Wo ohun tí a mọ̀ nípa àwọn afúrásí tí wọ́n nawọ́ gán ní ibùdó RAF Fairford ní UK

Ijọba orilẹ ede UK ti nawọ gan awọn afurasi marun-un lori ibugbamu ati ẹsun igbeṣumọmi lẹyin ibugbamu kan to waye ni ibudo awọn ọmọ ogun ofurufu ni ẹkun iwọ oorun England.
Igbimọ to n maa n ṣayẹwo ado oloro ti bẹrẹ si ni ṣe ayẹwo awọn ọkọ to wa ni ẹgbẹ ibudo Ologun oju ofurufu to wa ni Fairford ni Gloucestershire.
Ọpọ awọn ile to wa ni agbegbe naa ni awọn eeyan ti kuro nibẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa Gloucestershire sọ pe awọn gba ipe ni oru ọjọ Aiku pe awọn ọkọ meta kan n rin lọna RAF Fairford ti irinajo si mu ifura lọwọ.
Ọlọpaa ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi marun-un ni Whelford, ilu ti ko jina si ibi ti ibudo Ologun naa wa amọ wọn ko tii darukọ awọn afurasi naa tabi sọ ibi ti wọn wa.
Gẹgẹ bi ofin to de igbeṣumọmi, afurasi ti wọn ba mu lori igbeṣumọmi ni wọn le fi si ahamọ fun ọjọ mẹrinla.
Ikọ to n ri si gbigbogunti iwa igbesumọmi nileeṣẹ ọlọpaa lo n lewaju iwadii naa ti ileeṣẹ Ologun Amẹrika naa si ni awọn n ṣiṣẹ pọ pẹlu ileeṣẹ Ologun UK lati mojuto iṣẹlẹ naa.
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump sọ pe awọn ti wọn nawọ gan lo dabi pe wọn fẹ ṣiṣẹ aburu, ti won si ti n wo wọn fun igba pipẹ ki wọn to nawọ gan wọn.
Awọn to n pese amojuto lori iṣẹlẹ pajawiri ti wa ni agbegbe naa ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa, Maggie Blyth sọ pe amojuto naa maa tẹsiwaju fun ọjọ diẹ.
"Mo gbagbọ pe 999 ti mo pe lo da erongba wọn ru"
Olugbe agbegbe naa to pe 999 lati sọ fun awọn ọlọpaa lori awọn ọkọ mẹtẹẹta ti wọn ri ni ilu Whelford sọ pe Ọlọrun lo ni ki oun ri awọn ọkọ naa.
Nigba to n ba BBC Radio 4 sọrọ, obinrin naa ti ko fẹ ki a darukọ oun, sọ pe oun ri pe wọn ti di ọna nigba ti oun fi maa de ile, ti oun si ri awọn eeyan ti wọn wọ aṣọ nla, ti wọn so bo oju wọn.
"Bi wọn ṣe ri mi ni wọn sa siwaju mi, awọn kan wọ igbo lọ, tawọn mii si sa wọnu ilu Kempsford. Eyi lo jẹ ki n woye pe nnkan aburu kan n waye."
Obinrin naa ni eyi lo jẹ ki oun pe ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni RAF Fairford ṣugbọn ẹnikẹni ko gbe e, idi si niyẹn ti oun fi pe 999 tawọn ọlọpaa si de si ilu naa laaarin iṣẹju mẹwaa.
"Mo gbagbọ pe 999 ti mo pe lo da erongba wọn ru.
"O jẹ ohun to yami lẹnu pe emi araalu ni mo ri awọn eeyan naa."
Araalu mii to ri bi wọn ṣe nawọ gan awọn afurasi naa sọ pe oun kan n gbọ ariwo niwaju ile oun, ti oun ko mọ ibi ti ariwo naa ti n wa.
O ni nigba ti oun yọju sita ni oun ri tawọn ọlọpaa n fofin gbe awọn eeyan.
Ki ni ijọba UK sọ?
Olootu ijọba UK, Andy Burnham sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ohun to kọ ijọba lominu, ti ijọba yoo si gbe gbogbo igbesẹ lati da aabo awọn araalu.
Minisita naa rọ awọn araalu lati ye ro ohun ti wọn fẹ lọkan ara wọn, ki wọn gba awọn alaṣẹ laaye lati ṣewadii wọn bo ṣe yẹ.
Nigba to n sọrọ Minisita fun eto aabo, Wes Streeting dupẹ lọwọ awọn ara agbegbe naa fun bi wọn ṣe loju lalakan fi n ṣọri, ti wọ si fi iṣẹlẹ naa to awọn araalu lori.


























