Ṣé lóòótọ́ ni Ààrẹ Naijiria lè máa ṣèjọba láti ilẹ̀ òkèrè?

Oríṣun àwòrán, facebok/Bola Tinubu/Kashim Shettima
Ijọba apapọ ti sọ pe aarin ọsẹ yii ni Aarẹ Bola Tinubu yoo pada si Naijiria lẹyin to ti kọkọ lọ sinmi loke okun fun nnkan bii ọjọ mọkanlelogun.
Agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi lede loju opo X rẹ pe "koko lara Aarẹ le" ati pe ko ṣaisan gẹgẹ bi awọnkan ṣe lero.
O ni "O lọ fun isinmi iṣẹ eyii to lẹtọ si labẹ ofin. Laye ayelujara ti a wa yii, ko di dandan ko wa niluu Abuja lati ṣiṣẹ ti awọn araalu yan an fun lọdun 2023."
Gẹgẹ bi Onanuga ṣe sọ, Tinubu ti ṣe ipade pẹlu awọn olokoowo kan ni France lasiko isinmi naa, o tun sọ pe Tinubu lọwọ si bi awọn oniṣowo agbaye ṣe fẹ wa na owo ti iye rẹ to $7b nipinlẹ Ogun papakọ eti okun to wa nibẹ.
Ọrọ Onanuga yii lo n jẹyọ latari bi awọn ọmọ Naiiiria kan ṣe n sọ pe awọn ko ri Tinubu nibi ipade agbaye, UNGA 81, to waye niluu New York, nilẹ Amẹrika.
Amọ ṣa, ọpọ eeyan lo n bu ẹnu atẹ lu Tinubu lori bo ṣe lọ isinimi naa lai gbe ijọba kalẹ fun igbakeji rẹ, Kashim Shettima.
Ko ba ofin mu bi Tinubu ko ṣe gbe ijọba kalẹ fun Shettima – Agbẹjọro
Lọna ati mọ oju ti ofin fi wo ki Aarẹ rinrinajo lọ ilẹ okeere lai gbe ijọba silẹ fun igbakeji rẹ,
BBC Yoruba kan si agbẹjọro Victor Opatola lati tan imọlẹ si.
Nigba to n ba wa sọrọ, Opatola sọ pe ko tọ labẹ ofin ofin ki Aarẹ lọ ilẹ okere lai gbe ijọba silẹ fun igbakeji rẹ.
Gẹgẹ bo sẹ sẹ, Aarẹ gbọdọ kọwe si ile igbimọ aṣofin agba ko to lọ si eyikeyi irinajo, amọ to ba kọ lati ṣe bẹẹ, ile igbimọ aṣofin naa gbọdọ gbe agbara ijọba silẹ fun igbakeji Aarẹ.
O ni "Abala 145 iwe ofin Naijiria ni ọrọ ti a n sọ yii wa, abala naa lo sọ nipa ohun ti Aarẹ gbọdọ ṣe to ba n lọ fun isinmi, kii ṣe irinajo.
"To ba n lọ fun isinmi, o gbọdọ fi iwe ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin agba pe oun n lọ fun isinmi o, lẹyin naa, ile aṣofin naa lagbara lati gbe agbara fun igbakeji rẹ titi ti Aarẹ yoo fi pada de ti yoo si kọwe si wọn pe oun ti de, igba yẹn ni agbara Aarẹ to le pada sọwọ rẹ.
"Ile igbimọ aṣofin ni eku ẹda to da wahala yii silẹ"
Victor Opatola tẹsiwaju pe ti Aarẹ ba ti lo ọjọ to le ni ọjọ mẹtalelogun fun isinmi nilẹ okere, ofin sọ pe ile igbimọ aṣofin gbọdọ gbe igbesẹ lati gbe agbara aṣẹ fun igbakeji rẹ.
O ni "Aarẹ orilẹede yii ti kuro nile o ti le ni ọjọ mẹtalelogun, ohun to n tumọ si ni pe, ile aṣofin lo lẹtọọ lati gbe agbara fun Shettima.
"Nitori naa, ẹni to kuna lati ṣiṣẹ ti ofin fun ni ile igbimọ aṣofin, awọn ni eku ẹda to da wahala yii silẹ nitori wọn kuna lati sẹ ohun to yẹ ki wọn ṣe."
Amofin naa tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ nnkan bayii maa ṣẹlẹ ni Naijiria ti ile igbimọ aṣofin yoo kuna lati ṣe ojuṣẹ rẹ, kii ṣe ohun to bojumu rara.
"Ko si ohun to n jẹ 'working vacation' ninu ofin Naijiria"
Lori ọrọ ti agbẹnusọ Aarẹ sọ pe iṣẹ ni Aarẹ lọ ṣe ninu isinmi to lọ fun, amofin Opatola sọ pe ko si ohun to jọ bẹẹ ninu iwe ofin Naijiria.
O ni "Ede ti awọn alabaṣiṣẹ Aarẹ n lo pe Aarẹ lọ fun isinmi lati ṣiṣẹ, ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
"Ti Aarẹ ba lọ silẹ okere lori ọrọ Naijiria, bii ko lọ si ipade agbaye UNGA 81 ti wọn ṣe l'Amẹrika, a maa mọ pe iṣẹ ilu lo lọ ṣe.
"Amọ isinmi ni Aarẹ sọ pe oun n lọ ṣe, eyii si yatọ si pe o fẹ lọ ṣiṣẹ lorukọ ilu."
O pari ọrọ pe o yẹ ki ile igbimọ aṣofin ti gbe agbara Aarẹ fun igbakeji rẹ gẹgẹ bii ofin ṣe sọ ṣaaju asiko yii.
Wayi o, iroyin to n tẹ ea lọwọ bayii ni pe Aarẹ Tinubu yoo pada walẹ ko to di ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, to jẹ ayajọ ọjọ ominira Naijiria.

























