Igbo lo sọ foun pe kawọn lọ din akara igba ati ẹyọkan lati fi ṣe saara fawọn eeyan ki ọmọ naa le gbadun.

Amọ, o ni eewọ to wa nibẹ ni pe akara meji ti wọn ba kọkọ din gbọdọ so pọ, bi bẹẹ kọọ, ọmọ naa ko le ye.

Gbajumọ oṣere naa ni ọrọ ọhun dabi ẹni pe wọn ti kede iku ọmọ oun ni.

O ni ọrọ naa tumọ si pe wọn ti dajọ iku ọmọ oun ni, tori ti akara meji naa ko ba so pọ iku ti de.

Ilumọọka oṣere naa sọ pe Ọlọrun nikan lo lagbara wi pe nnkan ti Eledua ba ti sọ pe o maa ṣẹlẹ nikan ni yoo ṣẹlẹ si ẹda laye.